Okada Ban: Ara mi ò yá mọ́ báyìí tórí pé mo rìn lọ gbogbo ibi tí mò ń lọ - Ará Eko

Àkọlé fídíò, 'Ẹ bá wa sọ fún Sanwoolu kó dárí jì wá o, ìpinú tí wọ́n ṣe l'Eko kò m'ọ́gbọ́n wá rárá'
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ikọ iroyin BBC jade si igboro lati fun awn ara ipinlẹ Eko lanfani lati s iriri wọn lnu ọjọ mẹta ti ijọba ipinlẹ eko bẹrẹ ofin ti wn ṣe lati ko gbogbo ọkada ati kẹkẹ maruwa kuro lawọn adugbo kọọkan.

Ṣaaju eyi ọpọlọpọ iṣẹlẹ la ri nigboro ni idahun si igbesẹ ti ijọba ipinlẹ Eko gbe yii.

Ijora Olopa l'Eko dàrú bí àwọn ọlọ́pàá, awakẹ̀kẹ́ àti ọlọ́kadà ṣe dojú ìjà kọra wọn

Ija Igboro l'Eko

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni wi pe awọn to n fi ọkada ati kẹkẹ ṣiṣẹ ni agbegbe Ijora nipinlẹ Eko n wọya ija pẹlu awọn ọlọpaa.

A gbọ pe awọn eniyan naa ni dandan ni ki awọn o maa se iṣẹ aje awọn lọ.

Koda, iroyin sọ pe ibọn ti ba awọn eniyan kan, ti wọn si ti gbe wọn lọ sile iwosan.

Ọjọ kinni, oṣu Keji, ọdun 2020 ni ofin ti ijọba ipinlẹ Eko ṣe lati dena lilo ọkada ati kẹkẹ fun ero gbigbe ni awọn agbegbe kan, gbera sọ.

Bakan naa ni awọn kan n fi ẹhonu han ni agbegbe Ikeja, nitori ofin naa.

Ọkada to le ni aadọwa(188) ati kẹkẹ Maruwa mejidinlọgọrin(78) ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti gbẹsẹ le lẹyin ti ijọba ipinlẹ Eko fi ofin de ọkada ati kẹkẹ wiwa lawọn ijọba ibilẹ kan jakejado ilu Eko.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa, Bala Elkana lo fọrọ yii lede ninu atẹjade to fi sita.

Bakan naa ogoji eeyan ti wọn kọ lati pa ofin naa mọ ni ileeṣẹ ọlọpaa ti fi ọwọ ofin mu kaakiri ilu Eko laarin ọjọ Abamẹta si ọjọ Aiku ti eto naa bẹrẹ.

Ọlọpaa mu ọlọkada

Oríṣun àwòrán, Other

Ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu to ṣaaju awọn ọlọpaa lati ṣe itọpinpin eto naa kaakiri dunnu si bi awọn araalu sẹ pa ofin naa mọ.

Ọgbẹni Odumosu dupẹ lọwọ awọn olugbe ipinlẹ Eko fun ifọwọsowọpọ wọn pẹlu ijọba ati ileeṣẹ ọlọpaa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn yoo tẹsiwaju itọpinpin lati rii wi pe awọn olugbe ipinlẹ pa ofin ti ijọba fi de ọkada and kẹkẹ Maruwa wiwa mọ.

Ẹwẹ, Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti paṣẹ fun ileeṣẹ to n ri si ọkọ akero lati ko ọkọ bọọsi marunlelọgọta jade lati ṣe iranwọ fawọn eeyan to n lọ sẹnu iṣẹ wọn.

Awọn ọkọ akero naa yoo bẹrẹ iṣẹ lonii ọjọ Aje ọjọ kẹta oṣu keji.

Awọn ọna tuntun ti wọn yoo na niyii pẹlu owo ọkọ tawọn eeyan yoo maa san: Ikeja si Ogba(N100), Berger si Ogba(N100), Ikeja si CMS(N200), Oshodi si Ajah(N500), Obalende si Ajah(N250), CMS si Ajah(N250) ati Inner Marina si Ajah(N250).

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

Gomina Sanwo-Olu ti kọkọ ṣalaye pe ofin to ti wa tẹlẹ ni ijọba ṣe agbekalẹ rẹ pada lẹyin ti ijọba ti kọkọ fofin de wiwa ọkada ati kẹkẹ Maruwa lọdun mẹfa sẹyin.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Sanwo-Olu ni yatọ si wi pe iwakuwa awọn ọlọkada pọ, ijamba ọkada ati kẹkẹ Maruwa ti ran ọpọ lọ si ọrun lairotẹlẹ.