Coronavirus Updates: Báwo ló ṣe n tànkálẹ̀ l'Afrika?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Peter Mwai and Christopher Giles
- Role, BBC Reality Check
Ojoojúmọ́ ní aàrùn coronavirus ń pọ̀ si i láwọn orílẹ̀-èdè Afirika ti ikú tó ń tibẹ̀ wá náà sì ń pọ̀ si i.
Àjọ elétò ìlera àgbáyé (WHO) lo fidi eyi mulẹ.
A wo saàkun bí ǹkan ṣe ń lọ ni gbogbo àgbáyé, a sì wò o pé orílẹ̀-èdè wo lọ̀rọ̀ náà kan jù?
Báwo ni ìtànkálẹ̀ ààrun coronavirus ṣe ya si?
Ti a ba wó iye gbogbo rẹ̀ lápapọ, Afíríkà ló ni iye ènìyàn tó kéré jùlọ lágbayé, sùgbọ́n bi aàrùn náà ṣe ń tàn ka ni afíríkà jẹ́ ǹkan ti ó ń kọ àwọn elétò ìlera lóminu ni ìhà Afirika.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lé ni ọgọ́rún un ọjọ́ ti arún náà ti bẹ̀rẹ̀ kí ilẹ̀ Afíríkà to ri ènìyàn ẹgbẹ̀run lọ́nà ọgọ́run un kan to ní ààrùn náà, síbẹ̀ kò jú ọjọ́ méjìdínlógún lọ ti ó fi di ìlópo méjí ẹgbẹ̀run lọ́nà ìgba tó sì tún dí ẹgbẹ̀run lọ́nà irínwó léyin ogúnjọ́ náà.

Bí ǹkan ṣe wá ń ri ni Afíríkà yìí, ó ti fẹ́ jọ bi ó ṣe rí ni àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé ti aàrùn náà ti ṣe lọ́sẹ́ gidigidi.
Ọ̀pọ̀ àwọn ilẹ́ Afíríká ní Coronavirus tí ń tànkálẹ̀ láàrin ìlú gẹ́gẹ́ bi WHO.
Itúmọ èyí ni pé ti ènìyàn bá ni coronavirus láìṣe pé ó ni ǹkan to nii ṣe pọ̀ pẹ̀lú ẹni to wá láti òkè okun pẹ̀lú aàrùn náà, tàbi tó ní ǹkan ṣe pẹlú ẹni tó nii lábẹ́lé, èyí sì máà n jẹ́ kí o nira fun àwọn elétò ìlera láti wá orísun ibi ri ààrùn náà ti jẹyọ lábẹ́lé.
Àwọn orílẹ̀-èdè Afíríkà wo ni aàrùn náà pọ̀ sí jùlọ?
Àwọn orílẹ̀-èdè ti aàrùn náà pọ̀ si jù ni Afíríkà ni South Africa àti Egypt.
Àwọn ni wọ́n ni ìdá ọgọ́ta gbogbo àwọn àlárùn tuntun ni òpin oṣù June.
Orilẹ̀-èdè South Africa ló ti ni ènìyàn tó pọ̀ jùlọ tó ni aàrùn Covid-19, nígbà ti orilẹ̀-èdè tí ó ní àwọn tó ti kú ikú Coronavirus pọ̀ sí.
South Africa ló kọ́kọ́ pàsẹ kónílé-ó-gbélé to le jùlọ ni oṣù kẹta ọdún yìí.
Síbẹ̀ orílẹ̀-èdè yìí ni aarùn náà ti ń peléke si i lójoojúmọ́ lẹyin ti wọn dẹwọ kónílé-ó-gbéle nínú oṣù karun un, ọdún.
Agbègbè Western Cape ní ilú ti Cape Town wa ló ni ìdaji gbogbo Covid-19 àti ikú rẹ ni South Africa.
