James Ibori loot: Ìjọba àpapọ̀ ní òun ti dá £4.2b tó gbà lọ́wọ́ James Ibori padà fún ìpínlẹ̀ Delta

James Ibori

Oríṣun àwòrán, others

Ijọba apapọ ni awọn ti fi owo ti wọn ri gba pada ninu owo ilu ti iye rẹ le ni biliọnu mẹrin poun owo ilẹ Gẹẹsi ṣọwọ pada si ọdọ ijọba ipinlẹ Delta.

Oluṣiro owo agba fun apapọ orilẹede Naijiria, Ahmed Idris lo so sọ bẹẹ. Owo naa poora lapo ijọba lasiko iṣejọba James Ibori gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Delta tẹlẹ.

Amofin agba orilẹede Naijiria, Abubakar Malami ti kọkọ sọọ ni oṣu kẹta ọdun yii pe afara keji lori odo River Niger ati opopona Abuja si ilu Kano pẹlu titi marosẹ Eko si Ibadan ni wọn yoo na owo naa le lori dipo ki wọn daa pada si ipinlẹ Delta nibi ti Ibori ti ji.

Àkọlé fídíò, 'Mo fọ kọ́mú, pátá, ògiri ilé lórí 200,000 láìlèfọhùn lórílẹ̀èdè Oman'

Malami sọ ọ nigba naa pe ofin ijọba apapọ ni Ibori tapa si bẹẹni ijọba apaọ lo ṣe ẹjọ ti owo naa fi jade, kii ṣe iipinlẹ.

Amọṣa oluṣiro owo agba lorilẹede Naijiria ṣalaye fun ile aṣoju-ṣofin pe ijọba apapọ gba awọn owo naa lorukọ awọn ijọba ipinlẹ ni.

Oluṣiro owo agba ni Naijiria, Ahmed Idris ṣalaye fun igbimọ tẹẹkoto kan ti ile aṣoju-ṣofin gbe kalẹ pe aṣuwọn ipinlẹ ti wọn ba ti ji owo ni ijọba apapọ maa n da irufẹ owo bẹẹ pada si ni kete ti wọn ba ti gba a.

O ni lọtẹ yii o, wọn ti da owo naa pada si aṣuwọn ijọba ipinlẹ Delta nitori lasiko ti James Ibori ṣe gomina nibẹ lo ko owo ti wọn gba naa jẹ.

O ni ijọba apapọ kii jẹ ki iru owo bẹẹ pẹ lọwọ oun nitoripe awọn ipinlẹ tọrọ kan lee gbe lọ si ile ẹjọ.

Ọrọ oluṣiro agba lorilẹede Naijiria yii n waye lẹyin ọsẹ kan ti ijọba apapọ kede pe oun ti gba biliọnu mẹein o le igba miliọnu pọun (£4.2 billion) ti ijọba ilẹ Gẹẹsi gba lọwọ awọn alajọṣepọ Ibori