Ṣé lóòótọ́ ni wọ́n ń pa àwọn Kristẹni lọ́gọ̀ọ̀rọ̀ ní Nàìjíríà bí Trump ṣe fẹ̀sùn kàn?

Àwòrán ààrẹ Donald Trump tó wọ aṣọ dúdú

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Olaronke Alo
    • Role, BBC Global Disinformation Unit
    • Author, Chiamaka Enendu
    • Role, BBC Global Disinformation Unit
    • Author, Ijeoma Ndukwe
    • Reporting from, Lagos
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump ti dúnkokò láti kó ọmọ ogún wọ Nàìjíríà tí bí wọ́n ṣe ń pa àwọn ẹlẹ́sìn Kristẹni kò bá wá sópin.

Láti bíi oṣù díẹ̀ sẹ́yìn ni àwọn olóṣèlú kan ní Washington ti ń fẹ̀sùn kàn pé àwọn alákatakítí ẹ̀sìn Islam ń mọ̀ọ́mọ̀ kojú oro sáwọn Kristẹni ní Nàìjíríà.

Ṣùgbọ́n BBC ti ṣàwárí rẹ̀ pé àwọn nǹkan tí wọ́n ń rí láti fi pinnu yìí ṣòro láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn Kristẹni nìkan láwọn agbéṣùmọ̀mí náà ń dojú kọ.

Ní oṣù Kẹsàn-án, gbajúmọ̀ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ àti aláwàdà, Bill Maher parí gbogbo ẹ pẹ̀lú bó ṣe júwe ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà bíi ìgbìyànjú láti pa àwọn Kristẹni run.

Ó sọ pé ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí Boko Haram ti pa àwọn Kristẹni tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún láti ọdún 2009 sí àsìkò yìí, tí wọ́n sì tún ti sun ṣọ́ọ̀ṣì ti iye rẹ̀ jẹ́ 18,000.

Èyí ti ń fa onírúurú àríwísí lórí ayélujára.

Ìjọba Nàìjíríà ti fèsì pé àwọn ìròyìn jẹ́ ohun tó yàtọ̀ sí nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà àmọ́ wọn kò jiyàn pé ìkọlù aṣekúpani ń wáyé ní Nàìjíríà.

Àwọn aláṣẹ sọ pé àwọn agbéṣùmọ̀mí ń ṣekúpa gbogbo àwọn èèyàn yálà ẹlẹ́sìn Kristẹni, Mùsùlùmí àtàwọn ẹlẹ́sìn míì.

Àwọn àjọ míì tí wọ́n ń máa ń ṣe ìwádìí lórí láàsìgbò tó máa ń wáyé lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú sọ pé àwọn Kristẹni tí wọ́n ti pa kéré jọjọ bó ṣe jẹ́ pé àwọn Mùsùlùmí ni àwọn alákatakítí ẹ̀sìn náà ń dojúkọ jùlọ.

Onímọ̀ nípa ètò ààbò, Christian Ani sọ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìkọlù tí wáyé sáwọn Kristẹni, ó ní kò tọ̀nà láti sọ pé àwọn Kristẹni ni àwọn agbéṣùmọ̀mí ń mọ̀ọ́mọ̀ dojúkọ.

Bẹ́ẹ̀ náà ni Nàìjíríà ń kojú onírúurú ìpèníjà ààbò káàkiri gbogbo ẹkùn rẹ̀, yàtọ̀ sí àwọn alákatakítí ẹ̀sìn, tí kò sì yẹ láti ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn yẹn náà.

Ẹ̀sìn Islam àti Kristẹni ni ẹ̀sìn méjì tó gbilẹ̀ jùlọ ní Nàìjíríà, àwọn mùsùlùmí lò sì pọ̀ jùló ní ẹkùn àríwá Nàìjíríà níbi tí ọ̀pọ̀ ìkọlù náà ti ń wáyé.

Kí ni àwọn olóṣèlú Amẹ́ríkà ń sọ?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Sẹ́nétọ̀ Texas, Ted Cruz ti ń polongo èyí fún ìgbà pípẹ́ díẹ̀, tí òun náà sì ń polongo pé iye àwọn Kristẹni tí Maher fẹ̀sùn kàn pé wọ́n ti pa ni òun náà ń sọ.

Ní ọjọ́ Keje, oṣù Kẹwàá, ó kọ sójú òpó X rẹ̀ pé "láti 2009, àwọn Kristẹni tó lé ní 50,000 ni wọ́n ti pa lọ́nà àìtọ́ ní Nàìjíríà, jó ṣọ́ọ̀ṣì tó lé ní 18,000 àtàwọn ilé ẹ̀kọ́ 2,000 tó jẹ́ tí àwọn Kristẹni ni wọ́n ti bàjẹ́.

Nínú àkọránṣẹ́ kan sí BBC, Sẹ́nétọ̀ náà ní òun kò pe ìpànìyàn náà ní ìpanirun bíkòṣe ìpànìyàn lọ́nà àìtọ́.

Àmọ́ Cruz fẹ̀sùn kan ìjọba Nàìjíríà pé wọ́n ń kọtí ọ̀gbọ̀in sí báwọn alákatakítí ẹ̀sìn ṣe ń pa àwọn Kristẹni.

Ìjọba Nàìjíríà ti jiyà èyí, bí wọ́n ṣe sọ pé àwọn ń wá gbogbo ọ̀nà láti kojú àwọn alákakítí ẹ̀sìn yìí. Àwọn aláṣẹ kan sọ pé àwọn yóò tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Amẹ́ríkà láti kojú àwọn agbẹṣùmọ̀mí náà.

