Ṣàǹgbáfọ́! Àwọn ọ̀dọ́bìnrin tí wọ́n fún òrìṣà gẹ́gẹ́bí ìyàwó nílùú ibìkan ti di olówò nọ̀bì!

Oríṣun àwòrán, Sakhi Trust
- Author, Swaminathan Natarajan
- Role, BBC World Service
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
''Ibalopọ ti ṣakoba fun ara mi gan an. O ti jẹ ko rẹmi sara,'' Chandrika lo sọ bẹẹ.
Igbe aye Chandrika gẹgẹ bi olowo nabi bẹrẹ pẹlu ayẹyẹ ijọsin Hindu. Ọmọ ọdun mẹẹdogun lo wa nigba ti wọn ṣe igbeyawo fun un pẹlu oriṣa obinrin kan.
O sọ fun BBC pe ''mi o tii mọ itumọ ẹbọ nigba naa.
Chandrika to din diẹ logoji ọdun bayii ti n ni ibalopọ lati pa owo fun bii ogun ọdun bayii.
Didi olowo nabi lati iyawo ọsingin

Ipinlẹ Karnataka lẹkun guusu orilẹede India n wa awọn eeyan bii Chandrika ti wọn di aṣẹwo lẹyin ti wọn mu wọn wọ inu aṣa ati iṣe devadasi tan.
Aṣa Devadasi tabi ''ẹru oriṣa'' bẹrẹ lorilẹde India ni bi ẹgbẹrun ọdun sẹyin.
Wọn maa n kọrin, wọn si maa n jo tẹlẹ ni ninu ile ijọsin.
Amọ, nigba to ya, davadasi dabi iṣẹ aṣẹwo ṣiṣe.
Lọdun 1982 ni ipinlẹ Karnataka fofin de aṣa yii, amọ, o si tẹsiwaju titi di oni.
Ọpọ awọn obinrin devadasi yii maa n ni ọrẹkunrin, bakan naa si ni wọn tun maa n ni onibaara fun ibalopọ.
Ọpọ ninu wọn maa n lọ silu nla nla bii Mumbai lati lọ ṣiṣẹ aṣẹwo.
Wọn tan awọn obinrin lati maa ṣiṣẹ aṣẹwo
Chandrika pada wale lẹyin ayẹyẹ ifini fun oriṣa ti wọn ṣe fun un tan niluu Belgaum.
Lẹyin to gbe nile fun ọdun mẹrin tan ni ẹnikan mu un lọ si ilu Sangli ti o si fi i si ile aṣẹwo.
''O kọkọ nira fun mi nigba ti mo bẹrẹ, koda, mo ni ailera.
Mo gbero lati salọ, sugbọn mo pada faramọ iṣẹ naa,'' Chandrika lo sọ bẹẹ.
Oniruuru awọn eeyan bi akẹkọọ, amofin, lebira atawọn awakọ lo maa n lọ gbe aṣẹwo nibẹ.
Ni ile aṣẹwo yii ni Chandrika ti ba ololufẹ rẹ pade, isẹ awakọ nla ni ọkunrin naa n ṣe.
O si bi ọmọbinrin kan ati ọkunrin kan fun ara wọn.
Amọ, eyi ko da Chandrika duro lẹnu iṣẹ aṣẹwo ti o n ṣe nibi ti o ti maa n ri onibaara mẹwaa si mẹẹdogun lojumọ.
Baba ọmọ rẹ ku ninu ijamba ọkọ lẹyin to bi ọmọ keji tan, Chandrika si pada siluu Belgaum.
'Awọn ọkun kii wa lati fẹ wa ni iyawo'
Kii ṣe gbogbo obinrin davadasi lo maa n ṣiṣẹ nile aṣẹwo.
Ankita ati Shilpa tawọn mejeeji jẹ ẹni ọdun mẹtalelogun n gbe labula kan lẹkun ariwa ipinlẹ Karnataka.
Lẹyin ọdun kan pere nile ẹkọ ni Shilpa ko le tẹsiwaju ẹkọ rẹ mọ.
Ankita kẹkọọ titi o fi di ọmọ ọdun mẹẹdogun ki awọn obi rẹ to ṣeto fun ayẹyẹ ifiniforiṣa devadasi fun un.
''Awọn obi mi fẹ ki n ṣe igbeyawo pẹlu oriṣa, amọ, mo kọ jalẹ.
Wọn o fun mi lounjẹ mọ, inu mi si bajẹ gidi gan an.
Lẹyin naa ni mo gba lati ṣe ohun ti wọn fẹ, mo si ṣe igbeyawo pẹlu oriṣa,'' Ankita ṣalaye.
Mama ati mama to bi mama Ankita kii ṣe davadasi, amọ ''ẹru ba wa wi pe oriṣa le ṣepe fun wa ti ẹnikẹni ko ba ṣe iyawo pẹlu rẹ ninu ẹbi wa.''
Awọn obinrin to ba ṣe igbeyawo pẹlu oriṣa ko le ṣegbeyawo pẹlu ọkunrin mii.
Ṣugbọn wọn le ni ọrẹkunrin to ba wu wọn.
Ankita kọ lati ṣe ti gbogbo ọkunrin ti wọn n kọ ẹnu ifẹ si i, iṣẹ oko lebira nibi to ti n gba $4 lojumọ lo gbajumọ.

