NLC kéde ìwọ́de yíka Nàìjíríà tí ìjọba bá ṣe àfikún owó iná míì

Aworan Joe Ajaero

Oríṣun àwòrán, NLC/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ti kede pe awọn yoo ṣe iwọde kaakiri Naijiria ti ijọba ba tẹsiwaju pẹlu erongba rẹ lati ṣe afikun tariifu owo ina mii.

Ninu atẹjade kan to fi sita lẹyin ipade igbimọ alaṣẹ NLC niluu Yola ni ipinlẹ Adamawa lopin ọsẹ to kọja ni ẹgbẹ naa ti ṣapujewe erongba ijọba lati ṣe afikun owo ina mọnamọna gẹgẹ bi igbesẹ ti ko dara fawọn oṣiṣẹ ati fun gbogbo araalu.

Ṣaaju ni ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ina mọnamọna ti kilọ fun ijọba apapọ lori ipinnu rẹ lati ṣe afikun tariifu owo ina, wọn ni ko yẹ kawọn ọmọ Naijiria maa sanwo fun bi wọn ṣe n wa ninu okunkun latari bi ina ọba to n ṣe ṣegeṣege.

Ẹgbẹ NLC sọ ninu atẹjade to fi sita pe ileeṣẹ ijọba to n ri si ina mọnamọna ati ajọ NERC to n ṣamojoto lilo ina n dọgbọn lati ko awọn onibaara to wa ni ''Band B ati C'' lọ si "Band A'' ni pẹlu erongba wọn lati ṣe afikun owo ina.

NLC ni kii ṣe pe ijọba fẹ ki ina ọba duro deedee lo ṣe fẹ ṣe afikun owo ina, bi ko ṣe lati dakun iṣoro to n koju araalu.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

''Ẹgbẹ oṣiṣẹ ṣetan lati tako igbesẹ ijọba lori erongba rẹ lati ṣe afikun tariifu owo ina''

Ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC sọ ninu atẹjade to fi sita lẹyin ipade rẹ pe ''ijọba fẹ ki oṣi ati iṣẹ to n bawọn ọmọ Naijiria finra pọ si pẹlu erongba rẹ lati maa ṣe afikun owo ina loore koore ati afikun owo ori tawọn araalu n san.

Amọ, awa ẹgbẹ oṣiṣẹ naa ṣetan lati tako igbesẹ ijọba lori erongba rẹ lati ṣe afikun tariifu owo ina.''

Igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ ti sọ fun gbogbo awọn ẹka ẹgbẹ naa kaakiri Naijiria lati gbaradi fun iwọde ti ijọba ba le tẹsiwaju pẹlu ipinnu rẹ.

NLC ni kii ṣe asiko yii ti ọwọngogo nnkan gbode ni Naijiria lo tun yẹ ki ijọba maa gbero lati ṣafikun owo ina.

Ẹgbẹ naa ni ọgọọrọ ọmọ Naijiria lo jẹ wi pe tipa tipa ni wọn fo n ri ounjẹ lasiko yii, nigba ti ijọba si n ti awọn nnkan to yẹ ki wọn ṣe si ọdọ araalu.

Igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ NLC ni ẹgbẹ oṣiṣẹ ko ni maa woran ki ijọba maa fi ọmọ Naijiria ṣowo.

Fun ọpọlọpọ ọdun bayii ni orilẹede Naijiria ti n koju ipenija ina ọba to n ṣe ṣegeṣege eyi to ti ṣakoba fun ọrọ aje.

Bo tilẹ jẹ pe ijọba ti sọ ileeṣẹ mọnamọna orilẹede Naijiria di ti aladaani, oniruuru ipenija lo si tun n koju ẹka pẹlu bii awọn irinṣẹ amunawa ṣe n dẹnukọlẹ ni gbogbo igba.

Ti ẹ o ba gbagbe, lọdun 2024 ni ajọ NERC ṣe afikun owo ina eyi to jẹ kawọn onibaara to wa ni isọri ''Band A'' maa sanwo to pọju julọ.