Taa ló gbé Abdulrahman, afurasí tí wọ́n bá òkú Yetunde nílé rẹ̀ n'Ilorin kúrò l'ẹ́wọ̀n tó wà? Ohun tí a mọ̀ rèé

Aworan afurasi Abdurahman Muhamadu Bello ati Yetunde Lawal
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Lati irọlẹ ọjọ Ẹti, ọjọ Kẹrinla, oṣu Kẹta ni a ti n gbọ finfin pe wọn ti gbe Abdurahman Muhamadu Bello, afurasi ti wọn fẹsun kan pe o lọwọ ninu iku Yetunde Lawal Hafsah.

Iroyin ti a gbọ ni pe awọn ọlọpaa ti gbe kuro lọgba ẹwọn Okekura to wa ni ilu Ilọrin ipinlẹ Kwara, ibi ti ile ẹjọ ni ko wa na ti igbẹjọ rẹ yoo fi maa tẹsiwaju.

Ohun ti a ri gbọ ni pe ọjọbọ ọsẹ yii ni wọn gbe Abdurahman Muhammadu Bello kuro lọgba ẹwọn naa, ti a ko si ti le sọ ibi ti wọn gbe lọ pato.

Bakn naa ni a o ti mọ idi pataki ti wọn fi gbe kuro lọgba ẹwọn Okekura ilu Ilọrin.

Nigba BBC News Yoruba kan si agbẹnusọ ọgba ẹwọn Okekura ilu Ilọrin, Ọgbẹni Phillip sọ pe sadede ni awọn ọlọpaa wa gbe kuro lọdọ awọn ti oun ko si le sọ ibi ti wọn gbe lọ, ṣugbọn ko si Abdurahman Muhamadu Bello lọdọ awọn mọ.

Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ejirẹ Toun Adeyẹmi naa fidi rẹ mulẹ fun BBC News Yoruba pe ẹjọ naa ti kuro lọdọ awọn, o ti wa ni ikawọ ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran fun ijọba apapọ iyẹn FCID.

Lọjọ keje osu yIi ni Abdulrahmon Bello ati awọn mẹrin miI farahan ni ile ẹjọ magistrate ilu Ilọrin lori ẹsun isekupa Hafsah Yetunde Lawal.

Lasiko igbẹjọ naa ni Abdurahman Muhammadu Bello sọ fun adajọ S B Muhammed to n gbọ ẹjọ naa pe ki wọn tu awọn mẹrin to ku ti wọn mu sílẹ nitori pe oun nikan loun lọwọ ninu iku Hasfot Lawal.

Onidajọ Muhammed sọ pe oun ko lagbara lati tu awọn to ku silẹ, lẹyin eyi ni adajọ sọ pe wọn ti gbe ẹjọ naa lọ ile ẹjọ giga ipinlẹ Kwara nibi ti igbẹjọ naa yoo ti bẹrẹ ni pẹrẹu logunjọ oṣu yii.

Ọsẹ to n bọ ni ireti wa pe Abdulrahman atawọn afurasi yooku yoo tun foju bai le ẹjọ lori ẹsun naa amọ ti a o le sọ bi ọrọ naa yoo ṣe jẹ bayii.

Ti ẹ o ba gbagbe, oṣu Keji ọdun yii ni ọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Kwara tẹ Abdulrahman Bello fẹsun pe o sekupa Hafsah Yetunde Lawal to si tun kun-un wẹlẹwẹlẹ sinu ile rẹ ni Ilọrin.

Awọn ara ilu Ilọrin, ipinlẹ Kwara yoo maa reti ohun ti yoo sẹlẹ ni ile ẹjọ lọsẹ to n bọ.

Oju ree, iran ree!

Wo bí ìgbẹ́jọ́ Alfa Abdurahman, afurasí tí wọ́n bá òkú Yetunde nílé rẹ̀ n'Ilorin, ṣe lọ lónìí

Lonii Ọjọbọ ọjọ kẹfa oṣu Kẹta ni igbẹjọ aafa Abdurahman Muhamadu Bello, ti wọn fẹsun kan pe o pa Hafsat Yetunde Lawal waye, pẹlu awọn mẹrin mi ti wọn jọ fẹsun kan wọn.

