Oduduwa Nation: Àwọ́n lọ́balọ́ba tó ń ṣàtìlẹ́yìn jíjá fún Oduduwa Nation ní ilẹ̀ yorùbá

Awọn Ọba

O ti to asiko diẹ ti ajijagbara fun awọn ọmọ Yoruba, Sunday Igboho ti n pe fun idaduro orilẹede fun iran Yoruba, eleyii ti wọn n pe ni Oduduwa Nation.

Lati igba ti ijijagbara fun ilẹ Yoruba yii ti bẹrẹ ni awọn lọbalọba kọọkan ti n fi ero wọn han nipa igbesẹ Sunday Igboho.

Amọ bi awọn lọbalọba kan ṣe n gbaruku ti ipe fun Oduduwa Nation, awọn miran tako ipe naa.

Eyi ni awọn lọbalọba to ṣe atilẹyin fun ipe fun Oduduwa Nation;

Ẹni tó máa kú ko kú, ẹ jẹ́ ká jà fún ominira ile Yoruba- Ọba Adetokunbo Tejuosoho.

Adetokunbo Tejuosho

Oríṣun àwòrán, Adetokunbo Tejuosho

Ọba Adetokunbo Tejuosoho ti ni awọn ọmọ Oduduwa kan ti ṣetan lati fi ẹmi wọn lelẹ, ki ilẹ Yoruba le gba ominira lọwọ awọn to n ni aye wọn lara.

Ọba Adetokunbo Tejuosoho ni ko si ẹnikẹni to ṣetan lati salọ si ibi kankan, bi o tilẹ sepe awọn eeyan kan tilẹ ti n salọ kuro ni Naijiria tẹlẹ nitori bi gbogbo nnkan ṣe ri, paapaa nipa ti eto abo to mẹhẹ.

Tejuosho ni bi ọrọ ọhun ṣe n lọ yii, awọn ara ilu ti n ni igbagbọ ninu awọn eeyan bi Sunday Igboho ju igbagbọ ti wọn ni ninu ijọba lọ.

Ọba yii fikun un pe o yẹ ki ijọba pe ipade apero, ki gbogbo ẹya to wa ni Naijiria sọ ohun ti wọn n fẹ ki wọn si ṣe atunto, bi bẹẹ kọ, ki onikaluku maa lọ ni ilọ tirẹ.

Àkọlé fídíò, A ti ń fẹ́ Hausa, Ibo, ó sàn ka jọ ṣe é ní tùbí-ǹ-nùbí lórí ọ̀rọ̀ Nàìjíríà ju ìjà ogun lọ - Ọba Alara

Ìjọba ló ni àbùkù àìbìkítà lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho to n pe fun Oduduwa Nation- Ọba Olugbọn ti Orile-Igbọn

Olugbon Of Ile Igbon Part 2

Ọba Francis Olusola-Alao to jẹ igbakeji alaga awọn lọbalọba ni ipinlẹ Ọyọ ti fi atilẹyin rẹ han lọpọ igba fun ajijagbara iran Yoruba, Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ n pe ni Sunday Igboho.

Ọba Francis ni ijọba Naijiria ti kuna ni ojuṣe wọn lati da abo bo awọn eeyan ti wọn n dari lasiko yi.

Àkọlé fídíò, Francis Olusola Alao: Wọ́n ti ti ọ̀rọ̀ òṣèlú bọ ọ̀rs Sunday Igboho, ṣùgbọ́n..- Oba Olugbọn

Ninu ọrọ rẹ, Oba Francis ni ti ẹnikan ba n ro pe ohun ti Sunday Igboho n ṣe ko dara to, ki ẹni naa lọ ṣe bi akọni.

Oba Francis Olusola-Alao salaye pe ofin ijọba fi aye gba " Self Help" ati " Self Defence" ni eyi to n jẹ ki eeyan gbeja ara rẹ tabi eeyan rẹ bi Sunday Igboho se n se lọwọ yii.

Kabiesi wa parọwa fun ijọba apapọ ati ipinlẹ lati tete wa nkan ṣe si ọrọ eto aabo lasiko yii.

Emi kò tako ìpè fún Yoruba Nation- Aseyin ti ilu Iseyin

Aseyin

Oríṣun àwòrán, others

Asẹyin ti ilu Isẹyin, Ọba Abdulganiyu Adekunle Salau, Ologunebi-Ajinasẹ Kinni ti ṣalaye pe oun ko figba kankan tako ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba, iyẹn Yoruba Nation.

Kabiyesi sọ ọrọ yii lasiko ti Sunday Igboho fẹ wa ṣe iwọde ni ilu Iṣẹyin.

Asẹyin ni oun ko fi igba kankan fofin de Sunday Igboho pe ko gbọdọ gbe iwọde ipe fun Yoruba Nation de ilu Isẹyin.

Asẹyin ni ọmọ oun ni Sunday Igboho gẹgẹ bi ọmọ Oke Ogun to jẹ, nitori naa, ohun ti oun n sọ ni pe iwọde ti Sunday Igboho fẹ ṣe ko lee waye ni ilu Iṣẹyin nitori eto aabo to mẹhẹ kaakiri Naijiria.

Ẹ ó ríjà oba, tí ẹ bá gbìyànjú láti fọ́wọ́ kan Sunday Igboho - Oba ilu Oke-Iho

Oba ilu Oke-Iho lagbegbe Oke Ogun nipinlẹ Oyo, Oba Rafiu Osuolale Mustapha ti ni oun duro gbọin-gbọin lẹyin Sunday Igboho lori ipe re fun Yoruba Nation.

Oba Mustapha sọ ọrọ yii lasiko ti Igboho ṣe abẹwo si i ni ilu Oke-Iho.

Bakan naa ni ọba naa kilọ fun awọn to n gbero lati mu Sunday Igboho.

Ọba Mustapha Adeitan Keji gbadura fun Igboho pe didaduro iran Yoruba yoo ṣeeṣe.

Ilẹ Yoruba ko le dede yapa kuro ninu Naijiria lai beere lọwọ alalẹ ilẹ - Olubadan

Olubadan ti ilu Ibadan, Ọba Saliu Adetunji, Aje Ogungunnisọ Kinni, ti da si ọrọ pipe fun ki iran Yoruba da duro gẹgẹ bi orilẹede tirẹ, pe ko yapa kuro lara orilẹede Naijiria.

Kabiyesi ni ohun ti ohun fẹ ki gbogbo eeyan mọ ni wipe lootọ iru ipinu yẹn bii ti nini Yoruba Nation nilo iwadii daadaa, kii ṣe ohun a n ku giri ṣe.

"Taa ba wa jọ jokoo pọ taa fẹnu ko tan, ẹnikẹni o le gbẹyin ba ẹbọ jẹ".

Olubadan sọ pe ilẹ Yoruba ko le dede yapa kuro ninu Naijiria beere lọwọ alalẹ ilẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, "ti wọn ba fẹ fi ọba jẹ, wọn maa n beere lọwọ alalẹ ilẹ ki wọn to de ẹnikẹni lade ki ilu le tu awọn eeyan lara."