PDP fìdí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú yòókù janlẹ̀ nínú ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ nípìnlẹ̀ Osun

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke/X
Esi idibo awọn alaga ijọba Ibilẹ ati kasilọ ipinlẹ ọsun ti jade.
Ọjọ kejilelogun, osu Keji, ọdun 2025, ni idibo sipo alaga ijọba Ibilẹ ati kanselọ waye l'osun.
Ko ju wakati mẹta lọ ti gbogbo eto idibo naa ti pari.
Kika esi idibo naa lo waye ninu ọgba ile ijọba ipinlẹ Osun to wa ni agbegbe Oke-fia niluu Osogbo.
Eyi waye nitori bi awọn ọlọpaa ṣe ti ofiisi ajọ eleto idibo pa, ti a ko si ti mọ oun to sokunfa eyii.
Ninu ẹgbẹ oselu mejidinlogun to kopa ninu eto idibo naa, ẹgbẹ oṣelu PDP nìkan lo jawe olubori ni gbogbo ijọba ibilẹ ọgbọn gẹgẹ bii alaga ijọba Ibilẹ.
Bakan naa ni ẹgbẹ oselu PDP lo tun jawe olubori nibi ibo awọn kanselọ naa.
Ti gbogbo kanselọ naa si jẹ 332.
Alaga ajọ eleto idibo, Hashim Abioye, rọ gbogbo wọn, ki wọn maa ṣe gbagbe gbogbo ileri ti wọn ṣe ni akoko ipolongo idibo wọn fun awọn ara iluu.
Àkójọpọ́ àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ tó wọlé
Orukọ awọn to jawe olubori gẹgẹ bi alaga, ati ijọba ibilẹ wọn:
1. Boripe - Babalola Wasiu Kayode
2. Egbedore - Okunade Oluwafemi Adesanya
3. Ife Central - Adeyenuwo Rotimi John
4. Obokun - Agboola Francis Olajire
5. Isokan - Azeez Lateef Adeniran
6. Boluwaduro - Aina Abayomi Adesina
7. Ola Oluwa - Sodiq Samuel Oluwapelumi
8. Irepodun - Ajibade Oluwatoyin S.
9. Ilesa West - Adebanjo Oladiti Tunmininu
10 . Atakumosa East - Ibironke Alade Adegboye
11. Ife South- Aroke Muyiwa Aderemi
12. Olorunda - Kolade Obafemi Kolawole
13. Iwo - Moshood Adekunle Kabiru
14. Ifelodun - Awotunde Abiodun Sarafadeen
15. Osogbo- Akande Taiwo Adekunle
16. Atakumosa West - Dada Feyisayo Ajibola
17. Ede North - Amodu Taiwo
18. Ifedayo - Atolagbe Kayode Olayinka
19. Ife North - Akande Micheal O.
20. Oriade - Adeyekun Taiwo Adebayo
21. Ayedaade - Adeniran Adenike Felicia
22. Ede South - Afolabi Oyekola Lukman
23. Ife East - Odunyemi Haruna Bukola
24. Irewole - Jooda Ambali Babajide
25. Odo Otin - Adewale Adeyinka Oluwaseun
26. Ayedire - Ogunbiyi Solomon Akinyemi
27. Ejigbo - Raimi Adenike Nafisat
28. Ila - Adebisi Jayeola Nasir
29. Ilesa East - Ilesanmi Taiwo Sunday
30. Orolu - Alade Aderemi Fatai












