Ogun: Ìyàwó ilé lu ọmọ ìyàwó àkọ́kọ́ ọkọ rẹ̀ pa ní ìpínlẹ̀ Ogun

Arabinrin ẹni ọgbọn ọdun kan, Shukurat Olufowobi to jẹ iyawo ile ni ọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ latari pe o lu ọmọ iyawo akọkọ ọkọ rẹ titi doju iku.
Iṣẹlẹ naa ṣẹ ni agbegbe Oshodi Oke ni Ogijo nibi ti Shukurat ti lu Azeem Olufowobi ọmọ dun marun un pa.
Ọwọ ọlọpaa tẹ afurasi yii ni nkan bii ago mejila abọ oru ọjọ aiku tii ṣe ọjọ keji oṣu keji ọdun 2020 lẹyin ti awọn ara adugbo kan ta awọn ọlọpa ẹkun ti Ogijo lolobo pe Shukurat gba nkankan mọ ọmọ naa lori.
Eyi jẹ ki ọmọ naa ni ọgbẹ lori to si pada fa iku rẹ. Iroyin taa gbọ ni pe kiakia ni arabinrin naa ati ọkọ yara gbe oku ọmọ naa lọ si Ajah nilu Eko nibi ti wọn yọlẹ bo o mọlẹ si.
Kete ti ọrọ naa de agọ Ọlọpaa ni DPO Suleman Baba Muhammad ti ko awọn ikọ ọtẹlẹmuyẹ rẹ jọ lati lọ si ile to ti ṣẹlẹ ti wọn si ri i pe awọn tọkọtaya naa ti n ko ẹru wn kuro ni adugbo ọhun ni wọn ba tete mo irin si wọn lọwọ.
Iwadii to ti waye ṣaaju fi han pe o ti pẹ ti arabinrin naa ti n fiya jẹ ọmọ yii tipẹ, iya to bi i ti fi baba rẹ silẹ lori aigbraẹniye.
Sugbọn lọjọ buruku eṣu gbomi mu yii, nkan to wuwo ni arabinrin naa jan mọ ọmọ ọhun lori eyi to si fọ ori ọmọ ttti to fi fa iku rẹ.
Arabinrin naa ati ọrẹ rẹ sare bẹ nọọsi to kọkọ ṣetọju alaisan naa to si sọ ohun to ṣẹlẹ fun ọkọ ati iyawo ọhun pe ko parọ m nkan mii nipa ohun to fa iku oloogbe naa ṣugbọn o kọ tori pe o ni o lodi si ofin iṣẹ oun.
Ọkọ atiyawo naa Ayuba ati Shukurat Olufowobi ti wa ni agọ Ọlọpaa bayii ti wọn n fi ọrọ wa wọn lẹnu wo.
Ẹwẹ, kọmisana ọlọpaa Keneth Ebrimson ti paṣẹ pe ki wn tete gbe ẹjọ awọn afurasi mejeji lọ si ẹka to n ri si ipaniyan ni ẹka iṣewadii ati ọtẹlẹmuyẹ fun iwadi kikun ati fifi wọn jofin.












