Baba Ijesha: Agbẹjọ́rò ní àwọn kan ló dúró pé ojú ló fi ri béélì, ètè rẹ̀ kò ní bà á

Oríṣun àwòrán, babajesa/Instagram
Ariwo "nibo ni Baba Ijẹṣa wa? Nibo ni Baba Ijẹṣa wa?" ni ibeere ti ọpọ n beere lori ayelujara bayii.
Ibeere naa gbalẹ kan lẹyin wakati mejidinlaadọta ti adajọ ile ẹjọ Majisireeti agba kan nipinlẹ Eko, fun gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Olanrewaju Omiyinka ti ọpọ mọ si Baba Ijẹṣa ni anfani beeli,
Ibeere si idahun yii ni pe, titi di asiko ti a fi n ko iroyin yii jọ, ahamọ ọlọpaa, ni ẹka ọtẹlẹmuyẹ to wa ni Panti nilu Eko ni Baba Ijesha ṣi wa o.
- Baba Ijesha yóò jẹ́jọ́ ìwà tó hù, ohun tó bá gbà, ni màá fun - Iyabo Ojo
- Iyabo Ojo fèsì lórí béèlì tí wọ́n fún Baba Ijesha
- Béèlì Baba Ijesha kò túmọ̀ sí ìdáláre, iṣẹ́ sì ń bẹ níwájú - Yomi Fabiyi
- Princess pàrokò ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lẹ́yìn tí Baba Ijesha gba béélì
- Baba Ijesha gba béélì níléẹjọ́ Májísírétì, àmọ́ ọ̀rọ̀ kù kó tó jáde l’àhámọ́
- Ẹ fi Baba Ijesha sílẹ̀ fún mi, màá ṣe onídùróó rẹ̀ - Yomi Fabiyi
- Màá pe Kọ̀mísánà ọlọ́pàá Eko àti igbákejì rẹ̀ lẹ́jọ́ lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha - Amofin
- ''Àwa àgbààgbà òṣèré kò dákẹ́ lórí wàhálà láàrin Iyabọ Ojo ati Yomi Fabiyi nitori Baba Ijẹsha''
- 'Nígbá tí a rí Baba Ijesha lónìí ní Panti, ohun tójú wa rí, ẹnu kò lè sọ o!'
- Ṣé lóòtọ́ ni Iyabo Ojo ti bẹ Yomi Fabiyi lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha tó wà ní Panti?
Ki wa lo sokunfa bi ọrọ yii se ri, ki lo n da Baba Ijesha duro lati lọ sile lẹyin ọjọ meji to gba beeli?
Nigba to n wa idahun si awọn ibeere yii, ti BBC News Yoruba takoto rẹ si, ọkan lara awọn agbẹjọro Baba Ijesha, Amofin Adeshina Ogunlana ṣalaye wi pe, wọn ko tii ri ọrọ beeli rẹ yanju ṣugbọn o ṣeeṣe ki ọsan ko so didun laipẹ.
"Ni bi mo ṣe mọ ati bi mo ṣe wa yii, O (iyẹn Baba Ijesha) ṣi wa nibẹ (Panti)"
Nigba ti a beere nipa igba ti o ṣeeṣe ki nnkan bọ soju ọwọ fun agba apanilẹrin naa, Amofin Ogunṣina ni oun a fẹ ki a ṣi ni suuru di irọlẹ Ọjọru lati mọ bi nnkan yoo ṣe lọ si fun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọmọ Yahoo gba ọkọ̀ 25 padà lọ́wọ́ ẹ̀ṣọ́ EFCC lásìkò tí wọn dènà dè wọ́n l‘Osogbo
- Ẹ fún wa láàyè díẹ̀ si, kẹ tó fòfin de ẹ̀ran dídà nígboro - Fulani darandaran rawọ́ ẹ̀bẹ̀
- Òkú jíndé nígbà tó ku ìṣẹ́jú péréte ti wọ́n yóò se ètò ìkẹyìn fun
- Àwọn nọ́ọ̀sí àti àwọn òṣìṣẹ́ mííràn tó darapọ̀ mọ́ ìyásẹ́lódì le gbà ìwé ìdádúró
- Ọwọ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ sí Gómìnà Ogun ségi lórí ẹsùn jìbìtì $350,000
- Àwọn ọmọ Yahoo dènà de ẹ̀ṣọ́ EFCC tó fòru wọ̀lú l'Osogbo, nǹkan yan
- Àwọn nọ́ọ̀sí àti àwọn òṣìṣẹ́ mííràn tó darapọ̀ mọ́ ìyásẹ́lódì le gbà ìwé ìdádúró
- Nàìjíríà ti rí €4.2m gbà padà nínú owó tí James Ibori gbé- Malami
- Wo ìdí mẹ́fà tí ìjóba kò se tíì kápá Boko Haram
Bakan naa ni agbẹjọro naa ko ṣalaye nipa ilana gbigba beeli afurasi naa to takoko, ti wọn ko tii ri ọna se amusẹ rẹ fun gbigba beeli afurasi naa.
Amofin Adeshina Ogunṣina wa kọminu lori ilana eto idajọ ati ofin lorilẹede Naijiria.
O ni o ṣeni laanu pe, bi ofin to tọ ṣe wa to lorilẹede Naijiria, awọn to wa ni idi aro ifidimulẹ ofin wọnyi ni ka bẹ, lati ṣe ohun to tọ nigba gbogbo.
Amofin ni ohun to ku diẹ kaa to ni pe adajọ ni lati dide lọ si ahamọ ọlọpaa ni Panti, lati rii daju pe idajọ ododo wọle tọ Baba Ijẹṣa lọ amọ sibẹsibẹ, o ni awọn kan ṣi duro ni iduro pe 'oju lo fi ri beeli naa, ete rẹ ko ni kan an"




















