Sex enjoyment Yinka TNT: Ìye ìgbà tóo ní ìbálòpọ̀ kọ́ ló ń jẹ́ kí abẹ́ obìnrin fẹ̀

Àkọlé fídíò, Tóò bá fún ọkùnrinn lóúnjẹ́ tóo tẹ́ kiní yẹn sílẹ̀ fún un dáadáa... - Yinka TNT

"O lereju abẹ ti ọkunrin maa n fẹ ba le, ti wọn ba ti wọle ti wọn ri i pe awọn ja lu Express, wọn a sa pada".

Bẹẹ ba wo awọn onimọ nipa ibalopọ jakejado agbaye, wọn o ki n fẹ keeyan maa ṣẹnu ku pe awọn ẹya ara to wa fun ilo ibalopọ lakọ labo.

Ko yọ Yinka Ayanda ti ọpọlọpọ mọ si "Yinka TNT" silẹ pẹlu bo ṣe tẹnu mọ ọ pe "bi ẹ ṣe n pe oju ara yẹn o maa n bi mi ninu, ẹ wa orukọ mii to dun fun un".

O dabaa awọn orukọ kan bii Agbekẹ, Kabiyesi, Amuniṣiwi, Amunirẹrinmusẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Bi ti ọkunrin lo wa n sọ ni tabi ti ara obinrin, awa o le pin in si isọri.

Ilu London ni Yinka Ayanda wa to ti n ṣe iṣẹ to yan laayo lati maa ba awn kunrin ati obinrin sọrọ nipa gbigbadun ibalopọ ko da o ni eto lori ayelujara ti ọpọlọpọ maa n rọ bo lati wo olorin si ni pẹlu.

Yinka TNT

Oríṣun àwòrán, Yinka TNT/Facebook

Koda lasiko ti a n fi ọrọ wa Yinka TNT lẹnu wo, o ni i lara gan lati maa ṣẹnu ku pe awọn ẹya ara yii eyi to ti mọ ọ lara gẹgẹ bi onimọ nipa ibalopọ lakọ labo.

Amọ nitori ofin iṣẹẹ tiwa, kii ṣe gbogbo ọrọ lo ṣee sọ sita tori oniruuru eeyan lo n ka iroyin wa tabi wo fọnran ti a ba fi sita, bẹẹ si ni a gbudọ jẹ ki ohun gbogbo dọgba fun awọn ololufẹẹ wa.

Sibẹ sibẹ lori iru ọr bayii, ani lati fii lẹ bẹẹ ki alejo wa sọ oju abẹ niko nipa awọn ọrọ kọọkan ti ko ṣee tẹnu bọlẹ sọ nipa ibalopọ.

Yinka TNT

Oríṣun àwòrán, Yinka TNT/Facebook

Iwadii fi han pe ọpọlọpọ nkan ti a ṣẹnu ku sọ nipa ibalopọ lo n ko ba ọpọlọpọ igbeyawo to si ti jẹ ọpọlọpọ wọn tuka.

Ẹwẹ, alejo wa ki ẹnu bọ ọrọ lorii bi ẹ ṣe le gbadun ibalopọ, ohun to n jẹ ki ọkunrin wo ita, ohun to n jẹ ki obinrin di ọga ara rẹ tabi sa fun ibalopọ pẹlu ololufẹ rẹ.

Ọrọ pọ ninu iwe kọbọ.