BBC Debates: Àwòrán tí ẹ kò rò níbi ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá l'Eko

Ó ṣeé ṣe kí ẹ má fọkàn síi pé àwọn ǹkankan wáyé níbi ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ náà.

Àwòrán àwọn òṣìṣẹ́ BBC
Àkọlé àwòrán, Oludari agba BBC ni ẹkun iwọ oorun Afirika, Toyosi Ogunṣẹyẹ pẹlu oludari BBC ni orilẹede Naijiria, Aliyu Tanko n ṣe gbogbo akitiyan bi eto yoo ṣe yọri si rere plu awọn akẹgbẹ wọn lẹnu iṣẹ
Ọmọlara Adesanya (PPC)
Àkọlé àwòrán, Arabinrin Ọmọlara Adesanya dúró déédé lati ya fọ́tò ko to lọ we gele rẹ sori ni kete bo ṣe n de gbọngan ipade.
Àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò
Àkọlé àwòrán, Wámúwámú ni àwọn ọlọpàá dúró láti mójú tó àbò gbogbo àwọn akópa àti agbègbè ìpàdé
Muyiwa Fafowora, (ADC)
Àkọlé àwòrán, Muyiwa Fafowora ni ijọba oun ṣe tan láti ṣe metro line ni ìpínlè Eko, o ni ènìyàn 22m lo wà ní ìpínlè Eko bẹẹ si ni ohun irina bii metro line ti New York Experience ni won maa lo tí oun ba ti dé bẹ.
Ibudo iforukọsilẹ.
Àkọlé àwòrán, Àwòrán àwọn olùkópa bí wọn ṣe n fi orukọ silẹ ni ibi eto, WAEC International Centre l'Eko.
Àwòrán àwọn olukopa
Àkọlé àwòrán, Àwòrán àwọn olukopa ti wọn n fi tẹrin tọyaya gboriyin fun awọn oludije ti wọn fẹran aato ti wọn ni fun ipinlẹ Eko
Àwọn àwòrán ẹ̀yìn ìtàgé
Àkọlé àwòrán, Ọmọọbabinrin Adebisi Ogunsanya (YPP) bí ó ṣe n gunlẹ si gbọngan ipade ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba
Atọkun eto ipade ifọrọwerọ plu awọn oludije gomina nipinlẹ Eko
Àkọlé àwòrán, Atọkun eto n ka iwe kikan kikan ṣaaju eto naa nitori iṣẹ to rọrun kọ lati mọ ati sọrọ nipa gbogbo oludije lai figba kan bọ ọkan ninu paapaa nipa eto oṣelu.
Àwọn àwòrán ẹ̀yìn ìtàgé
Àkọlé àwòrán, Àwọn oṣiṣẹ BBC Yoruba to n ṣe iforukọsilẹ awọn olukopa
Ọmọọbabinrin Adebisi Ogunsanya (YPP) ati Ọgbẹni Muyiwa Fafowora (ADC)
Àkọlé àwòrán, Ọmọọbabinrin Adebisi Ogunsanya (YPP) ati Ọgbẹni Muyiwa Fafowora (ADC) níbi ìgbàlejò ṣáájú ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀
Babatunde Gbadamosi, ADP
Àkọlé àwòrán, Babatunde Gbadamosi ni owo ara ilu ni ijọba Eko n na, kii ṣe owo baba wọn tabi ogun ẹnikẹni.
Àwọn àwòrán ẹ̀yìn ìtàgé
Àkọlé àwòrán, Gbogbo ori aga ni BBC Yoruba ti gbe apo ẹbun si fun awọn olikopa lati mọ riri wiwa wọn.
Àwòrán ẹyin itage
Àkọlé àwòrán, Oludari BBC ni orilẹede Naijiria, Aliyu Tanko n ki Ọmọọbabinrin Adebisi Ogunsanya (YPP) ku abọ sibi eto
Oṣiṣẹ alaabo
Àkọlé àwòrán, Àwòrán àwọn oṣiṣẹ alaabo ti o ti de sibi ipade ṣaaju eto
Àwọn àwòrán ẹ̀yìn ìtàgé
Àkọlé àwòrán, Gbọngan ipade ṣaaju ifọrọwerọ.
Àwọn àwòrán ẹ̀yìn ìtàgé
Àkọlé àwòrán, Awọn amoju ẹrọ lẹnu iṣẹ ki gbogbo wiwo ati gbigbọ eto le to.
Àwọn àwòrán ẹ̀yìn ìtàgé
Àkọlé àwòrán, Awọn oluranlọwọ alejo nibi ipade ifọrọwerọ BBC Yoruba nipinlẹ Eko