Rwanda Sex: Wo bí àwọn obìnrin yìí ṣe máa ń gbáradì ojú abẹ́ wọn fún ìbálòpọ̀

Àkọlé fídíò, 'Ó ṣe pàtàkì kí obìnrin gbádùn ìbálòpọ̀ nítorí...'

Ni orilẹede Rwanda, wọn maa n ṣe igbelarugẹ ibadọgba akọ ati abo ninu ọpọlọpọ nkan bii oṣelu, eto ẹkọ atawọn ọrọ to kan araalu.

Ṣugbọn wọn o ba a mọ nibi awọn nkan to ṣee foju ri lawujọ nikan o, wọn tun n ṣe igbelarugẹ ọrọ ibalopọ laarin lakọ labo.

Eyi fun awọn eeyan lanfani lati maa sọrọ bi wọn ṣe n ba ara wọn lo pọ tabi bo ṣe wu wọn lati ṣe e tabi bi bi wọn ṣe n ni imọlara rẹ lasiko ibalopọ.

Sọrọ ori rẹdio yii ba kii fi para rara bẹẹ si ni kii ṣẹ ẹnu rẹ ku nipa ọrọ ibalopọ. O ba BBC sọrọ nipa bo ṣe maa n ran awọn obinrin lọwọ lori eto rẹ, koda bo ṣe maa n lọ kọ wọn ni ere idaraya to lee mu ara wọn dide fun ibalopọ.

Ọrọ Ibalopọ