Sùgbọ́n díẹ̀díẹ̀ ni aàrun náà ń lọ sóke ni àgbègbè Gauteng tó fi mọ́ Johanesburg.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aàrun náà ń rú gẹgẹ sí i ni láti àárín oṣu karùn-un, sùgbọ́n, o jọ pé o ti de ténté báyìí pẹlu bi aàrùn náà ṣe n dẹnu kọle ni ìbẹ̀rẹ̀ oṣù kẹfa báyìí.
Ní bayìí ǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà ń kọnilọminú, ibẹ̀ ni iye ènìyàn to n kú tún ti pọ̀ jù ṣikeji gẹ́gẹ́ bi abájade ìròyìn àjọ WHO ni ọjọ́ kínní, oṣù keje, ọdún yìí.
Akíyèsí: A le ri àkọsilẹ̀ Egypt tí a bá yan Middle East láti ara akọle tó wà lórí máàpù àti àwọn orilẹ̀-èdè to wà ni ìsàlẹ yìí

Mauritania náà ti n ni àwọn ènìyàn to pọ́ pẹ̀lú aàrùn náà láti ǹkan bi ọsẹ̀ díẹ̀ sẹ́yìn.
Ó ṣe pàtàkì láti sọ orúkọ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n kò fi bẹ́ẹ̀ ni àwọn aláàrùn Covid-19, pàápàá jùlọ láwọ́n ilẹ̀ Afirika tó wà ni ìlà-oorùn.
Kódà, àbọ ìwádìí àjọ WHO tuntun sọ pé àwọn orílẹ̀-èdè Afíríkà mẹwàá ló ni ìdá ọgọ́rún un àwọn to ni aàrun náà ni Afíríkà.
Ènìyàn mélòó ló n kú ní Afíríkà?
Ìye àwọn ènìyàn to ti kú gẹ́gẹ́ bi ìròyìn ṣe fi idi ẹ mulẹ kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀.
Iyẹn ti a bá ṣe àfiwé rẹ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè àgbáye tọ kù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹka ètò ìlera ọ̀pọ̀ ilẹ̀ Afirika kò kójú òṣùwọ́n.
Àjọ WHO sọ pé, ìdí èyí kò ju nítori pé, ọ̀pọ àwọn ènìyàn ilẹ Aduláwọ Afrika kò fi bẹ́ẹ̀ ni àrúgbó púpọ̀.
ìdá ọgọ́ta ní ilẹ̀ Afirika jẹ ẹni ọdún márùndinlọ́gbọ̀n.
O ti di mímọ̀ pé aàrùn Covid-19 sáabà lágbára lórí àwọn tó ti dàgbà.
Ọ̀nà míràn ti a tún lè gbà wò ó ni pé kí a wo iye ènìyàn to ni Covid-19 ti wọn sì bá a lọ.
5%:
Àwọn orílẹ̀-èdè Marun un ti wọ́n ni àwọn ènìyàn tó n kó o ni a ṣe àgbéyẹ̀wò wọ́n sí ara wọn, èyí sì fi han pé o farapẹ bi ǹkan ṣe ri fún ọ̀pọ lágbáye, ni eyi ti ko ju ìdá márun un lọ.
- Chad (8.5%)
- Algeria (6.6%)
- Niger (6.2%)
- Burkina Faso (5.5%)
- Mali (5.3)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Sùgbọ́n ní Githinji Gitahi, olórí Amref Health Africa to jẹ àjọ kan tí kìí ṣe ti ìjọba ti wọ́n sì máà ń mójú tó ọ̀rọ̀ ìlera, sàlàyé pé tí iye ènìyàn tó kú ba pọ̀, ó túmọ̀ si pé iye ènìyàn to ni aàrùn náà pọ̀ ju iye ènìyàn ti wọ́n ni àkọsilẹ̀ rẹ̀ ni.
O ni èyí sì le túmọ sí pé ayẹwò ti wọ́n ń ṣe kò pọ̀ tó.
Bí àyẹ̀wò bá ṣe kéré tó, bẹ́ẹ ni iye ènìyàn to ni ààrun náà ti yóò farahàn, bákàn náà ni àwọn ti yóò kú, yóò wá pọ̀ jọjọ.
