Iléepo Dangote àti NNPC bẹ̀rẹ̀ orogún òwò lórí àdínkú owó líta epo, wo àwọn tí orí ń ta

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ifọpo rọbi Naijiria, NNPCL ti sọ lita epo bẹntiroolu di N860 lawọn ile epo wọn nipinlẹ Eko.
Igbesẹ naa lo waye lẹyin ọjọ diẹ ti ileeṣẹ ifọporọbi Dangote kede adinku lori iye to n ta epo fawọn alagbata ni ibudo igbepo.
Ti ẹ o ba gbagbe, Dangote kede pe lita epo bẹntiroolu kan to n ta tẹlẹ ni N890 ti di N825 eyi to jẹ kawọn ile epo to n ra epo lati ile ifọpo rẹ bii MRS, AP ati Heydey maa ta lita epo bẹntiroolu kan ni N860 si N865 papaa julọ nipinlẹ Eko.
Lẹyin eleyii ni NNPCL naa kede adinku iye tawọn naa n ta epo fawọn alagbata lati N920 si N860.
Eyi lo jẹ kawọn ile epo NNPCL nipinlẹ Eko bẹrẹ si ni maa ta lita bẹntiroolu kan ni N860 bayii.
Lopin ọsẹ to kọja ni ileeṣẹ ifọporọbi Dangote kede wi pe oun ṣetan lati padanu N16bn eyi toun yoo san fawọn alagbata to n ra epo lọdọ oun tori o ṣee ṣe ki wọn ma tii ta epo ti wọn ti ra tẹlẹ tan ki ileeṣẹ naa to kede adinku iye ti wọn yoo maa gbe epo bayii.
Ileeṣẹ Dangote ni oun ṣeleyii ki wọn le maa ta epo fun araalu ni ẹdinwo ni.
Dangote ni awọn gbe igbesẹ yii kawọn ọmọ Naijiria le jẹ anfaani adinku ti ileeṣẹ naa kede, ati pe igbesẹ naa tun wa ni ibamu pẹlu eto ireti ọtun lati ta ọrọ aje Naijiria ji eyi ti ijọba Aarẹ Bola Tinubu n ṣe.
''NNPCL fẹ foju awọn onibaara mọra loun ṣe sọ epo bẹntiroolu di N860''
Amọ, iyalẹnu lo jẹ fun ọpọ eeyan nigba ti ileepo NNPCL nipinlẹ Eko naa bẹrẹ si ni ta lita epo bẹntiroolu kan ni N860 lana ọjọ Aje, ọjọ kẹta oṣu Kẹta ọdun yii.
Igbesẹ yii ba awọn alagbata epo bẹntirolu lojiji papaa julọ awọn to n ra epo lati ọdọ NNPCL.
Ọpọ awọn alagbata epo lo sọ pe ileeṣẹ NNPCL ko tii sọ fawọn pe adinku ti ba iye tawọn yoo maa ta epo fawọn bayii.
Awọn omwoye lẹka epo rọbi ṣalaye wi pe igbesẹ NNPCL lati maa ta epo bẹntiroolu ni iye tawọn ile epo to n gbe epo lati ileeṣẹ ifọporọbi Dangote jẹ ọna lati foju awọn onibaara mọra.
Ileeṣẹ epo rọbi NNPCL to w ani Port Harcourt ati ti Dangote to wa nipinlẹ nikan si ni awọn ileeṣẹ ifọporobi meji to n ṣiṣẹ lọwọ bayii lorilẹede Naijiria, lẹyin NNPCL sọ pe awọn ko tii ko epo wọle lati ilẹ okeere lọdun yii.
Amọ, ileeṣẹ NNPCL sọ laipẹ yii pe lati ileeṣẹ ifọporọbi Dangote lawọn ti ra epo fawọn ile epo awọn to w ani ipinlẹ Eko.
Iye ta n ra epo lati ọdọ NNPCL ko ti dinku – IPMAN
Ẹwẹ, ẹgbẹ alagbata epo bẹntiroolu, IPMAN ti sọ pe adinku ko tii ba iye tawọn n gbe epo lati ileeṣẹ NNPCL.
Agbẹnusọ fun ẹgbẹ IPMAN, Chinedu Ukadike, ṣalaye wi pe N940 tawọn ti n gbepo lati ọdọ NNPCL tẹlẹ naa si ni awọn n ra a.
Ukadike sọrọ yii lẹyin ti NNPCL kede wi pe awọn ti sọ lita kan epo bẹnrtiroolu di N860 lawọn ile epo to wa nipinlẹ Eko ati N965 niluu Abuja.
Agbẹnusọ NNPCL ko tii sọ nnkankan lori ọrọ naa titi di akoko yii.
Ukadike ni NNPCL ṣaba maa n fi ọrọ lori adinku owo sori ''portal'' rẹ, amọ, o sọ pe ko si ohun to jọ bẹẹ lori ''portal'' titi di asiko yii.
O ni N940 si lo wa lori ''portal'' gẹgẹ bii owo lita kan epo bẹntiroolu.
Igba meji ọtọtọ ni ileeṣẹ ifọporọbi Dangote fi kede adinku owo epo bẹntiroolu ninu oṣu Keji to kọja yii.















