''Mo fi ara mi sílẹ̀ fáwọn ajínigbé nígbà tí wọ́n fẹ́ máa mú ìyàwó mi lọ''

Aworan Olabiyisi Mobolaji Charles

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Olabiyisi Mobolaji Charles to mori bọ lọwọ awọn ajinigbe nipinlẹ Oyo ti sọ pe ẹnu ko le sọ ohun ti oju oun ri lakata awọn ajinigbe tan.

Olabiyisi, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn to n gbe ilu Jobele ṣugbọn to jẹ ọmọbibi ilu Akinmoorin nipinlẹ Oyo, lawọn ẹṣọ Amotekun doola ẹmi rẹ lakata awọn ajinigbe lẹyin wakati mẹẹdogun ti wọn ti jigbe.

Ni nnkan bii ago kan ọganjọ oru ọjọ Ẹti ọsẹ to kọja ni wọn ji Olabiyisi nile rẹ, ti wọn si gbe e lọ sinu igbo.

Amọ, igbakeji ọga agba ẹṣọ Amotekun nipinlẹ Oyo, Ọgbẹni Kazeem Babalola Akinro, ṣalaye pe kete ti awọn gbọ ipa iṣẹlẹ naa lawọn ẹṣọ Amotekun kan lu inu igbo lati doola ọdọkunrin naa.

O ni lati oru ọjọ Ẹti naa mọju lawọn ẹṣọ Amotekun fi wa Olabiyisi ninu igbo.

Ọgbẹni Akinro ṣalaye pe ''ni nnkan bii ago mẹrin abọ irọlẹ ni a gan an ni awọn ajinigbe ọhun ninu igbo, ti wọn si bẹrẹ si ni yinbọn si wa, ti awa naa si da a pada.

A ko le ri ọkankan ninu awọn ajinigbe naa pa tori a ko fẹ ki ọta ibọn ba ẹni ti a fẹ doola ẹmi rẹ.''

''Awọn ajinigbe gun ọgba ile wa wọle wa gbe mi lọ ni Jobele''

Nigba ti o n ṣalaye bi iṣẹlẹ ọhun ṣe ṣẹlẹ, Olabiyisi ṣalaye pe ''ni bii ago kan oru kọja iṣẹju mẹsan an lawọn aja wa bẹrẹ si ni gbo, ti a si ri awọn eeyan kan ti wọn gun ogiri ile wa ni wọle nilu Jobele.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bayii ni wọn bẹrẹ si ni yinbọn lati ja ilẹkun wọle, aburo mi ti lọ sapamọ sori aja, emi naa si ti salọ.

Ṣugbọn mo fi ara mi silẹ fun wọn nigba ti wọn fẹ maa mu iyawo mi lọ.

Wọn sọ fun iyawo mi pe ko pada sinu ile, wọn si fi okun de mi lọwọ ti wọn si mu mi lọ.

Lẹyin bii iṣẹju meji ni mo ri awọn Amotekun ti wọn n wa mi kiri amọ wọn ti fi aṣọ bo mi lẹnu ti n ko si le sọrọ.

Bayii ni wọn ṣe mu mi lọ, ti a si rin fun wakati mẹta ninu igbo, mẹfa lawọn ajinigbe ọhun, ẹya Fulani si ni gbogbo wọn bo tilẹ jẹ pe ọkan lara wọn le sọ ede Oyinbo diẹ diẹ.''

Olabiyisi sọ pe bi awọn ṣe n rin lọ ninu igbo lawọn ẹṣọ Amotekun naa n sun mọ wọn eyi ti wọn si mọ pẹlu.

O ni ara fu wọn pe awọn ẹṣọ eleto abo n tẹle wọn, nigba naa ni wọn sọ fun mi pe ki n pe ẹbi mi.

Olabiyisi ni lẹyin naa ni wọn pe baba oun ti wọn si bẹrẹ sii ja owo itusilẹ walẹ si lati N30m, N20m, de N15, ki wọn to sọ pe N10m lawọn yoo gba jalẹ.

Olabiyisi to n ṣiṣẹ didara sinu ile sọ pe ero wọn ni lati tete gbowo ti wọn ba le ri gba, ki wọn si fi mi silẹ.

Mo ro pe mo maa ku si akata awọn ajinigbe ni - Oyebiyisi

''Baba mi sọ fun wọn pe N400,000 loun ri, eyi to gbọ oyinbo diẹ lara wọn si sọ fun baba mi pe awọn yoo yinbọn pa mi ti ko ba wa owo gidi wa.

Lẹyin naa ni wọn sọ pe ki n dọbalẹ ti wọn si bẹrẹ si ni fi ada lu mi.

A tẹsiwaju irin wa ninu igbo, ṣadeedee ni a ja si oju ọna kan ti a si pade awọn ẹsọ Amotekun lojiji.

Bayii ni wọn ti si mi siwaju ki wọn ba le raye salọ, mo ni lati sọrọ soke wi pe emi ni ẹni ti wọn jigbe kawọn ajinigbe ma ba seesi yinbọn si mi.

Wọn bẹrẹ si ni yinbọn bi wọn ṣe n salọ, o ṣee ṣe ki wọn fara gbọta, bayii ni awọn ẹṣọ Amotekun ṣe doola ni irọlẹ ọjọ naa,'' Olabiyisi ṣalaye.

O ni wọn o foun lounjẹ lati jẹ ni gbogbo igba toun lo lọdọ wọn kawọn Amotekun fi doola oun.

Olabiyisi sọ pe bi ebi ṣe n pa oun ni ongbẹ n gbẹ oun, o ni oun tiẹ ro pe oun maa ku ni si akata awọn ajinigbe.

O fikun ọrọ rẹ pe nigba to di alẹ ni wọn lọ ka agbalumọ ati kaṣu wa ti gbogbo awọn jẹ.

Olabiyisi ni o ṣee ṣe kawọn ẹṣọ Amotekun ri pa ninu awọn ajinigbe naa, amọ, wọn o fẹ ki oun ni ipalara lo jẹ ki wọn rọna salọ.

Ọdọkunrin naa wa rọ ijọba lati ro awọn ẹṣọ Amotekun lagbara si tori iṣẹ takun takun ti wọn niluu Oyo ati agbegbe rẹ.

O ni oun ni ẹni kẹwaa tawọn ajinigbe yoo jigbe niluu Jobele yatọ si awọn ti wọn ti jigbe ni Ilora ati niluu Awe.