Bákan náà ni bí wọ́n ṣe n kéde ikú ọ̀hún le nípa lóri iyé ènìyàn tó kú.
Fún àpẹrẹ, àwọn abúlé ti àwọn óṣìṣẹ́ elétò ìlera àti àwọn òṣìṣẹ́ ilera míràn ṣe n ṣe àkọsílẹ̀ ikú Covid-19, bii ti orílẹ̀-èdè Chad, ó ṣeeṣe kí a ri ikú to pọ̀ ju bóṣe yẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àyẹ̀wò mélòó ní Afíríkà ti ṣe ?
Orilẹ̀-èdè mẹ́wàá lo ni ìdá ọgọ́rin nínú àyẹwò aàrùn náà- South Africa, Morocco, Ghana, Egypt, Ethopia, Uganda, Mauritius, Kenya, Nigeria, Rwanda.
Ìyàtọ gbáà ló wà láàrin àwọn tó ń ṣe àyẹwò, àyẹwò ti South Africa ń ṣe pọ̀ jọjọ jú ǹkan pérété ti Nàìjíríà ń ṣe lọ, èyi jẹ abájade ìwádìí WHO.
Ní ọjọ́ kẹrin, oṣù keje, Orilẹ̀-èdè South Africa ń ṣe àyẹwò ọgbọ̀n nínú ènìyàn ẹgbẹ̀run kan, ká fi wé àyẹ̀wò ènìyàn méjìléláàdọ́rin nínú ẹgbẹ̀run kan ni UK àti márùnlélọ́gọ́run nínú ẹgbẹ̀run kan ni US.
Ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, àyẹwo ti wọ́n ń ṣe kò tó odidi kan nínú ẹgbẹ̀run kan, Mẹ́wàá ní Ghana, mẹ́tà ni Kenya.
O ṣe pàtàkì láti tọ́ka si pé àwọn orilẹ̀ èdè Afíríkà kan, ó nira láti mọ ǹkan tó ń ṣelẹ̀ nítori kò tilẹ̀ sí àkọsilẹ̀ kankan, tàbi kí wọ́n ma pari àkọ́silẹ̀ náà.
"Bí ẹni fi èékánna buyọ̀ ni iye èèyàn ti wọ́n ń sàyẹwò fún bi Chiedo Nwankwor olùkọ́ ni Fásìtì John Hopskin ni America ṣe sọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ní Tanzania, Aàrẹ John Magufuli fi èrò ọkan rẹ̀ han pé kò dáju pe àwọn akósilẹ̀ èsì àyẹ̀wò ti wọ́n ń gbé síta ni ilé ibùdó àyẹwò peye.
O ni péréte báyìí sì ni àwọn akọsilẹ̀ ti wọ́n n fi síta naa.
Èdè àìyede wà láàrin Equitorial Guinea àti WHO lẹ́yìn ti wọ́n fẹ̀sun kan àṣojú WHO níbẹ̀ pé o ń ṣe àfikún iye àwọn to ni Covid-19.
Fún ìgbà díẹ̀ wọ́n kọ̀ láti jọwọ́ àwọn àkọsilẹ̀ wọn, sùgbọ́n wọ́n tún ti bẹ̀rẹ̀ si ni fi síta padà.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Naijiria:
Ní ìpínlẹ̀ Kano lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà láàrìn kan ó tó ẹgbẹ̀rún ènìyàn tó ń kú ni inú oṣù kẹrin ọdún, sùgbọ́n ìjọba kò ti fi ìdí rẹ múlẹ̀ títí di àsìkò yìí, àwọn ti ó jẹ́ ikú Covid-19 nibẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Akíyèsí: àwọn àwọran tí a lò yìí ni à wá láti ibomíràn pàápàá jùlọ ti France yàtọ̀ si èyí ti fasiti John Hopkins lò, èsì náà kéré díẹ̀ s ti gbogboogbo. àkójọpọ iye ti US ko ni ti PuertoRico, ti Guam tabi Us Virgin Islands ninu.















