Kí ló fà á tí àwọn ṣọ́jà Naijiria ń 'ṣèṣì' ju àdó olóró lu aráàlú?

Oríṣun àwòrán, AFP
- Author, Yusuf Akinpelu
- Role, BBC News
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Fun igba mẹta loṣu mẹta sẹyin, o le ni eeyan ọgbọn ti wọn padanu ẹmi wọn sọwọ ikọlu awọn ologun Naijiria to ṣeṣi ran wọn lọ si ọrun aṣante.
Alakọọkọ rẹ waye loṣu Kejila, nibi ti ọkọ ofurufu awọn ologun ti pa eeyan mẹwaa nipinlẹ Sokoto, ninu ikọlu ti gomina ilu naa sọ pe awọn ologun ṣeṣi doju rẹ kọ araalu ni.
Nigba to di oṣu Kin-in-ni, o kere tan, eeyan mẹrindinlogun ni ado oloro awon ologun Naijiria pa ninu awọn ikọ fijilante kan ni Tungar Kara, eyi to wa nipinlẹ Zamfara.
Awon ṣọja sọ pe awọn ro pe ikọ ọdaran ni wọn ni.
Loṣu Keji, ikọ ologun Naijiria kan ṣeṣi pa araalu mẹfa nigba ti wọn n le awọn ọdaran kan ni Ariwa Iwọ-Oorun ipinlẹ Katsina.
Ọpọ eeyan lo ti tọwọ awọn ikọ ologun Naijiria ku iku ojiji, ninu awọn abule wọn ti wọn jokoo si jẹjẹ lapa Ariwa ilẹ Naijiria.
Pupọ ninu awọn to di oloogbe yii ni won jẹ ọlọde adugbo ta a mọ si fijilante, ohun ti awọn ologun si n wi gẹgẹ bi awijare ni pe awọn ọdaran lawọn n foju sun, ki i se araalu.
Igba mi-in si wa ti wọn yoo ni awọn gba pe awọn ṣe aṣiṣe, ti wọn yoo si tọrọ aforiji.
Ileeṣẹ ologun ilẹ America, UK ati awọn mi-in n ṣatilẹyin fun awọn ologun Naijiria.
Atilẹyin naa n waye lati gbogun ti awon ikọ agbesunmọmi to n ṣọṣẹ lapa Ariwa orilẹede yii.
Ko din ni ikọlu mẹtadinlogun ti wọn lo ṣeṣi waye lati ọwọ awọn ologun Naijiria laaarin oṣu Kin-in-ni ọdun 2017 ati oṣu Kẹsan-an ọdun 2024.
Eeyan to le ni ẹẹdẹgbẹta (500) ni wọn pa, gẹgẹ bi akọsilẹ SBM intelligence ṣe sọ.
Ki waa ni idi rẹ ti ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria fi n pa awọn araalu leralera.
Ohun ti awọn kan n sọ ni pe ikuna lati ṣe ohun to yẹ lo n fa ikọlu naa.
Fun apẹẹrẹ, awọn eeyan sọ fun BBC pe nigba ti awọn ologun ṣeṣi ju ado oloro lakọọkọ si abule Tudunbiri, ni Kaduna, ti awọn araalu pariwo pe awọn ni wọn n pa, sibẹ, wọn tun ju ado ẹlẹẹkeji, to bẹẹ ti awọn to ku fi di marundinlaadọrun-un (85).
Bakan naa ni lilo irinṣẹ ogun ti a mọ si drone si jẹ ajoji bakan nilẹ Africa.
Orilẹede China ni wọn ni o n lewaju ninu awọn orilẹede to n ko drone wọle ju si awon ilu miran.
Orilẹede Naijiria naa si ti gba oriṣiriṣi rẹ, gẹgẹ bi Guy Martin , Olootu iwe iroyin Defence Web ṣe sọ
Bẹẹ ni wọn sọ ọ di mimọ pe ọpọ orilẹeede ilẹ Africa naa ni wọn ti gba ẹrọ yii, ṣugbọn ẹkọ to yẹ fun lilo rẹ fun awọn ṣọja naa ni ko ti i to bi Guy Martin ṣe sọ.
