Rògbòdìyàn láàárín ìlú méjì ní ìpínlẹ̀ Edo mú ẹ̀mí èèyàn méje lọ, mẹ́fà farapa

Riot

Oríṣun àwòrán, @radionigeriahq

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ko din ni eeyan meje to ti jade laye, ti awọn mẹfa mii si farapa yanyana lẹyin ija laarin ilu meji kan nipinlẹ Edo.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Edo, Moses Yamu, lo fidi iroyin naa mulẹ.

Gẹgẹ bii alaye Yamu, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Keji yii ni ọlọpaa gba ipe pajawiri nipa ija laarin ilu Gbelemonti ati Maidoti ni ijọba ibilẹ ila oorun Ovia.

Ni kete ti ọlọpaa gba ipe naa ni awọn ọlọpaa lati agọ Iguobazu

wa, awọn ọlọdẹ atawọn ọmọ ogun tekọ leti lọ sibẹ.

O ni "ikọ wa ko awọn eeyan kan lọ ile iwosan nibi ti wọn ti fidi rẹ mulẹ pe eeyan meje ti padanu ẹmi wọn, ti awọn mẹfa si n gba itọju lọwọ.

Yamu sọ siwaju si pe ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori ohun to ṣokunfa rogbodiya naa.

O fi kun pe kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ ọhun, Betty Otimenyin, ti ṣeleri pe ọlọpaa yoo ṣe gbogbo ohun to yẹ lati ri daju wọn tu iṣu de isalẹ ikoko iṣẹlẹ naa.

Alukoro ọlọpaa ọhun sọ siwaju si pe ibaṣepọ awọn pẹlu ileeṣẹ ọmọ ogun atawọn ọdẹ ibilẹ lati tete pa ina rogbodiyan naa so eso rere.

O juwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii eyii ti ko yẹ ko waye rara to ba jẹ pe awọn eeyan ko fi ofin si ọwọ ara wọn.

O pari atẹjade naa pe ki araalu dẹkun ati maa fi ofin si ọwọ ara wọn amọ ki wọn maa fi ọrọ to le da wahala silẹ to awọn agbofinro leti.

Wayi o, ọlọpaa ko mẹnuba ohun to ṣokunfa wahala naa.