Lagos sexual offences: Àwọn afurasí afipábánilòpọ̀ 206 wọ gàu l'Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọjọ gbogbo ni tole, ọjọ kan bayii ni ti oloun gẹgẹ Yoruba ṣe maa n wi.
Ijọba ipinlẹ Eko ti kede pe ọwọ ti tẹ afurasi afipabanilopọ mẹfa le lugba kaakiri ipinlẹ naa.
Kọmiṣọnna eto idajọ to tun jẹ agbẹjọro agba ipinlẹ Eko, Moyosore Onigbanjo lo fidi ọrọ yii mulẹ fawọn akorọyin nileeṣẹ ijọba ni Alausa, Ikeja.
- Èèmọ̀ wọ̀lú! Àwọn jàndùkú jí Adájọ́ gbé lọ nínú kóòtù lọ́sàn án gangan
- Ìwà ọ̀daràn yóò dínkù tí ìjoba bá bẹ̀rẹ̀ sí ní pa àwọn ọ̀daràn tí wọ́n bá mú- Oluwo ti Iwo
- Wo ojú àwọn ọmọ Yahoo tí EFFC lọ́ mú l‘Osogbo, tí ọ̀rọ̀ fi dariwo
- Ahmed Isah, Ordinary President, ṣàlàyé ìdí tó fí dá ìgbájú-ìgbámú bó obìnrin lórí afẹfẹ
- Ẹ̀yin tí ẹ sọ pé irọ ni mo ń pa bayii ni yoo ri fún yín
Onigbanjo ṣalaye pe igba eeyan ati mẹfa lawọn ti ẹsun ti wọn kan wọn niiṣe pẹlu ifipabanilopọ ninu ojilelugba eeyan le ẹyọkan ti wọn n ka ọwọ sẹyin rojọ.
Bakan naa ni kọmiṣọnna eto idajọ sọ pe awọn ileẹjọ alagbeka ti ijọba ṣẹṣẹ da silẹ gbọ ẹjọ to le lẹgbẹẹrun lọna ọgọta laarin ọdun kan.
O ni awọn awakọ to n rin loju ọna bọọsi BRT, awọn to n taja loju titi to fi mọ awọn to n tapa si ofin ati dena itankalẹ arun covid-19 lo ti foju ba ileẹjọ.
Onigbanjo fikun ọrọ rẹ pe ẹjọ to din diẹ ni ẹgbẹrun meji lo wa kaakiri ileẹjọ giga ati ileẹjọ majisreeti to fi mọ awọn afurasi mẹwaa ti wọn lu awọn oṣiṣẹ LASTMA.
Kọmiṣọnna eto idajọ tun ṣalaye pe awọn to n taja loju titi, awọn to n ri kaakiri at'awọn ti wọn fẹsun kan lori ọrọ ayika yoo ṣiṣẹ sin ilu fun ijiya ẹṣẹ wọn.
Onigbanjo fi dawọn eeyan ipinlẹ Eko loju pe ijọba yoo maa tẹsiwaju lati maa ba awọn agbofinro ṣiṣẹ lati gbogun ti iwa ibajẹ.














