Wee Cup: Obinrin kan ti pèsè kóńdòró tí obìnrin leè fi tọ̀ lórì òró láti dènà àrùn

Obinrin kan lorilẹede Kenya ti pese ọna abayọ fun awọn obinrin ti wọn ma n ko arun lẹyin ti wọn ba lo ile igbọnsẹ ni gbangba.
Obinrin ọhun, Njeri Muthaka pese ife itọ ti obirin lee lo lati fi tọ lóòró, eyi ti o n ran awọn obinrin lọwọ lati dena awọn arun ile igbọnse.
Muthaka sọ fun BBC pe, oun ko awọn awọn kondoro kan wọle si Kenya lẹyin ti oun ko arun ile igbọnsẹ lọpọ igba.
Lẹyin to lo awọn kondoro naa, to si ri pe o mu adinku ba bi oun ṣe n ko aisan ile igbọnsẹ, lo pinnu lati maa taa labẹle.
Awọn eleto ilera to se iwaadi si kondoro naa ni fi han pe ife ọhun lee dena arun ile igbọnsẹ fun awọn obinri.
Dokita Chris Obwaka sọ fun BBC pe, ti obinrin ba n tọ looro, o tumọ si pe iru obinrin bẹẹ ko fara kan awo ile igbọnsẹ, yoo si ṣoro fun iru obinrin bẹẹ lati ko arun.
Ṣugbọn awọn okunrin orilẹ-ede kenya ti n tako kondoro naa pe o lodi si aṣa ilẹ wọn.
Wọn ni o lodi si aṣa ati iṣe ilẹ wọn ki obinrin maa tọ lori iduro bi okunrin.
Iye owo kondoro naa jẹ dọla meji pere, obinrin to n ta si sọ pe oun ti ta kondoro to le ni irinwo.













