Wo àwọn ọba alayé tí wọ́n gba adé lórí wọn ní Nàíjíríà

Aworan ade oba kan

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Yoruba bọ wọn ni bi ọba kan ko ba ku, omiran ko le jẹ.

Amọ o jọ wi pe owe aye atijọ, ki awọn oyinbo amunisi to gbe aṣa eto ijọba ode oni de orilẹ ede Naijiria ni owe yii.

Laye atijọ, oye ọba jijẹ ajẹrọrun ni, iku lo maa n gba aṣọ lara eegun ni ọrọ naa ṣugbọn nnkan ti y pada lode oni.

Ọpọ ori ade ọrun ilẹkẹ ni awọn ijọba ti fi aṣẹ yọ nipo, ti wọn si ti fi ẹlomiran rọpo wọn loju aye wọn.

Lara awọn iroyin to ṣi n ja rain-rain lasiko yii ni Eleruwa ti Eruwa, Ọba Adebayo Adegbola ti ile ẹjọ to ga julọ nilẹ wa yọ nipo lọdun 2019 amọ ti ijọba ipinlẹ Oyo yan sipo pada lẹyin ọdun mẹfa to ti kuro lori itẹ.

Bakan naa, iroyin gbalẹ nipa Malamu Muhammadu Sanusi ti ijọba Kano da pada sipo gẹgẹ bii Emir tiluu Kano laipẹ yii.

Ni ọdun 2020 ni wọn kọkọ rọ ọba naa

Titi di asiko ti a pari akọjọpọ yii si ni ọrọ ọhun ṣi n fa oriṣiriṣi awuyewuye lọtun ati losi.

BBC Yoruba ti wa mu diẹ lara awọn ọba alaye ti ijọba tabi igbimọ to n ri sọrọ ọba lawọn ilu kọọkan ni Naijiria ti rọ nipo.

Ogboru - Ọọni Ile-Ifẹ

Ọọni Ooni Ogboru wa lara awọn Ọọni to jẹ ni saa to ti pẹ. Awọn oloye aafin la gbọ pe wọn rọ ọba naa loye lẹyin to ti lo aadọrin ọdun lori ipo.

Ẹtanjẹ ni wọn fi yọ Ogboru kuro nipo lọdun naa lọhun gẹgẹ bi itan ṣe ṣalaye rẹ.

Lẹyin ti wọn tan Ọọni kuro ninu aafin la gbọ pe wọn tilkẹkun mọ-ọn, to si lọ fi ibinu da ilu miiran ti wọn pe ni Ifẹ-Ọdan silẹ, nibi to ti n jẹ ọba rẹ lọ.

Bo ṣe kuro, Ọọni ti ko din ni mẹfa la gbọ pe wọn ku sori itẹ lẹyin ti wọn le Ogboru danu. Igba to si ya lo sọ pe oun ko jẹ ọba mọ, ko to fi ọmọ rẹ, Giẹsi rọpo. Lara awọn iran Giẹsi ni Ọjaja keji to wa lori ipo ọhun bayii.

Ovoranwen Nogbaisi, Ọba Benin

Ijọba ilẹ Gẹẹsi lo jawe lọ gbele ẹ fun Ọba Ovoranwen tilkuu Benin lọdun 1897 labẹ iṣakoso Vice-Consul Phillips Roberts nigba naa.

Lara ẹsun ti wọn fi kan Ọba Ovoranwen nigba naa ni wi pe o n da ṣakoso lori gbogbo ọja, eyi ijọba ilẹ Gẹẹsi ko nifẹ si. Awọn Consul gbiyanju lati yabo aafin rẹ ki wọn si gbe e, ṣugbọn awọn ẹṣọ aabo rẹ ko gba wọn laye.

Pẹlu ibinu ni awọn ologun ilẹ Gẹẹsi fi pa gbogbo awọn ẹṣọ aabo ọhun danu, ti wọn si pada gbe Ọba Ovoranwen.