Awọn ẹrọ yii ti wọn ba wa lati China, Russia, Turkey ati Iran maa n dinwo, oun si ni awọn eeyan n ra ju nilẹẹ Africa.
Awọn ijọba ilẹ Adulawọ mi-in ko si ki n tọpinpin ohun ti wọn n fi owo wọn ra.
Eyi lo fi jẹ pe bi ijamba ba ṣẹlẹ, o maa n ṣoro lati mọ bo ṣe ṣẹlẹ gan-an.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ohun tó ń fa àṣìjù àdó olóró
Anietie Ewang, ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ Human Rights Watch (HRW) sọ pe bi won ṣe n lo irinṣẹ drone yii wa lara idi pataki to fi n fa iku alaiṣẹ.
O ni awọn ilẹ Amẹrika ati ilẹ Gẹẹsi to n ti Naijiria lẹyin ko ṣe ileeṣẹ ologun ti wọn bi Naijiria ṣe n ṣe tiẹ.
Attah Jesse Olottah, ọkan lara awọn to n ṣayẹwo ijamba to ba ṣẹlẹ, sọ pe bẹẹ gẹlẹ ni ohun ti Ewang sọ ri.
Bi drone ṣe pọ jẹ ko rọrun fawọn ologun lati lo fun jiju ado oloro, ṣugbọn ẹkọ to yẹ fun lilo rẹ ati bi won yoo ṣe jẹ atamatase nipa lilo rẹ ko to.
Jesse lo sọ bẹẹ.
O ni bi wọn ba dida sẹria fun ologun to ba ṣẹ ko to, bi ko ṣe pe kawọn ilẹ okeere to n ṣatilẹyin fun awọn ti ilẹ eeyan dudu kọ wọn lẹkọọ to yẹ, ki wọn si kẹkọọ ninu ogun ati ede aiyede to ba n waye.
Ohun to tun wa nibẹ ni pe ko si ifiyajẹni kankan fun awọn ṣọja to ti ju ado oloro paayan ri yii, afi nigba ti eyi to waye ni Tudunbiri ṣẹlẹ.
Bi wọn ba ba wọn wi diẹ, won ki i kede ẹ ki araalu gbọ. Bẹẹ ni Jesse Olottah ṣalaye.
Bakan naa ni ọga ologun, Maj-Gen Edward Buba, sọ pe awọn ṣọja meji lo n jẹjọ lọwọ bayii ni kootu ologun.
O ni bi wọn ṣe n jẹjọ naa lọwọ ni wọn ti taari wọn si ibo mi-in.
Ni awọn agbegbe bii Tudunbiri, awọn araalu ṣi n beere fun idajọ ododo, nigba ti wọn ko fi aaye fun wọn lati ri ẹbun gb- ma-binu kankan gba, ti wọn ko ri nnkan kan lẹyin ileri ofo ti wọn ṣe fun wọn .

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọ̀nà àbáyọ
"A gbọdọ ri i daju pe a ro ti awon ti ikọlu ba mọ tiwa. Ka si ri i pe a da ikolọ wọn pada. " Ewang lo sọ bẹẹ.
Obinrin naa sọ pe ohun to yẹ ka bi ara wa leere ni pe ṣe lilo ẹrọ drone yii lati fi gbogun ti igbesunmọmi l'Oke Ọya tiẹ n ṣiṣẹ ti a fẹ ko ṣe.
O ni to ba jẹ pe a ri esi si eyi, boya yoo ṣee ṣe fun Naijiria lati doola, ki wọn si da aabo bo ọpọ ẹmi to n ṣofo.
Olottah ni ti ẹ sọ pe awọn ologun gbọdọ fi ọgbọn inu, afojusun ati ẹkọ to ye kooro kun iṣẹ wọn.
O ni bi awọn ologun Naijiria ba fẹẹ bori igbesunmọmi, wọn gbọdọ ṣetan lati din bi ikọlu ti wọn n sọ pe o ṣeṣi ni yii ṣe n waye ku.
"Ọga ologun Buba ninu ọrọ rẹ, ṣalaye pe bi awọn ṣọja ṣe n ṣiṣẹ kaakiri, awọn ti dangajia ninu irinṣẹ lilo bayii, awon si ti n lo awọn ọmọ ogun to too fiṣẹ ogun ran.













