August Alsina: Ohun tó ṣẹlẹ̀ rèé láàrin wa àti àlè ìyàwó mi

Oríṣun àwòrán, Red table talk
Ilumọọka olorin August Alsina ti fesi si ọrọ ti ololufẹ tẹlẹ, Jada Pinketh Smith sọ pe oun atirẹ n ba ara wọn lajọṣepọ lasiko toun ati ọkọ rẹ fi pinya.
Lọjọ ẹti to kọja ni ọrọ naa bẹrẹ si ni ja rayin-rayin lori ayelujara lẹyin ti Jada funrarẹ sọ ẹkunrẹrẹ bi wọn ṣe maa n laṣepọ lori eto kan to maa n ṣe lori Facebook, Red Table talk.
Awọn ololufẹ meji maa n ṣe ere ifẹ daadaa ti akọrin naa si ni oun gba aye lọwọ ọkọ Jada ki oun to maa ba a ṣe ere ifẹ to wọra to bẹyẹn. Ẹwẹ arabinrin hun ni oun ko mọ idi to fi n sọ tabi to tilẹ fi nilo aaye lọwọ ọkọ oun tori awọn ti pinya nigba naa.
Ṣugbọn oun ati ọkọ rẹ ti pada pari ija to wa laarin wọn bayii, ni ọrọ ṣe di akara tu sepo lẹnu ọjọ melo kan sẹyin.
Ni nkan bii alẹ ana ni olorin naa, August Alsina ba bọ soju opo Twitter lati ta a pada si Jada ati ọkọ rẹ pe:
"Mi o mọ bi ẹ o ṣe le kojumọ owo to pee yin. Gbogbo bo ṣe n lọ lo ye mi daadaa. Kii ṣe ọrọ eni. Ohunkohun to ba wu yin ni kẹẹ pe mi. Ṣugbọn ẹrẹ lẹ n ko rọ ara yin pẹlu dida si ọrọ ti ko kan yin".
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Nibo lọrọ ti bẹrẹ?
Ara meriri, mo ri ori ologbo lori atẹ ni ọrọ kan to n gbona lori ayelujara bayii, ti wọn n pe ni igbeyawo ti ko ni kọlọfin kankan ti wọn n fi nnkan pamọ si, Open Marriage.
Fun ọpọ ọmọ Kaarọ oo jiire, o lee dabi ọrọ rirun tori owe kan to ni, ‘obinrin ko le e laya laya, ko fi ale rẹ han ọkọ rẹ.’
Amọ eyi ko ri bẹẹ mọ lode oni nitori isẹlẹ kan to waye lọjọ Ẹti ninu idile kan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kí ló mú Obasanjo ti ilẹ̀kùn mọ́ ẹbí, òṣìṣẹ́, ojúlùmọ̀ ní ibi òkú àna rẹ̀?
- Wọ́n fi ikú Tunde Braimoh dá wa lóró ni o - Ẹbí pariwo
- Ẹ̀yin ọmọ ìta tó ní Funke Akindele ra ilé fún mi, irọ́ ni o - Ajirebi
- Ìtàn ayé Henry Fajemirokun, olówó tó fi owó mọ Olúwa àti ènìyàn
- Báwo ni Coronavirus ṣe n tànkálẹ̀ l'Afrika?
Idile kan ree ti tọkọ-taya, Will Smitt ati iyawo rẹ Jada Pinkett Smith jẹ gbajumọ osere tiata nilẹ Amẹrika, ti wọn si se igbeyawo lọdun 1997, Ọlọrun si fi ọmọ meji si aarin wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Sugbọn laipẹ yii ni ọkunrin akọrin kan, August Alsina, tii se ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, sọ loju opo Facebook rẹ pe, oun ati osere tiata lobinrin naa, Jada Pinkett Smith jọ ni ajọsepọ ri .
Akọrin naa ni oun lọ ba Will Smitt, tii se ọkọ to fẹ obinrin osere tiata naa sile, lati gba asẹ lọwọ rẹ pe ki oun maa fẹ iyawo rẹ.
O tẹsiwaju pe Smitt fun oun lasẹ, to si fọwọ si lati maa fẹobinrin naa, eyi to fidi rẹ mulẹ pe, tọkọtaya gbajumọ osere yii dijọ n ni ifẹ miran nita gbangba lẹyin igbeyawo wọn.
Sugbọn gbajumọ osere lobinrin naa ti fesi sọrọ ọhun, to si ni oun ati ọkọ oun mu akọrin naa, August Alsina ni ọrẹ ni ọdun mẹrin sẹyin lati ipasẹ ọmọ awọn, Jaden, tii se ẹni ọdun mejilelogun.
Jada, osere binrin naa ni lasiko ti oun ati akọrin naa, August n sere ifẹ, oun ati ọkọ oun, Smith ko dijọ gbe papọ mọ bii lọkọlaya .
"Ori mi gan lo ti bẹrẹ, mo nilo iranlọwọ lori ipo ti ilera ọpọlọ mi wa nigba naa, amọ ọrọ naa bẹyin yọ, ti mo si bẹrẹ ifẹ pẹlu August."
Jada, tii se ẹni ọdun mejidinlaadọta ni awọn ko nilo lati gba asẹ lọwọ ọkọ oun, ki oun ati August to maa sere ifẹ, nitori oun ati Will, ọkọ oun ko gbe papọ mọ nigba naa.

Oríṣun àwòrán, Red table talk
O fikun pe ọrọ ikọkọ ninu ile awọn lo ti wa bọ si gbangba yii, idi si niyi ti oun fi tete da si, bakan naa lo si dupẹ lọwọ ọkọ rẹ pe o n fara da fun oun.
Jada tẹsiwaju pe oun pade akọrin naa, eyiun August ni ọdun mẹrin aabọ sẹyin, tawọn si di ọrẹ korikosun.
O ni igba ti akọrin naa wa sinu ẹbi oun, o dabi ẹni pe aisan n se e, to si nilo iranlọwọ, asiko yii naa si ni inu ile tawọn ko toro.
"Ẹni kan soso to lee fun akọrin naa lati fẹ mi ni emi funra mi, ko si ye mi bo se ni ọkọ mi fun oun ni asẹ lati fẹ mi nitori emi ati ọkọ mi ko gbe pọ mọ nigba naa, bẹẹ ni kii si se ọrọ rẹ lo pin emi ati ọkọ mi niya."
Lọwọ-lọwọ bayii, Will Smith ati aya rẹ, Jada Pinkett Smith ti pada di tọkọtaya, ti ifẹ wọn si n gbona gidigidi.
Ninu ifọrọwerọ kan ti wọn dijọ se lori isẹlẹ yii, tọkọ taya naa ni "A dijọ n wa ọkọ igbeyawo wa lọ ni, a dijọ ku papọ ni, titi aye laa ma lo igbeyawo wa lọ, ko baa ma dara."















