Baba Ijesha: Ọlọ́pàá kò fún Omiyinka láàyè láti ṣa ikọ̀ agbẹjọ́rò rẹ̀ jọ

Bi ọrọ ba se n pẹ nilẹ, yoo maa gbọn si ni, bayi si ni ọrọ Baba Ijesha da bayii lori ayelujara.
Gbogbo atotonu tawọn ilumọọka si n se lori ẹsun sise asemase pẹlu ọmọde ti wọn fi kan Baba Ijesha, tii se osere tiata, ni ko tii lọ sodo lọ mumi.
Ni ọsan ọjọ Aiku, ni gbajumọ osere tiata nni, Yomi Fabiyi tun gbe fidio miran jade lati tako awọn ọlọpaa lori bi wọn se kọ lati gba beeli Baba Ijesha.
- 'Nígbá tí a rí Baba Ijesha lónìí ní Panti, ohun tójú wa rí, ẹnu kò lè sọ o!'
- Davido sí Yomi Fabiyi: Mùmú ni ẹ́
- Ẹ̀sùn gbígbìyànjú láti wọ́lé sí ojú ara ọmọdé pẹ̀lú ìpá àtàwọn ẹ̀sùn mìí tí Baba Ijesha yóò jẹ́ rèé
- Bí àwọn gbajúmọ̀ ṣe pín rèé lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha
- Iyabo Ojo gbé fídíò jáde nípa bí ọwọ́ ṣe tẹ Baba Ijesha
- Orí yọ ẹ́ o Baba Ijesha tí mi ò rí fídíò èpè tí wọ́n ní ò ń ṣẹ́, ǹkan tí mi ò bá ṣe fún ẹ... - Iyabo Ojo
- Iyabo Ojo fi ẹ̀hónú hàn ní àgọ́ ọlọ́pàá Panti láti tako béèlì Baba Ijesha
Nigba to n salaye ibi ti ọrọ naa de duro, Fabiyi ni orukọ ti wọn n pe Baba Ijesha pe abọmọdelopọ ni, ko tọ si rara nitori pe ọmọ to wa pẹlu rẹ kii se ọmọde.
Bakan naa lo salaye pe ko si ẹri pe Baba Ijesha ba ọmọ naa sun nitori pe iya ọmọ naa kan sin awọn osisẹ lọ si isalẹ ile rẹ ni.
O fikun pe awọn eeyan kan lo dẹ pakute fun osere tiata naa, ti oun naa si rọ lu u nitori o dabi pe wọn fẹ pa Baba Ijesha ni.
Bakan naa lo salaye pe titi di akoko yii, awọn ọlọpaa ko fi aaye gba afurasi naa lati ko ikọ agbẹjọro rẹ jọ, ko le mọ ohun ti yoo se tabi sọ nile ẹjọ.
O wa n beere pe nigba tawọn ọlọpaa ko fun afurasi naa laaye lati seto nipa awijare rẹ, to ba wa jare nile ẹjọ nkọ?
"Ti wọn ba ti ba ilera rẹ jẹ, ba isẹ ọwọ rẹ jẹ, to fi mọ orukọ ati gbogbo ohun to ni, ki ni yoo sẹlẹ ti adajọ ba da lare nile ẹjọ?
Ofin ilẹ wa gbe kalẹ pe ki wọn fun afurasi nile ẹjọ, koda gan, ẹni to pa eeyan gan ni anfaani si beeli, yoo si dara ki wọn bẹru Ọlọrun.
Ẹ mase joko sori ayelujara lati maa se idajọ ti ko tọ, ẹ kan n lọ silu oyinbo lasan lai kọgbọn nibẹ."
Yomi Fabiyi wa n ke si awọn ọlọpaa lati fi Baba Ijesha silẹ fun oun, ki oun si duro bii oniduro fun nitori ko tiẹ tii mọ iru awọn ẹsun ti wọn fi kan."
Osere tiata naa fikun pe lasiko ti oun lọ bẹ Baba Ijesha wo ni ahamọ, o ni se lo tako iwọde ti oun fẹ se lati beere fun beeli rẹ.
Amọ o ni oun sọ fun Baba Ijesha pe oun ko se iwọde naa nitori tiẹ nikan, amọ nitori ki oun le ja fun ẹtọ ọmọniyan ni.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ìdí méje tí olólùfẹ́ rẹ fi le kọ ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ
- Òfin tí yóò fààyè gba obìnrin láti ní ọkọ méjì ń bọ̀ lọ́nà
- Màá pe Kọ̀mísánà ọlọ́pàá Eko àti igbákejì rẹ̀ lẹ́jọ́ lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha - Amofin
- Ojú mi rí màbo nígbà tí mo bímọ àkọ́bí, ẹ̀ṣẹ̀ ni ká bímọ láì rí owó tọ́jú rẹ̀ - Lizzy Anjorin
- Shehu Sani fi olùwọ́de Yoruba Nation ṣe ẹlẹ́yà torí òjò tó tú wọn ká
- Àgbà ọ̀jẹ̀ akọrin Fuji, Amoo Igisekele, jáde láyé
- Àwọn olùwọ̀de Yoruba Nation mú afurasí òṣìṣẹ́ DSS níbi ìwọ́de l‘Osogbo
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá rí ọmọ oṣù kan he lẹ́ba ọ̀nà lẹ́yìn tí wọ́n gbé e sọnù l'Eko
Yomi fabiyi ni oun kii se afipabaọmọdelopọ tabi afipabaagbalopọ, to si n sẹ epe fun gbogbo awọn eeyan to n pe ni orukọ buruku yii.
"Idi ti n ko fi sọ oko ọrọ si Iyabo ni pe o ti se awọn ohun to dara fun mi saaju, bẹẹ lo si dide lati sugba mi nigba ti iya mi ku.
To ba jẹ ẹlomiran lo dan wo, ẹni ti ko ni orukọ lọdọ mi, yoio tii da mọ, yiyọ ẹkun mi, tojo kọ, n ko si fẹ mọ boya eeyan jẹ ololufẹ mi tabi bẹẹ kọ."
Fabiyi wa n fi ika hanu pe o ya oun lẹnu pe awọn agbaagba ati asaaju to yẹ ko dide lagbo osere tiata lori ọrọ baba Ijesha ko dide rara si ọrọ naa.





















