World Cancer Day: Onímọ̀ sáyẹ́ńsì ní ká tètè ṣe àwárí àrùn jẹjẹrẹ ọyàn ni ọ̀nà àbájọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Arun jẹjẹrẹ ọyan jẹ ọkan lara arun jẹjẹrẹ to wọpọ julọ jakejado agbaye, to si saba maa n fa iku awọn obinrin lorilẹede Amẹrika, ati jakejado agbaye.
Idi ree ti ọdọbinrin kan, tii se ọmọ orilẹede Singapore, to tun jẹ onimọ ijinlẹ sayẹnsi, Dokita Jingmei Li se pinnu lati wadi awọn ohun to n fa arun jẹjẹrẹ ọyan ati awọn ọna abayọ si arun naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Máṣe tijú láti gé ọmú rẹ to bá ṣàkíyèsí kóró nínú ọyàn, ilèra ló ṣe kókó - Ẹni tó ye àìsàn jẹjẹrẹ ọyàn
- Arap Moi, ààrẹ Kenya tẹ́lẹ̀ jáde láyé
- Àwọn òṣìṣẹ́ ọba ní Kwara sọ ara wọn sínú ààwẹ̀ àti àdúrà torí owó oṣù tuntun
- Ìtàn ìgbé ayé Arap Moi, ààrẹ kejì ní Kenya tí ọ̀pọ̀ ń rántí ìjọba rẹ̀ fún ìwà àjẹbánu
- Ìdùnnú ṣubú layọ̀ fáwọn obìnrin, ife ìtọ̀ tó ń dènà àrùn nílé ìgbọ̀nsẹ̀ ti dé
Dokita Li ati awọn akẹẹgbẹ rẹ ti sawari awọn ohun ajogunba ninu ara toto okoolelọọdunrun o din meje, 313, ti wọn wa ninu ara to lee sokunfa arun jẹjẹrẹ ọyan.
"Afojusun mi ni lati sawari awọn eroja kan ninu ara, ti yoo se atọna si ọna abayọ fun iwosan arun jẹjẹrẹ ọyan."
Sise awari awọn eroja ara to n fa arun jẹjẹrẹ ọyan:

Oríṣun àwòrán, University of Singapore
Iwadi si ti fihan pe a lee lo awọn eroja ara yii lati fi dena nini arun jẹjẹrẹ ọyan, nitori ida ọgbọn ninu ọgọrun awọn eeyan to ni arun jẹjẹrẹ ọyan lo maa n ku tori eroja ara wọn ti ko dara.
Bakan naa ni eroja ara yii yoo pese awọn iroyin to yẹ nipa ayẹwo ọyan ati idi taa fi lee tete se ayẹwo naa nitori lawọn ọpọ orilẹede, ayẹwo maa n bẹrẹ fawọn obinrin to ti le ni aadọta ọdun, to si maa n waye lọdun meji si mẹta.
"Awọn obinrin to seese ko wa ninu ewu nipa eroja ajogunba ara wọn yẹ ko tete se ayẹwo ara wọn nitori inu ewu kannaa ni wọn wa pẹlu awọn eeyan miran lọjọ iwaju."
- Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ PDP tó sápamọ́ kọlù mí lásìkò tí mò ń lọ sí ibi iṣẹ́, ló fa rògbòdìyàn - Olamiju Akala
- Kò sí ìfòyà tí ẹ bá ti ní nọ́mbà ìdánimọ̀, kékeré ni káàdì ìdánimọ̀ - NIMC
- Wọ̀dùwọ̀dù àsìkò ijáde mú ẹ̀mí akẹ́kòó mẹ́tàlá lọ
- Akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ Afíríkà kan tí lùgbadì ààrùn Coronavirus ní Fásitì China
- Ọwọ Gómìnà Makinde làṣẹ wà bóyá a ó fí òfin dé Okada ní Oyo -OYRTMA
- 'Ẹ bá wa sọ fún Sanwoolu kó dárí jì wá o, ìpinú tí wọ́n ṣe l'Eko kò m'ọ́gbọ́n wá rárá'
Awọn ile iwosan maa n fẹ lo itan ilera mọlẹbi kan lati tọkasi awọn eeyan to lee tete lugbadi arun jẹjẹrẹ ọyan, sugbọn itan ilera mọlẹbi, nigba miran lee ma se gbara le.
