Tọkọ taya tó dàgbà jùlọ lágbàáyé sọ ìrírí wọn lẹ́yìn tí ìgbéyàwó wọn pé ọdún 83

Oríṣun àwòrán, Guinness World Records/X
Tọkọ taya to dagba julọ lagbaaye, Lyle ati Eleanor Gittens, ti sọ iriri wọn lẹyin ti wọn wọ inu iwe itan pẹlu irinajo ifẹ wọn.
Lyle ati Eleanor Gittens ti wọn jẹ akẹkọọ nile ẹkọ giga fasiti Clark Atlanta University pade ara wọn lọdun 1941 lọdun mẹrindinlelọgọrin sẹyin.
Kete ti wọn pade ara wọn ni wọn ti mọ pe Eledua ti kọ wọn papọ, eyi lo si jẹ ki wọn ṣe igbeyawo lọdun keji to tẹle ọdun ti wọn pade ara wọn.
Ẹni ọdun mejidinlaadọfa (108) ni Lyle i ṣe nigba ti iyawo rẹ Eleanor jẹ ẹni ọdun mẹtadinlaadọfa (107).
Tọkọ taya yii kii ṣe ọkọ ati iyawo to dagba julọ lagbaaye ti wọn si laaye lasan, awọn tun ni tọkọ taya to dagba julọ ninu itan lagbaaye.
Nigba ti wọn kọkọ pade nile ẹkọ, ninu ẹgbẹ agbabọọlu alapẹrẹ ni Lyle wa nigba ti Eleanor maa n tẹle e lọ sibi to ti n gbabọọlu naa.
Ninu ifọrọwerọ ti wọn ṣe pẹlu LongeyiQuest, Eleanor sọ pe oun ko le ranti nnkan to ṣẹlẹ nibi ere bọọlu alapẹrẹ naa mọ.
Nnkan ti Eleanor le ranti ni pe nibi ere bọọlu ọhun ni o ti pade Lyle ti wọn si pada fẹ ara wọn bii tọkọ taya.
Awọn mejeeji da ọjọ igbeyawo wọn bo tilẹ jẹ wọn mọ pe o ṣee ṣe ki ijọba ni ki Lyle lọ jagun lasiko ogun agbaye ekeji.
Ọjọ kẹrin oṣu Kẹfa ọdun 1942 ni wọn ṣe igbeyawo wọn, ọjọ mẹta ni wọn fun Lyle lati ibi igbaradi awọn ologun pe ko fi lọ ṣe igbeyawo.
Igbeyawo wọn ti pe ọdun mẹtalelọgọrin lodun 2025 bayii.
Mo ranti igba ti Lyle n lọ soju ogun ti n ko si mọ bo ya ọkọ mi yoo pada wale mọ - Eleanor
Eleanor ranti ninu ifọrọwanilẹnuwo kan ti o ṣe pẹlu The Westside Gazette bi Lyle ti lọ soju ogun ti ko si mọ bo ya ọkọ rẹ yoo pada wale mọ lai lai.
Wọn tun ran Lyle lati lọ ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ ologun the 92nd Infantry Division lorilẹede Italy.
Eleanor ti wa ninu oyun akọbi wọn nigba naa, asiko yii gan an lo lọ siluu New York nibi to ti pade ẹbi Lyle fun igba akọkọ.
Ni New York lo ti ri iṣẹ pẹlu ileeṣẹ kan to n ṣe ẹya ara baalu, ti o si n kọ lẹta si ọkọ rẹ to wa loju ogun loorekoore.
Lyle ati Eleanor lanfaani lati jọ maa gbe papọ nigba ti ogun agbaaye ẹlẹẹkeji pari.
Niluu New York ni wọn wa pẹlu idile wọn nibi ti wọn ti bi ọmọbinrin meji, Angela ati Ignae, ti wọn jẹ aburo fun ọmọkunrin wọn, Rodgers, ti wọn bi lasiko ogun.
Tọkọ taya yii pada ri isẹ ijọba niluu New York, wọn si n gbe pọ pẹlu ifẹ.
Eleanor pada gboye Ọmọwe ninu imọ eto ẹkọ fun ilu nla ni fasiti Fordham University lẹni ọdun 69.
Awọn mejeeji jọ wa ninu ẹgbẹ awọn akẹkọọjade lati ile ẹkọ giga fasiti Clark Atlanta University fun ọpọlọpọ ọdun.
Nigba ti ọjọ ori awọn mejeeji to ọgọrin ọdun ni Angela ọmọbinrin wọn gbe wọn lọ si Miami ki o le maa ri wọn daadaa.
Lyle si n ṣafẹri ilu New York, amọ, wọn n gbe pẹlu idunnu ni Miami naa.
Nigba ti wọn beere lọwọ awọn mejeeji wi pe ki ni aṣiri bi igbeyawo ṣe pẹ, idahun won ni pe awọn nifẹẹ ara wọn.















