Afurasí oníṣòwò lu ìyàwó rẹ̀ pa lórí oúnjẹ ààwẹ̀ Ramadan, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

Aworan ọkọ ati iyawo ti wọn n ja
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Bauchi ti mu oniṣowo kan, Nuru Isah, lori ẹsun pe o fi ẹgba lu iyawo rẹ, Wasila Abdulahi, pa lẹyin ede-ai-yede to waye laarin wọn lori eroja ounjẹ ati eso ti wọn fẹ fi ṣinu aawẹ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Ahmed Wakil, sọ pe lalẹ ọjọ Abamẹta opin ọsẹ to kọja ni iṣẹlẹ yii waye lagbegbe Fadamam Mada ni Bauchi.

Iroyin fidi rẹ mulẹ pe Isah fi ẹgba lu iyawo rẹ keji titi ti o fi ṣubu, lẹyin to ṣubu tan ni wọn gbe e lọ sile iwosan nibi tawọn dokita ti sọ pe o ti ku.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye pe ''iṣẹlẹ yii waye lẹyin ariyanjiyan laarin Alhaji Nuru Isah ẹni aadọta ọdun to jẹ oniṣowo lọja kan ni Bauchi ati iyawo rẹ keji, Wasila Abdulahi, ẹni ọdun mẹrinlelogun lori ọrọ ounjẹ ti wọn fẹ fi ṣinu awẹ.

Iwadii fi han pe afurasi Alhaji Isah lo ẹgba lati lu iyawo rẹ eyi to jẹ ko ṣubu ti ko si le sọrọ mọ.

Lẹyin naa ni wọn gbe Wasila lọ si ile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun ATBU nibi ti wọn ti fidi rẹ mulẹ pe ẹlẹmi ti gba a.''

Ọgbẹni Wakil sọ pe lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa gbọ nipa iṣẹlẹ naa ni awọn ọlọpaa bẹrẹ iwadii ti wọn si fọwọ ofin mu ọkunrin naa.

O ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Bauchi ti bẹrẹ iwadii kikun lori iṣẹlẹ naa.

Agbẹnusọ ọlọpaa fikun ọrọ rẹ pe ẹgba ti wọn ni ọkunrin naa lo lati lu Wasila ti wa lọdọ awọn ọlọpaa gẹgẹ bi ẹri.

Bakan naa ni o tun fidi rẹ mulẹ pe wọn ti gbe oku obinrin naa lọ si mọṣuari nibi ti yoo wa ki wọn to ṣe ayẹwo oku naa lati mọ ohun to ṣokunfa iku rẹ gan an.

Wakil sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo sa gbogbo ipa rẹ lati ri wi pe idajọ ododo waye lori iṣẹlẹ naa.

Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Bauchi, CP Auwal Muhamad, ti fi dawọn eeyan ipinlẹ naa loju pe idajọ ododo yoo waye lori ọrọ ọhun.

CP Muhamad ni ileeṣẹ ọlọpaa ko ni kaarẹ ninu akitiyan rẹ lati maa pese abo to peye fun araalu ati dukia wọn.