O lee nira lati mọ boya tootọ ni awọ̀n iroyin ti wọn sọ̀ si wa lọwọ, to fi mọ ohun to fa arun naa. Fun apẹẹrẹ, o seese ki mọlẹbi kan jalaisi nitori arun jẹjẹrẹ inu egungun, ko si jẹ pe inu ọyan ni arun ọhun ti kọkọ bẹrẹ.

Oríṣun àwòrán, MOHAMMED HUWAIS/GETTY IMAGES
Iha ti asa ati ise ẹya kọọkan n kọ si arun jẹjẹrẹ ọyan:
Bakan naa lawọn orilẹede to wa ni ila oorun Asia, asa ati ise lee jẹ igbona kan gboogi lati lee tete se awari arun jẹjẹrẹ ọyan ninu ara.
"Ni apa ibi ti mo ti wa, a kii fẹ sọrọ nipa awọn arun to n ba wa ja, bẹẹ si ni ti ko ba bọwọ sori tan, a kii fẹ lọ sọdọ dokita fun itọju.
Koda, awọn asa kan tiẹ gba pe awọn arun kan ati jẹjẹrẹ jẹ ifẹ Ọlọrun, ti wọn kii si fẹ wa iwosan fun ayafi to ba ti buru tan patapata."
Iwadi fihan pe ni ọpọ ta ba ri pe koro wa ninu syan wa, o seese ko jẹ pe iru koro bẹẹ ti di nkan nla, idi si ree ti Dokita Li fi ni o se pataki fun wa lati pa awọn asa awujọ wa kan ti sẹgbẹ kan, ka si maa se ayẹwo ọyan wa loore-koore.
Ki lo n fa arun jẹjẹrẹ ọyan?
Bi arun jẹjẹrẹ ọyan se n fi ojoojumọ gbilẹ si la lee so mọ ilana igbe aye wa ati awọn ohun to rọ mọ ilana ibimọ wa.
Lara rẹ la ti ri iwa jijẹ awọn ounjẹ afaralokun taa mọ si Cabonhydrate eyi to maa n jẹ ka sanra asanju, ati minu ọti lile ni amuju
Koda, iwadi tun fidi rẹ mulẹ pe, ọmọ bibi maa n mu adinku ba nini arun jẹjẹrẹ ọyan lọjọ iwaju, bẹẹ si awọn obinrin to ba loyun akọni, ti osu rẹ si pe titi to fi bimọ, ko to pe ẹni ọdun marundinlogoji, lee ma ni arun jẹjẹrẹ ọyan lọjọ iwaju.
Idena arun jẹjẹrẹ ọyan:
Dokita Li ni bi o tilẹ jẹ pe owo tuulu lawujọ agbaye ti na lati se awọn oogun fun itọju awọn obinrin to ni arun jẹjẹrẹ ọyan, amọ o ni ohun to daa ni pe ka dena awọn obinrin lati ri arun naa.
"Ọpọ ohun la ti se nidi ipese oogun ati tawọn ileesẹ apoogun si n pawo wọle lojoojumọ amọ mo fẹ se nkankan lati tiẹ fi dena arun jẹjẹrẹ ọyan, nibayii ta n gba owo lọwọ orilẹede Singapore."
O ni ayẹwo ọyan lee sawari arun jẹjẹrẹ ọyan taa ba ri ami miran pe arun yi ti wọnu agọ ara, ti koro ọyan naa ko si to ibu eso bluberry.
Lii ni " K jẹ ka kọlu awsn ọmọ ogun arun naa nigba ti ọta si wa ni kekere." O ni idaniloju wa pe ti itọju to yanranti ba wa ni akoko yii, ida ọgọrin ninu ọgọrun awsn obinrin to ni arun jẹjẹrẹ ọyan ni yoo lo kọja ọdun mẹẹdogun si lẹyin ti wọn kede pe wọn ni arun yii.
Amọ o ni ti koro ọyan ọhun ba ti to ibu eso ọsan lasiko ti wọn kofiri ninu agọ ara, o seese ki ẹmi ẹni bẹẹ ma gun to ọdun mẹẹdogun mọ lẹyin ikede eyi.
"arun jẹjẹrẹ kọọkan lo yatọ si ara wọn, ta ba ni ẹgbẹrun mẹwa arun jẹjẹrẹ, a nilo itọju lọna ẹgbẹrun mẹwa, idi si ree ti mo se n pariwo pe ka tete sawari arun jẹjẹrẹ lọna abayọ, dipo ka maa wa itọju fun-un."
