Lẹyin ti wọn rọ ọ loye, wọn tun dajọ iku fun un nipa yiyẹgi fun un, ṣugbọn to ri aaye lati na papa bora lọ si ilu kekere kan ti wọn pe ni Essien niluu Calabar. Ibẹ si lo pada ku si lọdun 1914.

Erejuwa akọkọ - Olu tiluu Warri

Ọba alaye ilẹ Itsekiri ni Erejuwa akọkọ, to si tun kọkọ jẹ laarin ọdun 1951 si 1964. Ẹgbẹ oṣelu NCNC ti ẹkun Ila Oorun lo rọ ọ loye nigba akọkọ.

Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o n ṣatilẹyin fun ẹgbẹ Action Group to jẹ ti Oloogbe Awolọwọ. Ilu kan ti wọn pe ni Ogbesse lo lọ farapamọ si.

Ọdun 1966 ni ijọba ologun labẹ iṣakoso David Ejoor daa pada sipo naa, to jẹ titi di 1989 ko to jade laye.

Alaafin Ọyọ – Ọba Adediran Adeyẹmi II

Ọba Adediran Adeyẹmi keji ni baba to bi Alaafin to ṣẹṣẹ gbesẹ yii, iyẹn Ọba Lamidi Adeyẹmi kẹta.

Ẹni ọdun mẹrinlelọgọrin ni Ọba Adeyẹmi keji wa nigba ti wọn rọ ọ loye nitori ija oṣelu to wa laarin oun ati Ọbafẹmi Awolọwọ nigba naa.

Ẹgbẹ oṣelu NCNC ti Oloye Nnamdi Azikwe n ṣagbatẹru rẹ ni wọn sọ pe Ọba Adeyẹmi keji n tẹle nigba naa lati fi tako Awolọwọ.

Lẹyin ti wọn rọ ọ loye ni wọn yan Gbadegẹṣin Ladigbolu gẹgẹ bii Alaafia tuntun lọdun 1970.

Awujalẹ Ijẹbu – Ọba Adenuga Fọlagbade

Ẹni ọdun mẹtalelọgbọn ni Awujalẹ Adenuga Fọlagbade gun ori itẹ awọn baba-nla rẹ ninu oṣu kọkanla, ọdun 1925.

Ọdun 1929 ni wọn gba ade lori rẹ, to si salọ siluu Ilọrin lori ẹsun iwa jibiti to nii ṣe pẹlu iṣẹ aṣọgbo.

Ọlọwọ tiluu Ọwọ – Ọba Ọlatẹru Olagbegi keji

Ọba Ọlatẹru Ọlagbegi keji jẹ olowo ati ọlọrọ rẹpẹtẹ, to si tun jẹ alẹnulọrọ pataki niluu Ọwọ, ipinlẹ Onso nigba naa. Ọdun 1941 lo gun ori itẹ, to si jẹ titi ọdun 1966.

Wahala nla bẹrẹ fun un nigba to yan Oloye S.L. Akintọla dipo ọrẹ rẹ, Ọbafẹmi Awolọwọ lasiko oṣelu.

Aafin Ọwọ ni wọn ti da ẹgbẹ oṣelu Action Group silẹ lọdun naa lọwọ. Ija nla ni eyi jẹ lasiko naa, to si fa iku ọpọlọpọ awọn araalu, to tun di pe ọpọ dukia lo ṣofo.

Pẹlu ibi lawọn ara Ọwọ fi lee kuro laafin fun ọdun mẹtadinlọgbọn, ti wọn si yan Ọba Ogunoye dipo rẹ.

Iku Ọba Ogunoye lo jẹ ki wọn pe Ọba Ọlatẹru pada lọdun 1993. Ọdun marun lo pada lo ko to jade laye lọdun 1998.

