Zelensky ṣèlérí láti ṣèpàdé àlááfíà pẹ̀lú Trump lẹ́yìn tí wọn pariwo mọ́ ara wọn

Oríṣun àwòrán, EPA
Aarẹ Volodymyr Zelensky orilẹede Ukraine ti sọ pe oun ṣetan lati ṣe ipade lori ọna ti alaafia yoo fi jọba pẹlu Aarẹ Donald Trump Amẹrika lẹyin ọjọ diẹ ariyanjiyan waye laarin wọn.
Zelensky loun kabamọọ ihuwasi oun lasiko itakurọsọ to waye laarin awọn olori orilẹede mejeeji nileeṣẹ ijọba Amẹrika.
Lẹyin naa ni ijọba Amẹrika kede pe oun yoo da iranwọ ologun ti Amẹrika n ṣe fun Ukriane duro lori ogun to n lọ laarin Russia ati orilẹede naa.
Zelensky ni asiko ti to lati ṣe ohun to yẹ lẹyin ti Trump sọ pe aarẹ Ukraine ko ṣetan lati ṣepade alaafia.
Aarẹ Ukraine tun sọ nipa awọn ọna ti ogun pẹlu Russia fi le pari.
''A ṣetan lati ṣiṣẹ ki ogun le pari ni kiakia, igbesẹ akọkọ si ni idasilẹ awọn to wa lẹwọn, fifofin de awọn ado oloro ti wọn n ju soke ati awọn nnkan ijagun mii.
Ukraine ṣetan lati gbe awọn igbesẹ yii ti Russia naa ba ti sẹtan lati ṣe bẹẹ,'' Zelensky lo sọ bẹẹ.
Zelensky setan lati buwọlu adehun ti yoo fun Amẹrika lanfaani si nnkan alumọọmi Ukraine
Aarẹ Ukraine sọ loju opo ayelujara wi pe ipade toun ṣe pẹle Trump lọjọ Ẹti to kọja ko lọ boun ṣe fẹ ki o lọ.
O ni oun kabamọọ wi pe ipade naa pari bi o ṣe pari lọjọ naa, amọ, oun ṣetan lati ṣe atunṣe bayii.
Zelensky tun fidi rẹ mulẹ oun ṣetan lati buwọlu adehun lori nnkan alumọni pẹlu Amẹrika, eleyii to kọ lati ṣe lasiko ipade to sẹ pẹlu Trump niluu Washington.
Lanaa ọjọ Iṣẹgun ni iroyin jade wi pe Amẹrika yoo dawọ iranwọ ọmogun to n ṣe fun Ukraine duro lẹyin ariyanjiyan to waye laarin Trump ati Zelensky.
Zelensky ko ṣai lu Amẹrika lọgọ ẹnu fun iranwọ ti o ti ṣe fun Ukraine lati igba ti ogun ti bẹrẹ pẹlu Russia.
Ti ẹ o ba gbagbe, igbakeji aarẹ Amẹrika, JD Vance, fẹsun kan Zelensky wi pe alaimoore eeyan ni tori ko mọ riri iranwọ ti Amẹrika ti sẹ fun Ukraine.
Zelensky naa sọ ti ẹnu rẹ lasiko ipade naa, ṣugbọn o pada ṣalaye lori ileeṣẹ tẹlifisan Fox News lẹyin ipade naa oun moore ti Amẹrika ti ṣe Ukraine.
Lara nnkan ti ipade Zelensky ati Trump da lori ni bibuwọlu adehun awọn olori orilẹede mejeeji lori ọna ti Amẹrika yoo fi lanfaani si nnkan alumọni Ukraine.
Lẹyin ti ipade naa fori ṣanpọn ni Trump sọ pe Zelensky n fi ogun agbaye ẹlẹẹkẹta ṣere.
Trump tun sọ fun Zelensky wi pe ki o pada wa ti o ba ṣetan lati jẹ ki alaafia jọba.
Ọpọ awọn olori orilẹede to ti goke agba bii Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Keir Starmer, ati Emmanuel Macron orilẹede France lo ti gboṣuba fun Zelensky lori akitiyan lati jẹ ki ogun o mi.