Igbẹjọ naa waye ni ile ẹjọ Majisireeti to wa ni idojukọ ile ẹjọ giga ipinlẹ Kwara niluu Ilorin .

Ẹsẹ o gbero lọgba ile ẹjọ naa lonii, pẹlu bawọn araalu se yabo ibẹ lati wa wo ohun ti yoo sẹlẹ.

Asise ni bi mo se kun oku Yetunde, ẹ da awọn afurasi yoku silẹ, wọn ko mọwọ mẹsẹ nipa iku oloogbe - Abdulrahman

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lati bi ago meje owurọ lawọn ọlọpaa ti duro wamu wamu ti wọn si di ọna to wọ ile ẹjọ naa pa.

Onidajọ S. B. Muhammed to jẹ adajọ ile ẹjọ naa salaye fun awọn afunrasi naa nipa ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan wọn.

Lẹyin eyi ni agbẹjọro ijọba lati ile iṣẹ eto idadọ ipinlẹ Kwara, Isah Sakare sọ pe ile iṣẹ eto idajọ ipinlẹ naa ti tẹwọ gba ẹjọ ọhun, lati gbe e lọ si ile ẹjọ giga ipinlẹ Kwara to lagbara lati gbọ ẹjọ naa.

Agbẹjọro awọn obi ọmọ to di oloogbe, A.S. Hussein ni oun fara mọ igbesẹ naa .

Lẹyin eyi ni afurasi Abdurahman Muhamadu Bello na ọwọ soke lati sọrọ, ti adajọ si fun un laye.

Abdurahman ni oun nikan ṣoṣo ni ọrọ iku Hafsat Yetunde Lawal kan.

O fikun ọrọ rẹ pe, bi Ọlọrun ṣe kọ ọ pe ọrọ iku rẹ yóò ri, lori lo ṣe ri, nitori pe lọjọ naa oun lọ ba a ra ounjẹ ti yóò jẹ loun deede ba a ninu ile to ti ku.

Ṣugbọn o ni aṣiṣe ti oun se ni bi ohun se kun oku rẹ wẹlẹwẹlẹ.

Abdurahman rọ ile ẹjọ lati da awọn to ku silẹ nitori wọn o mọ ọwọ, wọn o mo ẹsẹ nipa ọrọ naa.

Adajọ sọ pe oun ko lagbara lati tu awọn afurasi yoku naa silẹ, nitori ẹjọ ti n lọ si ile ẹjọ giga ipinlẹ Kwara

Nigba ti adajọ bi i leere ibi ti oku Yetunde wa, o ni oun ti kun un wẹlẹwẹlẹ, oun si mu awọn ọlọpaa lọ ibi ti oun da eyi toku ara rẹ si.

O sọ fun ile ẹjọ pe ọwọ nikan ṣoṣo lo ku ti wọn ba ninu ile oun.

Adajọ sọ pe oun ko lagbara lati tu awọn afurasi yoku naa silẹ, nitori ẹjọ ti n lọ si ile ẹjọ giga ipinlẹ Kwara.

Agbẹjọro fawọn afurasi to ku ti wọn mu, naa parọwa si adajọ lati tu awọn to ku silẹ niwọn igbati Abdul-rahmon ti jẹwọ wi pe lootọ oun nikan ṣoṣo loun mọ nipa iku Yetunde Lawal.

Adajọ ile ẹjọ S B Muhammed ti wa sun igbẹjọ siwaju di ogunjọ oṣu yii lati fagile ẹjọ naa ni ile ẹjọ Majisireeti.

O ni igbesẹ naa ni yoo mu ki ẹjọ naa le bẹrẹ pada ni ile ẹjọ giga ipinlẹ Kwara logunjọ oṣu kẹta ọdun yii.

Lasiko ti Baba ọmọ naa ba akọroyin ile iṣẹ BBC Yorùbá sọrọ, Ọgbẹni Lawal ni ohun ti oun n fẹ lori ọrọ naa ni idajọ ododo.