Emir tiluu Kano – Sir Mohammodu Sanusi akọkọ

Sir Mohammodu Sanusi akọkọ gbajumọ daadaalẹkun Ariwa Naijiria. Aarin ọdun 1954 si 1963 lo si fi jẹ Emir tiluu Kano.

Alaaji Ahmadu Bello to jẹ ibatan rẹ lo gba ipo lọwọ rẹ, lẹyin iwa ṣiṣe owo kumọkumọ ti wọn fi kan an.

Ilu Azare ni wọn le danu si lọdun1964, ṣugbọn to pada ku siluu Wudil.

Ọba Ibikunle Akintoye ati Ọba Koṣokọ - Awọn Ọba Eko

Igba meji ọtọọtọ ni Ọba Ibikunle Akintoye fi jẹ Ọba Eko. Igba akọkọ ni ọdun 1841 si 1845. Wọn lee danu kuro lọ si Badagry lori ẹsun wi pe o gbogun ti iwa okoowo ẹru.

Lẹyin rẹ ni wọn yan Ọba Kosọkọ ti wọn si tun le oun danu, lori ẹsun wi pe o kọ lati bọwọ fun awọn oyinbo Gẹẹsi akonilẹru.

Yiyọ ti wọn yọ ọ lo mu ki wọn pe Ibikunle Akintoye pada lọdun 1851.

Inu oṣu kẹsan, ọdun 1853 ni wọn tun lee danu lẹẹkeji.

Ọba Abibu Lagunju - Timi tiluu Ẹdẹ

Timi Abibu Languju ni musulumi ti yoo kọkọ jẹ ọba nilẹ Yoruba, itan naa ṣi fi ẹsẹ mulẹ titi di oni. Ọdun 1855 si 1892 lo fi jẹ ko to di pe ijọba Gẹẹsi nigba naa lee danu lọ siluu Ibadan lati lọ maa gbe.

Ẹnikan ti wọn pe ni Sunmọnu Apampa, iyẹn Aṣipa ilu Ibadan nigba naa lo gba a tọwọ-tẹsẹ ko to di pe o jade laye lọdun 1900.

Sultan tiluu Ṣokoto – Ibrahim Dasuki

Ijọba ologun labẹ iṣakoso Ọgagun Sanni Abacha lo rọ Sultan Dasuki loye lọdun 1996. Kaakiri orileede yii ni ọrọ naa ja rain-rain de, to si di akọle ijiroro fun ọlọpọpọ oṣu.

Lara awọn awuyewuye to jẹyọ nigba naa ni pe Ibrahim Dasuki ṣe awọn dukia ibatan Abacha kan baṣubaṣu.

Awuyewuye miran tun ni pe ọna ti Dasuki n gbe iṣakoso rẹ gba, to si mu ki awọn eeyan pe fun iyansipo Sultan Maccido, ẹni to pada rọpo rẹ.

Awọn ọba miran ti wọn tun rọ loye ni;

Emir ilu Kano, Aliyu Ibn Abdullahi Maje Karofi

Akarigbo tilẹ Rẹmọ – Oyebajo

Alase tilẹ Rẹmọ, Oloye Awolesi

Osemawe tiluu Ondo – Ọba Adekolurejo Jimosun keji (Otutubiosun)

Osemawe tiluu Ondo – Ọba Adenuga Fidipọtẹ keji

Emir tiluu Gwandu – Mustapha Jokolo

Emir tiluu Ningi – Dan Yaya

Ọlọfa tiluu Ọffa – Ọba Wuraọla Isioye

Emir tiluu Bauchi – Umar Mohammed

Deji tiluu Akurẹ – Ọba Oluwadamilare Adeṣina Oṣupa kẹta

Ọba Awujalẹ Sikiru Adetọna

Onojie tiluu Uromi Kingdom – Anslem Aidenojie

Olupoti tiluu Ipoti Ekiti – Ọba Ọladele Ayẹni ati

Eleruwa tiluu Eruwa - Ọba Samuel Adebayọ Adegbọla