Akeredolu, south west governors: Ó yẹ kí Aàrẹ Buhari yọ Abubakar Malami nípò lórí ọ̀rọ̀ tó sọ nípa ẹ̀yà Igbo àti àwọn darandaran- Amofin Adeoye

Oríṣun àwòrán, @agfmalami
Abubakar Malami: Agbẹjọro bu ẹnu atẹ lu bi Malami ṣe tako awọn gomina lori ifofin de dida ẹran.
Amofin lorilẹ-ede Naijiria, Ola Fatai Adeoye ti bu ẹnu atẹ lu olootu eto idajọ ati minisita fun eto idajọ ni Naijiria, Abubakar Malami lori bi o ṣe tako awọn gomina ti wọn fofin de dida ẹran kaakiri lorilẹede Naijiria.
Laipẹ yii ti awọn gomina mẹtadinlogun ni ẹkun Guusu Naijiria buwọlu iwe adehun lati fofin de dida ẹran kaakiri igboro ni awọn agbegbe wọn, nitori bi awọn Fulani darandaran ṣe n ṣekupa awọn agbẹ, ijinigbe ati awọn iwa ọdaran miran.
Amọ, Malami lasiko to n sọrọ ni ofin orilẹede Naijiria gaju ofin ipinlẹ lọ, to si fi aye gba awọn darandaran lati rin lati ibikan si omiran.
O tẹsiwaju lati safiwe igbesẹ awọn gomina lati fofin de dida ẹran ni iha Guusu, bi fi fofin de awọn ẹya Igbo ti wọn ma n ta ẹya ara ọkọ kaakiri ni ariwa orilẹede Naijiria.
- Ọlọ́pàá ní ká san ₦500,000 fún béèlì baba Ijesha, mo yarí torí ọ̀fẹ́ ni béèlì - Amòfin Ogunlana
- Wo ǹkan mẹ́jọ tí o kò ma nípa Abiidemi Rufai, amúgbálẹ́gbẹ̀ Gómìnà Dapo Abiodun tí wọ́n mú ní America
- Ẹ̀yin tí ẹ sọ pé irọ ni mo ń pa bayii ni yoo ri fún yín
- Ọwọ́ tẹ àwọn afurasí afipábánilòpọ̀ 206 l'Eko
- Èèmọ̀ wọ̀lú! Àwọn jàndùkú jí Adájọ́ gbé lọ nínú kóòtù lọ́sàn án gangan
Amọ, agbẹjọro Ola Fatai Adeoye ni ọrọ ti Malami sọ naa ko ṣe e gbọ lẹnu olootu eto idajọ lorilẹ-ede Naijiria, nitori ọrọ awọn darandaran yii ti jasi ipaniyan ati ọpọlọpọ iwa ọdaran ni awọn agbegbe wọn yii.
Amofin Adeoye fikun pe awọn to n ta ẹya ara oko ko jasi iku ẹnikẹni, nitori ọrọ ti ko bojumu ni Malami sọ.
'O fihan gbangba pe Malami ko mọ iṣẹ rẹ gẹgẹ bi olootu ijọba, nitori itiju lo jasi fun Naijiria'.
- Ọlọ́pàá ní ká san ₦500,000 fún béèlì baba Ijesha, mo yarí torí ọ̀fẹ́ ni béèlì - Amòfin Ogunlana
- Ìbúgbàmù wáyé nílé ìyáwé-kàwé Obasanjo, mú ẹ̀mí ènìyàn kan lọ
- Yóò dára kí APC kópa nínú ìbò káńsù, kí ẹsín wọn lè hàn sí aráàlú - PDP
- Princess jèbùrẹ́, ọ̀rọ̀ Baba Ijesha gbóná ju èrò ọ̀pọ̀ èèyàn lọ - Adewale Eleso
- Ìdí rèé tí mo fí kọ PDP sílẹ, lọ darapọ̀ mọ́ APC- Ben Ayade
Bakan naa ni Amofin Adeoye salaye pe: 'Malami ko mọ nkankan to n ṣẹlẹ pẹlu awọn araalu nitori o jina si wọn pẹlu ọrọ ẹnu rẹ.'
'To ba jẹ orilẹ-ede miran to mọ eto awọn araalu ni, bi Malami ṣe sọ ọrọ naa tan lo yẹ ki aarẹ orileede Naijiria jawe lo gbe ile rẹ fun un.'
Agbejoro Ola Fatai wa rọ awọn gomina lati ri wi pe wọn fi ofin naa mulẹ pe ko gbọdọ si dida ẹran kaakiri igboro.

Oríṣun àwòrán, @akeredolu
Malami, a kò ni yí ọkàn wa padà lórí ìpinnu wa nípa Fulani darandaran- Akeredolu
Malami, a kò ni yí ọkàn wa padà lórí ìpinnu wa nípa Fulani darandaran- Akeredolu
Gomina Oluwarotimi Akeredolu lo buwolu atejade tuntun kan to jade pe o to ge fun awon darandaran lati maa da eran kiri igboro.
Akeredolu ni oun jade wa fesi leyin ti oun ri atejade kan ti won ni o wa lati odo Malami to je minista fun eto idajo ni Naijiria.
O ni atejade Abubakar Malami naa soro tako ohun ti awon gomina Iwo oorun guusu Naijiri fenuko le lori pe ko si dida eran maalu rin kiri igboro mo
Akeredolu ni ko dara bi Malami se fi dida eran rin kiri igboro we tita ohun eelo eya ara moto ni ariwa Naijiria rara.
O ni o seni laanu pe Malami ko fi ara re sipo ọwọ gẹgẹ bo se tọna ni ipo idajo lorile ede Nanijiria ati pataki ipo to di mu.
Akeredolu ni oju ti la lagbaye ninu eto ọgbin ju ki eeyan si maa da maalu kiri bẹẹ.
O ni iyato wa laarin okowo mejeeji ti Malami mẹnuba sira wọn.
Akeredolu ni titesiwaju lati maa huwa tani o mu mi bi awon darandaran kan se n se si ibanuje awon agbegbe ti wọ́n n gbe kudiẹ kaato
Akeredolu menuba ọ̀pọ̀ ẹ̀mi ati dukia to ti sọnu nitori iwa ika awon kan ni NAijiria.
O gba Adajo Malami niyanju lati gbe ẹjọ naa l sile ẹjọ́ ti ko ba tẹ́ Adajo Malami lọ́run lori igbeseẹ̀ awon Gomina ilẹ̀ Yoruba.
Akeredolu ni pelu ayo ni oun ati awon gomina guusu Naijiria a pade Malami nile ẹjọ́.














