Àgbà òṣèlú, Dókítà Doyin Okupe jáde láyé

Doyin Okupe

Oríṣun àwòrán, Doyin Okupe

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Agba oselu kan ni orilẹede Naijiria, Dokita Doyin Okupe ti dagbere fun aye pe o digbose.

Ọjọ Ẹti oni tii se ọjọ Keje osu Kẹta ọdun 2025 ni Okupe jade laye lẹni ọdun mọkanlelaadọta.

Nigba to n fidi isẹlẹ iku okupe mulẹ fun BBC Yoruba, amugbalẹgbẹ feto iroyin fun Doyin Okupe lasiko to jẹ agbẹnusọ fun aarẹ Goodluck Jonathan, Ọmọwe Sanya Awosan ni lootọ ni isẹlẹ naa waye.

"Naijiria ni yoo mọ riri Doyin Okupe nitori ọpọ ipa manigbagbe to ti ko si idagbasoke Naijiria"

Awosan ni iku Okupe jẹ ohun to dun oun lọkan, ti ko si sẹni to reti iku agba oselu naa lasiko yii.

O wa se apejuwe ọga rẹ naa gẹgẹ bii ọlọpọlọ pipe, to si maa n se agbekalẹ ero rẹ lọna to mu ọgbọn dani.

"Ilu Abuja la ti pade, ti a si dijọ sisẹ papọ labẹ ijọba Goodluck Jonathan.

Ohun manigbagbe nipa Okupe ni pe ori rẹ pupọ ninu ohunkohun, ko si le se agbekalẹ ọrọ kan, ki gbogbo eeyan ma patẹwọ fun nitori ọpọlọ pipe ti yoo fi gbe kalẹ.

Gbogbo Naijiria ni yoo mọ riri akọni oloselu to papoda naa nitori ọpọ ipa manigbagbe to ti ko si idagbasoke Naijiria."

Koko pàtàkì nípa ìgbe aye Doyin Okupe

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Apetan orukọ oloogbe naa ni Adedoyin Ajibike Okupe, ti ọpọ eeyan mọ si Doyin Okupe.

Ọjọ kejilelogun osu kẹta ọdun 1952 lo dele aye, ọmọbibi ilu Iperu nipinlẹ Ogun si lo jẹ.

Baba rẹ, Oloye Matthew Adekoya Okupe jẹ osisẹ banki Agbonmagbe, to si lọ sile ẹkọ alakọbẹrẹ St. Jude ni Ebute Metta nilu Eko.

Bakan naa lo tẹsiwaju lẹnu ẹkọ rẹ nile ẹkọ girama Igbobi College ni Yaba, ko to wa morile fasiti Ibadan lati kọ ẹkọ nipa imọ isegun.

Asiko to n sisẹ bii dokita onisegun oyinbo lo dara pọ pẹlu awọn eeyan miran lati da ile iwosan Royal Cross Medical Centre silẹ, ko to bọ si agbo oselu

Doyin Okupe ni alukoro apapọ fun ẹgbẹ oselu National Republican Convention (NRC).

Ijọba ologun Sani Abacha si ti Okupe mọle lasiko kan, amọ o pada di oludije fun ipo gomina fẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Ogun.

Bakan naa ni Okupe jẹ amugbalẹgbẹ feto iroyin ati ipolongo fun Aarẹ President Olusegun Obasanjo ati akọwe feto iroyin naa fun aarẹ President Goodluck Jonathan.

Lẹyin eyi ni Okupe tun jẹ oludari agba feto ipolongo ibo fun oludije aarẹ fẹgbẹ oselu Labour lọdun 2023, Peter Obi.

Amọ losu kejila ọdun 2022, saaju ibo aarẹ naa ni Okupe ti kọwe fipo silẹ gẹgẹ bi oludari agba feto ipolongo ibo naa lẹyin ti wọn fi ẹsun kiko owo kan.

O wa papa kuro ninu ẹgbẹ oselu Labour lẹyin ibo ọdun 2023.

Ọjọ Ẹti, ọjọ Keje osu kẹta ọdun 2025 si ni Dokita Adedoyin Ajibike Okupe jade laye.