Hisbah mú àwọn ọ̀dọ́ tó ń jẹ ọ̀sán lásìkò ààwẹ̀ Ramadan

Aworan to n kede ajọ Hisbah ati agbegbe ti wọn wa nipinlẹ Kano

Oríṣun àwòrán, Hisbah M,agazine/ Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ikọ ọlọpaa to n lo ofin Sharia ti a mọ si Hisbah, ti mu awọn ọdọ kan ti wọn ni wọn n jẹun lọsan-an aawẹ Ramadan nipinlẹ Kano.

Gẹgẹ bi Dokita Mujahideen Abubakar, Igbakeji adari Hisbah ṣe ṣalaye, ọjọ akọkọ ninu oṣu Ramadan ni ọwọ ba awọn ọdọ naa.

Tẹ o ba gbagbe, ọkan ninu awọn ipinlẹ ti wọn ti n lo ofin Sharia ni Naijiria ni ipinlẹ Kano jẹ.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lori awọn tọwọ ba naa, Abubakar sọ pe o ṣe pataki lati jẹ kawọn eeyan tẹle ofin to de ilu ti wọn n gbe, paapaa julọ, awọn Musulumi.

O ni awọn ki i mu ẹni ti ko ba ki n ṣe ẹlẹsin Islam bi ko ba gba aawẹ, ṣugbọn fun awọn eeyan to jẹ Musulumi, awọn yoo fọwọ ofin mu ẹni to ba ṣẹ si ofin naa.

Aworan awọn ọmọ ogun Hisbah lẹyin ọkọ wọn

Oríṣun àwòrán, Hisbah

Àwọn onikẹkẹ maruwa tó ń gbé ọkùnrin àti obìnrin pọ̀ náà bọ́ sọ́wọ́ Hisbah

Yatọ si awọn ti ko gba aawẹ tọwọ ba, awọn onikẹkẹ marwa tó ń gbé ọkùnrin àti obìnrin pọ̀ náà tun bọ́ sọ́wọ́ ikọ Hisbah.

Ikọ Hisbah sọ pe ikọni ẹsin Islam lodi si pe ki ọkunrin ati obinrin ti wọn ki i ṣe tọkọ-taya maa fi ara ro ara wọn lawujọ.

Eyi ni wọn lo fa a tawọn fi n mu awọn onikẹkẹ to ba lodi sofin ẹsin yii nipinlẹ Kano.

Bakan naa ni ofin Sharia tun mu awọn eeyan to gẹrun ti wọn ni ko tọna si ori wọn.

Fifa ori apa kan ki eeyan si da apa kan si, lodi si ẹkọ Islam bi Hisbah ṣe wi.

Eyi si ni wọn ṣe tun fi ọwọ ofin mu awọn eeyan ti wọn gẹrun naa sori lasiko Ramadan yii.

Eyi kọ ni igba akọkọ ti Hisbah yoo nawọ gan awọn eeyan to n jẹun nita gbangba ninu aawẹ Ramadan, lọdun to kọja, eeyan mọkanla ni wọn mu lori ẹsun yii kan naa.

Lawal Fagge, agbẹnusọ Hisbah, fidi ẹ mulẹ pe ọwọ awọn ti ba awọn kan lori ẹsun yii lọdun yii naa.

O ni ṣugbọn awọn ti da wọn silẹ bayii, lẹyin ti wọn ti ṣeleri pe awọn ko ni i jẹun lọsan-an aawẹ mọ.