Coronavirus lockdown: Bí àrùn Coronavirus ṣe dá gbogbo àgbáyé gúnlẹ̀ sójú kan náà nìyí

Aarun coronavirus ti kọlu eniyan to le ni miliọnu kan ni agbaye báyìí, sugbọn ipa to ni to ni kọja ọdọ awọn to ni i.
Bi awọn ijọba orilẹ-ede kaakiri agbaye ti ṣe idasilẹ awọn ilana tuntun lati koju rẹ.
Eyi lo mu ki a ṣe agbeyẹwo ipa to ti ni l'ara awọn eniyan, ati ayika wọn.
Bi aye ṣe d'ẹnu kọlẹ
Ka ma parọ, orisirisi ọna ni wọn ti fi n koju coronavirus.
Ni Colombia, numba kaadi idanimọ eeyan ni yoo sọ ọjọ ti yoo anfaani lati jade; ni Serbia, wọn ti ya asiko ti o le mu aja rin nigboro sọtọ.
Ni Belarus, aarẹ wọn kọ lati tẹle imọran awọn eleto ilera, to si sọ pe ki awọn eniyan o maa mu ọti vodka ati iwẹ sauna lati daabo bo ara wọn.
Diẹ lara awọn ilana to wọpọ ni ofin ijọba l'ori ijina sira ẹni láwùjọ ni awọn agbegbe kan tabi jakejado orilẹ-ede.
Nigba ti aarun naa kọkọ bu jade ni China ni ipari ọdun 2019, sise ofin konile o gbele dabi aseju.

Sugbọn bi o ṣe n tan kaakiri agbaye, lo n nira lati koju rẹ.
Ọpọ orilẹ-ede lo ti gbe ilana alagbara lati koju rẹ.
Awọn orilẹ-ede ti ko din ni ọgọrun un lo ti kede konile o gbele nigba ti yoo fi di ipari oṣu Kẹta, ọdun 2020, eyi to kan ọpọlọpọ biliọnu eniyan.

O dabi ẹni pe awọn agbegbe kan to ṣẹṣẹ ni akọsilẹ aarun naa laipẹ yii ti n sawokọse awọn akẹgbẹ wọn ní Asia ati Europe.
Awọn ijọba nilẹ Africa naa dabi ẹni ti n jara mọ ọrọ naa.
China ti dẹ ọwọ l'ara awọn ilana rẹ, lẹyin to la asiko ọpọlọpọ iku ati ibujade aarun naa kọja.
Sugbọn igbe aye ko ti i pada bọ sipo.
Ọna si jin paapa fun awa to ku.

Ewu irinna loju ofurufu
Nigba ti aarun naa kọkọ bu jade, ọpọ orilẹ-ede lo fi ofin de baalu lati China, tabi ki wọn o fi awọn to ba rinrinajo de lati orilẹ-ede ti aarun naa pọ si, si ìyà sọtọ.
Lẹyin ti ajọ eleto ilera l'agbaye, WHO kede pe ajakalẹ aarun ni coronavirus lọjọ kọkanla, osu Kẹta, awọn ilana orisirisi tun jẹyọ.
Ààrẹ Trump fi ofin de gbogbo irinajo ti ko ba ṣe koko lati ilẹ Yuroopu si America lọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹta.
Ọjọ kan lẹyin rẹ naa ni ajọ ilẹ Yuroopu naa ṣe bẹ ẹ.
Nigba ti yoo fi di ipari oṣu Kẹta, irinajo si awọn papakọ ọkọ ofurufu to tobi ju ti dinku.
Ni ọsẹ to gbẹyin oṣu Kẹta, irinajo ọkọ ofurufu dinku si ìdá mẹtalelọgọ́ta nitori pe awọn orilẹ-ede kan tun fi ofin de irinajo oju ofurufu.

Lílọ bibọ
Kiise lílọ bibọ lati lati ilu kan si òmíràn nikan ni o kan, irinajo laarin awọn ilu nla kaakiri agbaye ti dawọ duro.
Ori ayelujara lo ku ti awọn eniyan ti n gburo ara wọn bayii.
Bakan naa ni akọsilẹ fihan pe saaju ki ijọba to kede konile o gbele ni awọn eniyan ti din irinajo wọn ku.
Koda awọn eniyan ni awọn ilu bi Stockholm ni Sweden, Honk Kong, ati Singapore ti ijọba ko ti ṣe ofin ijina sira ẹni láwùjọ, awọn eniyan n din irinajo wọn ku.
Ṣugbọn olu ilu South Korea, Seoul, ko ti fofin d'ẹnu kọlẹ bi awọn ilu nilẹ Yuroopu.
Bo tilẹj ẹ pe ọpọlọpọ eniyan lo ni coronavirus nibẹ - ilana títọ pinpin awọn to ni nkan ṣe pẹlu ẹni to ba ni aarun naa ni wọn n lo.

Bakan naa ni nkan ṣe ri fun awọn to n rin lojupopo.
Lílọ bibọ eniyan lojupopo ti dinku pupọ ko to o di pe ijoba kede konile o gbele ni awọn ìlú nla kaakiri agbaye.
Aworan ìsàlẹ̀ yii se afiwe asiko ti yoo gba lati lọ lati ibi kan si omiran laarin ilu si igba ti ko si lílọ bibọ.
Igbele wọn ọgọ́ta tumọ si pe irinajo yoo gba ìdá ọgọ́ta ju ti oju ọna ba da paroparo.
Fun àpẹẹrẹ, irinajo to yẹ ko gba ọgbọn isẹju yoo di isẹju marunlelogoji.
Opin ọsẹ ni awọn ibi ti o ti wa silẹ julọ.

Awọn àpẹẹrẹ pe nkan ti n bọ sipo ti n farahan ni China.
Igbokegbodo ọkọ ti pada si ilaji bo se ri ni Beijing ati Shanghai lọdun 2019.
Ni Wuhan ti aarun coronavirus ti bẹrẹ, igbokegbodo ko ti i pada bọ sipo rara ti a ba fi we bọ ṣe ri lọdun to kọja.

Ayika
Ọkan ninu anfaani ti konile o gbele mu wa ni pe o dabi ẹni pe ijamba si ayika ti dinku ni awọn ibi kan ni agbaye, paapa si ayipada oju ọjọ.



Ni UK, ati awọn ibomiran, akọsilẹ ẹ̀rọ satalaiti ko fihan boya adinku to ba lílọ bibọ lo mu adinku ba titu jade eefin, bo tilẹ jẹ pe awọn kan sọ oun ni.
Bi a ṣe n sisẹ bayii
Bi awọn orilẹ-ede ṣe d'ẹnu kọlẹ, ọpọ oṣiṣẹ ti gbiyanju lati tẹsiwaju pẹlu isẹ wọn lati ile.
Eyi tumọ si pe ìpè oni fidio ati atẹranṣẹ ori ayelujara ti di irin'ṣẹ pataki.
Iye atẹranṣẹ ti awọn eniyan ti fi ránṣẹ lori ayelujara ni New York, Paris, London ati Berlin ti lọ soke si ni ìlọ́po mẹta laarin ọsẹ diẹ.

Sugbọn kii ṣe gbogbo eniyan ni ilana iṣẹ tuntun ti mọ l'ara.
O tun wa a ni ṣe pẹlu ibi ti o ba wa - aaye si le wa lati ṣatunṣe.














