Gómìnà Makinde ló lè pàṣẹ bóyá kí a gbà okada wọlé tàbí kí a fòfin dè wọ̀n l'Òyó

Aworan oṣiṣẹ ajọ OYRTMA

Oríṣun àwòrán, OYRTMA

Lara ohun ti yoo tẹyin aṣẹ ijọba ipinlẹ Eko lati fofin de lilo okada ati keke Napep lawọn ijọba ibilẹ kan ni pe awọn ọlọkada naa yoo kẹru wọn lọ si awọn ipinlẹ to sumọ Eko.

Ipinlẹ Ogun ati Oyo ni awọn to wa ni tosi Eko ti o si ṣeeṣe ki pupọ wọn ti gunlẹ sibẹ bi a ṣe n sọrọ yii.

O ri bẹẹ ko ri bẹẹ, ajọ to n dari eto irina nipinlẹ Oyo OYRTMA ti tẹnumọ ipinnu wọn lati mojuto apọju awọn kẹkẹ ọkada ati lilo awọn ọkada nipinlẹ naa.

Alaga ajọ naa, Akin Fagbemi ni o fi ọrọ yii to awọn akọroyin leti nilu Ibadan.

Fagbemi ni ajọ naa n fi tọkan tọkan reti igbesẹ ati aṣẹ lati ọdọ Gomina Seyi Makinde boya awọn naa yoo fofin de lilo ọkada tabi ki wọn ma lo ni ipinlẹ ọhun.

''Ko ba wa lojiji pe awọn ọkada yoo ya wọ Oyo lati Eko ṣugbọn digbi la wa lati koju ipenija yii''.

O ni lootọ ni pe awọn a ma gba awọn ajoji lalejo ṣugbọn ti o ba ti di wi pe yoo ṣakoba fun aabo tabi awọn ohun amayedẹrun ilu, awọn ko ni ma ṣalai gbe igbesẹ to yẹ.

Fagbemi tun tẹsiwaju pe awọn ti n ṣe eto lati ni akojọpọ orukọ awọn ọlọkada, oni kẹkẹ Napep ati awọn ọlọkọ ero nipinlẹ naa.

Okada

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Okada Ban: ọjọ kini oṣù keji ni òfin tuńtun yóò bẹ̀rẹ̀

O ni igbesẹ yi yoo jẹ ki o rọrun fawọn lati le mọ awọn ọkọ ti wọn ba jigbe ati lati le ni ounka iye awọn ijamba ọkọ to ba waye.