Ansoogun ògbóǹtarìgì jagunjagun Iresa Adu l'Ogbomoso 'tó bínú di òkúta pẹ̀lú àwọn ẹrú rẹ̀'

Aworan Ansoogun ni Iresa Adu l'Ogbomoso
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Bi ọmọ ko ba itan, yoo ba arọba tori arọba ni baba itan, bẹẹ ni ọrọ akọni Oodua, Ansoogun yii ṣe ri gan an.

Ansoogun jẹ ilumọọka jagunjagun to gbona nigba aye rẹ, oun si awọn eeyan mọ gẹgẹ bii baba gbogbo ilu Irẹsa l'Ogbomoso.

Oloye James Olawale to jẹ Baba Irasa ni Irẹsa Adu lo farabalẹ ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun BBC Yoruba nigba ti a kan sibẹ.

Gẹgẹ bi Oloye Olawale ṣe ṣalaye, Ansoogun ati awọn ẹru ati ẹṣọ rẹ ti wọn jọ n bọ lati oju ogun lo di okuta oriṣiiriṣi lori apata niluu Iresa Adu.

''Ansoogun lọ jagun lọjọ kan ni o gba iroyin ibanujẹ nigba to n pada bọ wa sile lo ba binu wọlẹ to si di okuta ni agbegbe Iresa Adu nijọba ibilẹ Suurulere ni Ogbomoso ni ipinlẹ Oyo ni guusu iwọ oorun Naijiria.

Koda, kii ṣe Ansoogun nikan lo di Apata nla o, gbogbo ẹru ati ẹṣọ to wa pẹlu rẹ lasiko naa lo sọ di apata yika ara rẹ ni agbegbe naa.''

Oloye Olawale salaye pe gbogbo nkan ti wọn fi n bọ oriṣa Ogun naa ni wọn fi n bọ Apata Ansoogun bii aja, epo, ẹmu, obi ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Koda, Oloye ni Baba Ansoogun to di apata yii a maa ranṣẹ beere fun ẹbọ nigba miran tabi fun etutu.

O ni Baba Ansoogun a maa gbọ adura loju ẹsẹ, ati pe ko si ohun ti eeyan wa beere lọwọ rẹ ti kii ṣe fun eeyan.

Eewọ ti ojubọ apata yii ni ni pe Ọba kankan ko gbodọ foju kan apata Ansoogun.

Oloye ni iru Oba bẹẹ kọ lo maa pada sile lọjọ to ba dẹjaa

Idi niyi ti wọn fi maa n mu gbogbo Oba ni Ogbomoso wa si iloro ọna apata yii fun etutu ṣugbọn wọn ko ni jẹ ki Oba rin sori apata naa tabi ko sunmọ ọ ju lati fi oju kan apata naa.

BBC Yoruba maa n jade lọ kaakiri ilẹ Yoruba lati gbe iroyin jade nipa awọn akọni Oodua ki itan Yoruba ma baa parun.