Oríṣun àwòrán, Sakhi Trust

Oríṣun àwòrán, Sakhi Trust
Shilpa bẹrẹ irinajo ifẹ pẹlu ọkunrin kan lẹyin ayẹyẹ igbeyawo rẹ pẹlu oriṣa.
O n gbe pọ pẹlu ọrẹkunrin rẹ nile, o si loyun lẹyin oṣu diẹ ti wọn ti jọ wa papọ.
''$35 ni o fun mi nigba ti a jọ wa papọ, ṣadeedee lo sa kuro nile nigba ti mo wa ninu oyun.
Mo pe e lori foonu ṣugbọn ago rẹ ko lọ, ati pe mi o tiẹ mọ ibi to ti wa gan an.
Awọn ọkunrin kii kọ ẹnu si wa lati fẹ wa ni iyawo,'' Shilpa ṣalaye.
Iṣẹ ati ifinijiya

Oríṣun àwòrán, Sakhi Trust
Dokita M. Bhagyalakshmi to jẹ ọga ajọ Sakhi Trust ti kii ṣe ti ijọba ti n ṣiṣẹ lori awọn obinrin devadasi fun bii ogun ọdun.
O ni awọn eeyan si tun gbe ọmọbinrin wọn ni iyawo fun oriṣa, bo tilẹ jẹ pe ijọba ti fofin de aṣa naa.
''Lọdọọdun ni a maa n da obinrin mẹta si mẹrin ti wọn fẹ sọ di devadasi duro.
Amọ, idakọnkọ ni wọn saba ti maa n ṣe ayẹyẹ ifiniforiṣa naa.
Ninu ẹgbẹrun mẹwaa obinrin devadasi ti a ṣe iwadii le lori lẹkun Vijayanagara, mo ri ọpọ ninu wọn to jẹ alaabọ ara, awọn mii ko riran, ọpọ ninu wọn wọn ni wọn ti sinu rẹ ti wọn ko si nile lori,'' Dokita Bhagyalakshmi ṣalaye fun BBC.

Dokita Bhagyalakshmi ida 95% awọn obinrin devadasi lo wa lati Dalit caste atawọn ileto mii.
O ni ko si anfaani kankan ninu jijẹ obinrin devsdasi ju ijiya lọ.
Awọn ọrẹkunrin awọn obinrin devadasi kii saba lo rọba idaabobo lasiko ibalopọ.
Eyi lo maa n jẹ kawọn obinrin ri loyun.
Fifi opin si aṣa devadasi

Awọn obinrin devadasi pẹjọ siwaju ile ijọsin Saundatti Yellamma nibi ayẹyẹ ti wọn n ṣe.
Amọ, wọn o ṣe igbeyawo tuntun fun ọmọbinrin kankan nibẹ.
Ọmọ ile igbimọ aṣofin kan nipinlẹ Karnataka, Vishwas Vasant Vaidya, sọ pe ijiya wa fun ẹnikẹni to ba fi ọmọbinrin rẹ fun oriṣa.
Vaidya ni aṣa ṣiṣe igbeyawo fọmọbinrin pẹlu ori'sa ti lọọlẹ gan an pẹlu igbesẹ ijọba lati ka aṣa naa nilẹ.
Igba ọtun

Oríṣun àwòrán, Sakhi Trust
Owo ti Chandrika n ri nibi iṣẹ aṣẹwo to n ṣe ko jẹ ko mọ oṣi.
O si fi awọn ọmo rẹ sile ẹkọ onileegbe kawọn eeyan ma baa le maa fi wọn ṣe yẹyẹ.
''Ominu maa n kọ mi lori ọmóbinrin mi.
Mo ṣe igbayawo fun un pẹlu ibatan mi kan nigba ti o pe ọmọ ọdun mẹrinfinlogun ki ọrọ rẹ ma ba da bi ti temi.
Mo ti n dagba, mi o ni le maa ṣiṣẹ aṣẹwo yii lọ titi lai,'' Chandrika lo sọ bẹẹ.
O ni oun ti gbero lati maa ta eso ati ẹfọ.
Shilpa ni tiẹ fẹ fun ọmọbinrin rẹ ni ẹkọ to ye kororo, tori o korira aṣa devadasi.
Ankita ni oun fẹ ṣe igbeyawo pẹlu ololufẹ oun ki oun si yọ ẹgba ọrun to ṣe edidi igbeyawo rẹ pẹlu oriṣa.
( *Orukọ mii ni a lo lati daabo bo Chandrika)











