Èèyàn méje dèrò ẹ̀wọ̀n lórí ikú Mojisola Awesu tó jáde láyé lẹ́yìn tó bá ọkùnrin lọ ilé ìtura

Aworan Mojisola Awesu

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Adajọ Ibrahim Yusuf ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Kwara ti paṣẹ pe ki awọn afurasi meje ti ileeṣẹ ọlọpaa mu pe wọn lọwọ ninu Iku Mojisola Awesu, akẹkọọ ile ẹkọ giga gbogbo niṣe Kwara, to wa ni ilu Offa lọ ma gba atẹgun lọgba ẹwọn.

Aṣẹ ile ẹjọ yii lo waye lẹyin ti agbẹjọro awọn oṣiṣẹ ile itura mẹta; Adeoye Adeola, Lawal Aminat ati Peter Bulus, ti wọn jẹ olujẹjọ karun un, kẹfa ati keje ninu igbẹjọ naa kọ lati yọju si ile ẹjọ.

Eeyan meje lo n foju ba ile ẹjọ lori ẹsun siṣe iku pa Awesu, akẹkọọ to wa ni ipele aṣekagba Kwara College of Health Technology, to wa ni ijọba ibilẹ Offa.

Awọn afurasi naa ni Happiness Adebayo ati Timileyin Kolawole, ti wọn lewaju ninu afurasi, pẹlu Adebayo Adeniyi ati Bukola Adeniyi, ti wọn jẹ obi Happines, ati Adeoye Adeola, Lawal Aminat ati Peter Bulus ti wọn jẹ oṣiṣẹ ile itura ti wọn ti ṣekupa Awesu.

Bawo ni Mojisola ṣe di awati?

Ọlọpaa sọ ninu atẹjade pe ọjọ kẹtala, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 ni wọn fi to ileeṣẹ naa leti pe oloogbe ọhun di ẹni ti wọn n wa.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Kwara sọ pe "Lọjọ kẹtala, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024, ni nnkan bii aago mẹrin abọ irọlẹ, omidan kan, Blesson O, to n gbe lagbegbe Gbomi, niluu Offa, nipinlẹ Kwara sọ fun wa pe alabagbe oun ninu yara kan naa, Omidan Mojisola Awesu, ẹni ọdun mọkanlelogun to jẹ akẹkọọ Kwara State College of Health Technology, ti di awati lati ọjọ kẹsan an, oṣu Kẹjọ.

"Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, Mojisola gba ipe lati ọdọ Omidan kan ti orukọ rẹ n jẹTimileyin, to ni ko yọju sibi ode ariya kan ti yoo waye ni fasiti Summit ati Al-HikmaH, niluu Ilorin.

"Omidan Timileyin fa Mojisola le Ọgbẹni kan to n jẹ Adebayo Happiness lọwọ, to jẹ akẹkọọ fasiti Summit, ti Adebayo si ni ko ba oun lọ ode ariya nibi ti yoo ti dibọn gẹgẹ bii ọrẹbinrin oun ti oun yo si fun ni ẹgbẹrun marundinlogun naira."

Ọlọpaa ṣalaye pe nigba ti oloogbe ọhun yoo de ibẹ, o pe alabagbe rẹ pe ile itura ti Adebayo Happiness fi oun si ko tẹ oun lọrun ati pe ko si ayẹyẹ kankan to n waye nibẹ.

Gẹgẹ bii ohun ti ọlọpaa sọ, lẹyin to fi ọrọ naa ranṣe si alabage rẹ tan ni ẹrọ ilewọ rẹ ku ti ko si si aaye lati kan si mọ.

Agbẹnusọ ọlọpaa ṣalaye siwaju si pe awọn ti tare ọrọ naa lọ si ẹka CID fun iwadii ni kikun.

Kọmiṣọna ọlọpaa, CP Victor Olaiya si ti ṣeleri lati tu iṣu de isalẹ ikoko iṣẹlẹ naa.

Ki ni adajọ sọ?

Adajọ Yusuf ni oun fun awọn afurasi naa ni oreọfẹ lati wa agbẹjọro ti yoo wa ṣoju wọn ṣugbọn ohun iyalẹnu ni pe oun ko ri ẹnikẹni ko wa ṣoju wọn.

Adajọ naa ni "Lonii, ọpọ yin lo tun wa si ile ẹjọ lai mu agbẹjọro yin wa, mo tun fun yin ni ore ọfẹ miiran titi di ọjọ ti mo sun igbẹjọ si. N ko ni faye gba eyi.

"Ẹsun ọdaran to ni ṣe pẹlu iṣekupani, mi o ni faye gba. Ẹ n fi ẹjọ yii falẹ

"Mo wa n pa laṣẹ pe ki gbogbo awọn afurasi wa ni ọgba ẹwọn niluu Ilorin titi di ọjọ ti a sun igbẹjọ si. Gbogbo afurasi gbọdọ mu agbẹjọro ni ọjọ ti sun igbẹjọ si ni ọjọ kẹrin, oṣu Kẹta, ọdun 2025."