Yoruba Nation: Aseyin ní òun kò tako ìpè fún Yoruba Nation

Aworan Aseyin ati Igboho

Asẹyin ti ilu Isẹyin, Ọba Abdulganiyy Adekunle Salau, Ologunebi-Ajinasẹ Kinni ti ṣalaye pe oun ko figbakankan tako ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba, iyẹn Yoruba Nation.

Atẹjade kan ti Kabiyesi, Asẹyin gbe sita lo ti sọrọ naa lati yannana ọrọ ati aigbọraẹniye to n la kaakiri pe oun ti fofin de Sunday Igboho pe ko gbọdọ gbe iwọde ipe fun Yoruba Nation de ilu Isẹyin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kabiyesi Asẹyin ni ohun ti oun sọ fun Sunday Igboho ni pe, bi oju ọjọ ṣe ri pẹlu ọrọ abo ni ilu Isẹyin, gbigbe iwọde bẹẹ kalẹ lewu nitori awọn janduku lee jaa gba bi wọn ṣe ja ti #EndSARS gba.

Àkọlé fídíò, Asẹ́yìn, àwọn ẹbí olóògbé ṣì ń fomijé dárò àwọn tóṣìṣẹ́ 'Custom' yìnbọn pa nílùú Iseyin

O ni ohun ti oun sọ fun wọn ni pe ki wọn sun iwọde naa, ti wọn fi si ọjọ karun un oṣu kẹfa ọdun 2021 kuro, di ẹyin adura ọjọ kọkanlelogoji awọn eeyan ti oṣiṣẹ aṣọbode pa nilu naa.

"Mi o ni pe ki Sunday Igboho maa wa silu Isẹyin, mi o si ni ki iwọde o maa waye nilu Isẹyin ṣugbọn mi o fẹ ko waye bayii nitori ilu Isẹyin ṣi n daro awọn ọdọ marun un tawọn aṣọbode naa pa."

Asẹyin ni ọmọ oun ni Sunday Igboho gẹgẹ bi ọmọ Oke Ogun to jẹ, nitori naa, ohun ti oun n sọ ni pe iwọde ti Sunday Igboho fẹ ṣe ko lee waye bayii.