Sex Denial: Wo àwọn ìwà to ń hù tí olólùfẹ́ rẹ fi lè fi ìbálòpọ̀ jẹ ọ́ níyà

Awọn dokita onimọ nipa ibalopọ tun sọ pe ibalopọ maa n ran tọkọ taya lati gbaradi fun ipenija.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ni orilẹede Naijiria, ọpọ ibasepọ tabi igbeyawo lo n fori sanpọn nitori ọrọ ibalopọ.

Ninu ọpọ idile ti ayọ wa tẹlẹ, ni irufẹ ayọ bẹẹ ti dinku nitori awọn idi kan ti wọn ko le ṣalaye fun araye.

Lọpọ igba lo jẹ pe ko si idi miran ti ede aiyede fi n waye laarin ololufẹ, paapaa laarin lọkọ-laya, bikoṣe nipa aisi ibalopọ deede tabi ibalopọ ti ko tẹ ọkọ tabi aya lọrun.

Onkọwe kan nipa ibalopọ laarin tọkọtaya, Tammy Nelson sọ fun iwe iroyin Punch pe o ṣeeṣe ki eeyan wa ninu ibanujẹ, ti ẹnikeji rẹ ba n fi ibalopọ jẹ niya.

Nelson sọ siwaju si pe irufẹ ipo bayii lo jẹ ki ọkọ tabi aya irufẹ ẹni bẹẹ maa lero pe ololufẹ wọn ti ni oju miran sita.

oruka igbeyawo

Oríṣun àwòrán, other

Ṣugbọn ki lo le fa ki ọkọ tabi aya maa fi ibalopọ dun ẹnikeji wọn?

Ninu iwadii kan ti ọmọwe naa ṣe, o mẹnuba awọn idi meje ti ololufẹ ẹni le fi maa fi ibalopọ dun ni, awọn idi naa ree:

Ija lemọlemọ ati ariyanjiyan:

Ija ojojumọ ati oniruru ariyanjiyan le ṣakoba fun ibalopọ laarin ọkọ tabi aya.

Gẹgẹ bi Nelson ṣe sọ, ololufẹ rẹ le ni ọ sinu eyi to le mu ko ma fẹ ni ibalopọ pẹlu rẹ lasiko ti ija naa ba ṣi n lọ lọwọ.

Ni iru akoko bayii, Nelson gba tọkọ-taya niyanju lati pari aawọ to ba wa laarin wọn, ki wọn to gbiyanju lati ni ibalopọ kankan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Wahala ojojumọ:

Ko rọrun lati jẹ eeyan nile aye, ẹnikẹni ti ko ba fẹ ṣe ẹru ẹgbẹ rẹ gbọdọ mura si iṣẹ, oju bọrọ ko si ṣe gba ọmọ lọwọ ekurọ.

Wahala jijẹ-mimu le mu ki ibalopọ maa run si awọn ẹlomiran.

Fun apẹrẹ, ẹni to n gbe ni ilu Eko to ti lo ọpọ wakati ninu sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ, le ma fẹ ṣe ere ifẹ pẹlu ololufẹ rẹ lẹyin to ba ti de ile tan.

Àkọlé fídíò, Olaiya Igwe: Ilà ójú mi, ló wà lójú ìyá MC Oluomo, ọ̀gá àti àbúrò mi ni – Olaiya Igwe

Iwa ti ko dara:

Onimọ nipa ibalopọ kan ni ipinlẹ Eko, Chinwe Adeniyi sọ pe o ṣeeṣe ki ololufẹ ẹni kọ ibalopọ lẹyin ti eeyan ba ti bẹrẹ si n hu awọn iwa kan ti ko tẹẹ lọrun.

Chinwe ni "Fun apẹrẹ, ti eeyan ba dede di alara kikan, ololufẹ irufẹ ẹni le maa sa fun to ba ti to akoko ibalopọ."

Ti eeyan ba kọ lati fọwọ kan ololufẹ rẹ fun ọpọ ọjọ:

Awọn onimọ sọ pe ibi ti ibalopọ ti bẹrẹ ni ifẹnukonu, fifi ọwọ kan ara ọkọ tabi aya, ati bẹẹ lọ.

Gẹgẹ bi ohun ti Nelson sọ "Awọn nnkan kekeke bii ki ololufẹ fi ọwọ kan ara wọn, ki wọn di ọwọ ara mu lawujọ, ati bẹẹ lọ le tunbọ jẹ ki ifẹ wọn gbilẹ si, yoo si mu ki ibalopọ rọrun."

Ibalopọ ti ko nina ninu:

Onkọwe kan to tun jẹ onimọ nipa ibalopọ nilẹ Amẹrika, Dawn Michael ni ibalopọ ko gbọdọ jẹ ohun ti eeyan yoo maa ṣe loju kan soso, ni ipo kan ati gẹgẹ bii aṣa adayeba ti laa kalẹ.

O ni tọkọtaya gbọdọ mu ara ọtọ wọ inu ibalopọ wọn ko le ni ina ninu, ki wọn to le gbadun rẹ daadaa.

Dokita naa ni ti tọkọ-taya ba kọ lati ṣe eyii, o le tete sun eyikeyi ninu wọn, ki wọn si maa sunra ki fun ololufẹ wọn.

Àkọlé fídíò, Pains and Pleasure Band: Ọ̀pọ̀ àwọn akọrin tó ní ìpèníjà ojú ló jẹ́ Ẹnjiníà, atagìtá

Aniyan lori bi ibalopọ naa yoo ṣe ri:

Oriṣiriṣi ireti lo ṣeeṣe ko waye ṣaaju ibalopọ, ti awọn ireti yii ba ti pọ ju, paapaa fun ọkunrin, o ṣeeṣe ki irufẹ ọkunrin bẹẹ ma le ṣe to bo ṣe lero tabi bo ṣe yẹ.

Nelson ni ti eeyan ba ti n ro bi oun yoo ṣe ṣe daadaa ninu ibalopọ, o ṣeeṣe ki irufẹ ẹni bẹẹ ja ololufẹ rẹ kulẹ.

Awọn onimọ nipa ibalopọ, William Masters ati Virginia Johnson sọ pe eeyan ko nilo lati maa ṣaniyan nipa ibalopọ, o kan ni lati ni ifẹ si ibalopọ nikan ni.

Aini ifẹ si ibalopọ bo ṣe yẹ:

Kii ṣe gbogbo eeyan lo nifẹ ibalopọ, awọn miran fẹran ibalopọ bi ounjẹ, bẹẹ si ni awọn miran kọbi ara si.

Bi awọn kan ṣe le ni ibalopọ ojojumọ lawọn mii le wa fun ọpọ ọjọ, ọsẹ tabi lai ni ibalopọ, eyii to le fa iṣoro ninu ile fun tọkọ-taya.

Fun irufẹ awọn ti ko kundun ibalopọ bayii, awọn onimọ sọ pe ki wọn maa sun daadaa, ki awọn jẹ awọn oujẹ to le ṣe ara loore ki wọn si tun maa ṣe ere idaraya dede lọna ati ṣẹgun idojukọ naa.

Àkọlé fídíò, Iya àwọn aderinposonu ìbejì tí ọ̀pọ̀ mọ sì Twinz Love ṣàlàyé ìrìnàjò rẹ pẹlu awọn ọmọ rẹ