Ìgbésẹ̀ láti káwọn ọmọ Nàìjíríà tí kò ní ìwé ìgbélùú l'Amẹrika padà wálé, ti bẹ̀rẹ̀ tipẹ́ - Mínísítà

Minisita fọrọ ilẹ okeere ni Naijiria, Yusuf Tuggar, ti sọ pe eto lati ko awọn ọmọ Naijiria ti ko ni iwe igbeluu l'Amẹrika pada wale ti bẹrẹ ti pe.
Minisita sọrọ yii ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe laipẹ yii pẹlu BBC.
Ọgbẹni Tuggar sọ pe eto naa ti bẹrẹ ṣaaju ki Aarẹ Donald Trump to wọle ibo aarẹ Amẹrika fun saa keji.
Minisita ni nnkan ti ijọba Aarẹ Tinubu ti n foju sọna si ni eto ọhun.
''A ki awọn ọmọ Naijiria ti ko ni iwe igbeluu l'Amẹrika kaabọ pada sile.
Ijọba apapọ labẹ alaṣẹ Aarẹ Tinubu ti ṣeto silẹ fawọn ọmọ Naijiria yii to n bọ wale lati orilẹee Amẹrika.
Naijiria jẹ orilẹede ti oniruuru anfaani pọ si, nitori naa, a ko ri pipadabọ wale awọn ọmọ Naijiria kan gẹgẹ bii iṣoro.
Ohun to jẹ wa logun ni pe ki wọn si jẹ ọmọluabi, a o fẹ ki wọn fi ma mu gaari si wọn lọwọ tabi ki wọn maa fiya jẹ wọn,'' minisita fọrọ ilẹ okeere lo sọ bẹẹ.
Iṣoro ti ijọba ni pẹlu Binance ni pe awọn eeyan n lo ileeṣẹ naa lati ji owo ko lọ silẹ okeere - Tuggar
Minisita tun sọrọ lori igbẹjọ Ọgbẹni Tigran Gambaryan, ati akẹgbẹ rẹ Nadeem Anjarwalla ti ileeṣẹ iṣuna Binance Holdings ti ajọ EFCC to n gbogun tiwa ibajẹ fẹsun kan pe wọn lọwọ ninu iwa gbigba ọna ẹburu ko owo to to $35.4m kuro lorilẹede Naijiria.
Ọgbẹni Tuggar sọ pe iṣoro kan ti ijọba apapọ ni pẹlu ileeṣẹ Binance ni pe iru awọn ileeṣẹ yii maa n fawọn eeyan lanfaani lati kowo lọ si ilẹ okeere lọna aitọ.
O ni awọn nnkan yii si n ṣakoba nla fun eto ọrọ aje Naijiria eyi ti ijọba n ṣiṣẹ le lori pe ko le gbeeru si.
Bakan naa lo sọ pe eyi tun maa n ṣakoba fun bi owo naira ṣe gbẹwọn si pẹlu dọla.
Minisita sọ pe ijọba Naijiria ko ni iṣoro pẹlu ileeṣẹ ilẹ okeere kankan, niwọn igba ti wọn ko ba ti ni ṣe ohun to lodi sofin ni Naijiria.
Minisita Tuggar ko ṣai mẹnu ba ọrọ lori iṣẹlẹ awọn eeyan kan ti wọn maa n dunkoko mawọn miran wi pe awọn yoo fi fọto tabi fidio ihoho wọn sita lori ayelujara ayafi ti wọn ba fawọn lowo.
Ọgbẹni Tuggar ni ile igbimọ aṣofin agba ti ṣe agbekalẹ ofin to sọ ijiya to tọ fun ẹnikẹni to ba n hu iru iwa bayii.
O ni awọn agbofinro n lo awọn ofin yii daadaa, ati pe awọn agbofinro yii n ni idanilẹkọọ loore koore lori bi wọn ti le maa lo ofin yii.















