Ordinary President: Inú mi kò dùn pé mo gbá obìnrin létí lórí afẹ́fẹ́

"Gẹgẹ bi baba, inu mi ko dun si bi mo ṣe da igbati bo obinrin lori afẹfẹ."
Gbolohun abamọ to n jade ree lẹnu Ordinary Ahmed Gbajugbaja atọkun eto ajafẹtọmọniyan kan ni ilu Abuja .
Ahmed, ti ọpọ mọ si Ordinary President ṣalaye idi to fi hu iwa yii, to si ni inu oun ko dun si iwa aibọwọ fun ẹtọ ọmọniyan toun hu yii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Lizzy Anjorin sọ̀rọ̀ sókè lórí obìnrin tó ń ba fa sùrútù torí ọkọ rẹ̀
- Níbo ni Baba Ijesha wà lẹ́yìn wákàtí 48 tí wọ́n gba béèlì rẹ̀?
- Wo ojú àwọn ọmọ Yahoo tí EFFC lọ́ mú l‘Osogbo, tí ọ̀rọ̀ fi dariwo
- Ẹ fún wa láàyè díẹ̀ si, kẹ tó fòfin de ẹ̀ran dídà nígboro - Fulani darandaran rawọ́ ẹ̀bẹ̀
- Òkú jíndé nígbà tó ku ìṣẹ́jú péréte ti wọ́n yóò se ètò ìkẹyìn fun
- Àwọn nọ́ọ̀sí àti àwọn òṣìṣẹ́ mííràn tó darapọ̀ mọ́ ìyásẹ́lódì le gbà ìwé ìdádúró
- Ọwọ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ sí Gómìnà Ogun ségi lórí ẹsùn jìbìtì $350,000
Ninu fọnran fidio kan to fi si oju opo Youtube lo ti sọrọ naa ni idahun si ariwo to gbode lẹyin fọnran fidio iwadii BBC, to ṣafihan aṣemaṣe ti ajafẹtọ yi hu si arabinrin kan.
Obinrin yii lo da karosini sori ọmọdebinrin ọmọ ọdun mẹfa lori to si dana sun.
Oludasilẹ ati oludari ileesẹ eto Berekete Family ni lọjọ ti iṣẹlẹ yii waye, o ti rẹ oun gan nitori oun da eeyan to to igba lohun.
''Lọwọ irọlẹ ti a ti pari eto tan, ni wọn ṣẹṣẹ gbe arabinrin naa ati ọmọde to bu kẹrosini si lori wa.
Bi obinrin naa ti ṣe n sọrọ ko ṣe bi ẹni to kabamọ nkan to ṣe rara. Koda awọn eeyan mii to wa nita fẹẹ le maa lu obinrin naa nitori bo ti ṣe n sọrọ.''

Oríṣun àwòrán, Screen Shot
O tẹsiwaju pe ''Aworan fidio ti ẹ ri yẹn, BBC ati Peter Nkanga ati awọn ti wọn jijọ wa ya, wọn kan gbe ibi to wu wọn sita ni .
Mo rọ gbogbo ẹyin alatilẹyin berekete family kaakiri agbaye, kẹ ṣadura pe gbogbo nkan ti BBC ati awọn ti wọn ṣiṣẹ yii ba gba lero, ki ero wọn maa pada si wọn lori.''
O ni ki awọn eeyan fi ọrọ ro ara wọn wo gẹgẹ bi obi, ki wọn to le da oun lẹbi pe oun gba arabinrin kan leti lori afẹfẹ.
Lẹyin naa lo sọ bi oun ti ṣe digbaju ru obinrin naa.
''Nkan ti mo fẹ wadi lọdọ rẹ ni pe, ta lo sọ fun pe Ajẹ ni ọmọde yi? Iwadii yii ni mo n ṣe ti inu fi bi mi, ti mo fi gba oju ẹ.
Mo tọrọ aforiji, inu mi ko dun si nkan ti mo ṣe yii wi pe mo fọ obinrin leti.
O ni gẹgẹ bi ẹlẹran ara,''mi o ni ọmọ ọkunrin, ọmọ obinrin meji ni mo ni, mo wa fi ọrọ ro ara mi wo, lo mu mi ṣe bẹẹ.
Gbara ti mo da igbati bo arabinrin naa, ni mo bẹrẹ si ni kabamọ nkan ti mo ṣe.
Lara ọrọ ti Ahmed sọ ninu fọnran naa tun ni bo se naka abuku si oniroyin iwadii Peter Nkanga pe awọn ọta oun ati awọn eeyan kan ninu ijọba lo lo o lati wa iṣubu oun.
O ṣalaye pe awọn ileeṣẹ ijọba ti ko mojuto ojuse wọn, kii ṣe pe oun n bawọn du ipo, bi kii ṣe pe oun ṣe aanu fawọn mẹkunnu.
Gẹgẹ bo ti ṣe sọ, ka ni wọn n ṣe ojuṣe wọn ni, awọn eeyan ko ni maa wa sori eto lọdọ rẹ.



















