Tó bá jẹ́ pé òkú ma ń wo ẹ̀yìn, ọkọ mi yòó ti sun ẹ̀kún gálọ̀ọ́nù kan - Ìyàwó Mohbad

Àkọlé fídíò,
Tó bá jẹ́ pé òkú ma ń wo ẹ̀yìn, ọkọ mi yòó ti sun ẹ̀kún gálọ̀ọ́nù kan - Ìyàwó Mohbad

Iyawo gbajugbaja akrin takasufe, Ilerioluwa Aloba, Mohbad, ti sọ pe iku ọkọ rẹ jẹ ki oun mọ pe, eniyan buru pupọ.

Ninu ifrọwanilẹnu wo to ṣe pẹlu BBC Yoruba, Arabinrin Omowunmi Aloba, sọ pe ọkọ oun yoo ti sun ẹkun to le kun inu galọọnu kan, nitori pe "to ba tilẹ ro pe ẹnikan maa ba ẹyin rẹ jẹ, ko le ro pe baba oun ni".

Wunmi to sọrọ lori awọn idojukọ to n ni lati igba ti Mohbad ti jade laye lọdun 2023 sọ pe, gbogbo nnkan to ba gba ni oun yoo fun un, lati jẹ ki ọmọ rẹ, Liam, ri aye gbe.

Lati igba ti Mohbad ti ku, oriṣiriṣi nnkan lo ti ṣẹlẹ, paapaa laarin awọn obi oloogbe, iyawo rẹ, ati awọn ojugba rẹ.

Arabinrin naa sọ pe ẹni to yẹ ko jẹ alaabo fun oun ati ọmọ oun gan-an lo n fa awọn le awọn ti yoo fi aye su awọn.

"Iyẹn nikan jẹ nnkan to ma n jẹ ibanujẹ ọkan fun mi."

Nibo ni nnkan de lori ọr DNA ti baba ọkọ rẹ ni ko ṣe?

Omowunmi Aloba

Arabinrin Omowunmi Aloba sọ pe oun ti ṣetan tipẹ lati ṣe ayẹwo DNA. O ni ṣugbọn, baba ọkọ oun ni ko tii gba lati kopa ninu rẹ.

"Lori ọrọ DNA, a kan wa loju kan ṣa."

Lori ẹsun ti awọn kan fi kan Wunmi pe oun lo ti ọkọ rẹ pa, o ni ipo alailagbara ni oun wa bayii nitori nnkan ti awọn eeyan n ṣe si o.

"Ko si idi kankan ti wọn ko ṣe ti i sin oku ọkọ mi, tabi ṣe DNA. Awọn lo wu lati ṣe bo sẹ wu wọn."