Kókó ọ̀rọ̀ tí Ààrẹ Tinubu sọ lórí àwẹ̀ Ramadan tó bẹ̀rẹ̀

Aworan Aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Ahmed Bola Tinubu/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ Bola Tinubu ti sọ awọn koko ọrọ kan lori awẹ Ramadan to bẹrẹ lonii ọjọ kinni oṣu Kẹta ọdun yii.

Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ aarẹ fi sita eyi ti Tinubu funra rẹ buwọlu ni o ti sọ pe asiko awẹ Ramadan jẹ asiko ifi ara ẹni jin si Allah ati asiko lati maa ṣaanu fawọn eeyan.

Tinubu ni asiko awẹ jẹ asiko iko ara ẹni ni ijanu ati asiko fifi ifẹ han sawọn eeyan papaa julọ si awọn alaini.

Aarẹ Naijiria wa rọ awọn musulumi to n gba awẹ lati mu awọn ẹkọ to wa ninu awẹ lo nipa wiwu iwa irẹlẹ ati sisa fun iwa adanikanjọpọn eyi ti oṣu yii da lori.

Aarẹ Tinubu ni o yẹ kawọn musulumi lo asiko yii lati sun mọ Allah ki wọn si tun gbadura fun alaafia ati iṣọkan awujọ wọn.

''Awẹ Ramadan ọdun yii ṣe pataki tori o bọ si asiko ti eto ilọsiwaju ati ireti tuntun n lọ lọwọ ni Naijiria.

Awọn oniruuru eto ti ijọba apapọ dawọ le ti n so eso rere pẹlu bi ọrọ aje wa ti n gberu sii diẹ diẹ.

Akọsilẹ GDP oṣu mẹta to kẹyin lọdun 2024 fi han pe o dara ju ti ọdun 2023 lọ.

Ounjẹ to gbowo lori tẹlẹ ti lọọlẹ bayii, eyi si ti mu aye rọrun fawọn to n gba awẹ atawọn ọmọ Naijiria lapapọ.

Owo naira naa ti n gberu sii ju ti tẹlẹ lọ si owo dọla, bakan naa ni adinku tun ti ba owo epo bentiroolu eyi to n ṣapujuwe ọjọ iwaju to dara fun Naijiria,'' Tinubu ṣalaye.

Aarẹ tun fikun ọrọ rẹ pe ijọba oun ko ni dẹkun akitiyan rẹ lati ri pe ẹka eto ọgbin duro deedee.

Aworan atẹjade ileeṣẹ aarẹ

Oríṣun àwòrán, State House Digital

Tinubu ni ijọba yoo ri pe ounjẹ sun ọmọ Naijiria bọ, ati pe ijọba yoo tun ṣeto to dara fun fifi ounjẹ pamọ bakan naa.

O ni ijọba yoo ṣe iranwọ fawọn agbẹ to n gbin ounjẹ pẹlu irinṣẹ fun oko dida ki ounjẹ le tubọ pọ si.

Aarẹ ni ijọba oun ko ni beṣu bẹgba lati ri pe orilẹede Naijiria di ilẹ ọlọra.

Tinubu wa kepe gbogbo ọmọ Naijiria lasiko oṣu alapọnle yii wi pe ki wọn gbadura fun idasoke ati ilọsiwaju orilẹede wọn.

O ni ki wọn beere fun itọni ati abo Allah lori orilẹede Naijiria lasiko awẹ yii bakan naa.

Aarẹ wa gbadura fun gbogbo awọn to n gba awẹ lasiko yii pe ayọ, alaafia ati ibukun oṣu Ramadan yoo jẹ ti wọn ati ẹbi wọn.