Àwọn aláṣẹ ti ń gbìyànjú láti kojú ìkọlù àwọn alákakítí ẹ̀sìn àtàwọn ọ̀daràn – onírúurú ìkọlù ló máa ń wáyé ní gbogbo ọ̀sẹ̀.

Boko Haram, tó gbajúmọ̀ fún jíjí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Chibok gbé ní nǹkan bíi ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn – ti ń ṣọṣẹ́ láti ọdún 2009 ṣùgbọ́n ẹkùn ìlà oòrùn àríwá Nàìjíríà, tí àwọn mùsùlùmí pọ̀ sí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkọlù wọn ti ń wáyé.

Àwọn ikọ̀ alákatakítí ẹ̀sìn míì tún ti ń ṣọṣẹ́ ní Nàìjíríà tó fi mọ́ ikọ̀ Islamic State West Africa Province, ISWAP tó sì jẹ́ pé ẹkùn ìlà oòrùn àríwá Nàìjíríà ni àwọn náà wà.

Iye Kristẹni tí Amẹ́ríkà ló ti jáde láyé pọ̀ púpọ̀ àmọ́ ó ṣòro láti fìdí wọn múlẹ̀.

Níbo láwọn nọ́mbà náà ti ń wá?

Nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àkọ́ọ́lẹ̀, níbi ètò kan nínú oṣù September ni Cruz ti sọ pé ìjábọ̀ àjọ International Society for Civil Liberties and Rule of Law, InterSociety tọ́dún 2023 ni òun ti mọ̀ nípa àwọn Kristẹni tí wan ti pa ní Nàìjíríà.

Ọ́fíìsì rẹ̀ náà fi àwọn ìròyìn kan ṣọwọ́ sí BBC èyí tó jẹ́ pé InterSociety, tó jẹ́ àjọ tí kìí ṣe ti ìjọba ni gbogbo wọn náà ń tẹ̀lé.

Maher kò fèsì sí BBC lórí ìbéèrè pé níbo ló ti rí àwọn nọ́mbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ṣùgbọ́n ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé ìjábọ̀ InterSociety ni òun náà tẹ̀lé.

Fún àkọ́ọ́lẹ̀ tó lè máa ṣe atọ́nà Amẹ́ríkà lórí Nàìjíríà, àwọn iṣẹ́ InterSociety kò ṣe é gbáralé.

Nínú ìjábọ̀ InterSociety tí wọ́n gbé jáde nínú oṣù Kẹjọ èyí tó jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn iṣẹ́ ìwádìí tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn, wọ́n ní àwọn Kristẹni tó lé ní 100,000 ni wọ́n ti jáde láyé látọwọ́ àwọn alákatakítí ẹ̀sìn Islam láti ọdún 2009.

Wọ́n ní àwọn mùsùlùmí 60,000 ló jáde láyé látọwọ́ àwọn alákatakítí ẹ̀sìn lásìkò yìí kan náà.

InterSociety kò sọ bí wọ́n ṣe rí àkọ́ọ́lẹ̀ náà lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan èyí tó jẹ́ kó ṣòro láti ṣe àgbéyẹ̀wò àkọ́ọ́lẹ̀ ikú náà.

Nígbà tí wọ́n ń fèsì, àjọ náà ní ó máa ṣòro fún àwọn láti ṣe àkójọ gbogbo àwọn àkọ́ọ́lẹ̀ tí wọ́n ti ṣe láti ọdún 2010.

Obìnrin tó wọ aṣọ pupa tó dorí kọlẹ̀

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọ̀pọ̀ àwọn tí Boko Haram ṣe ìkọlù sí ló jẹ́ Mùsùlùmí

Àwọn tí wọ́n ti pa lọ́dún 2025

InterSociety gbà pé àwọn Kristẹni 7,000 ni wọ́n ti pa láàárín oṣù Kìíní sí oṣù Kẹjọ ọdún yìí. Èyí ni ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń pín kiri lórí ayélujára tó fi mọ́ aṣòfin Amẹ́ríkà, Riley M Moore, ẹni tó ń léwájú ìjíròrò yìí ní ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin Amẹ́ríkà.

Bákan náà ló ṣe àkọ́ọ́lẹ̀ àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn àádọ́rin gẹ́gẹ́ bí orísun ìròyìn rẹ̀ láti mọ̀ nípa ìpànìyàn àwọn Kristẹni lọ́dún 2025. Àmọ́ ìdajì nínú ọ̀pọ̀ àwọn ìròyìn náà ni kò sọ ẹ̀sìn àwọn èèyàn náà ní pàtó.

Bí àpẹẹrẹ, InterSociety dárúkọ ìròyìn Al Jazeera kan lórí ìkọlù táwọn agbébọn ti ṣèkọlù sáwọn àgbẹ̀ ní Damboa ní Borno tí àgbẹ̀ ogójì ti pàdánù ẹ̀mí wọn ṣùgbọ́n ìròyìn Al Jazeera kò sọ pé Kristẹni ni wọ́n gẹ́gẹ́ bí InterSociety ṣe gbé jáde.

InterSociety sọ fún BBC pé àwọn ṣe ìwádìí síwájú láti mọ̀ nípa àwọn èèyàn náà ṣùgbọ́n wọn kò sọ bí wọ́n ṣe ń ṣe èyí.

BBC ṣe àkójọ iye èèyàn tó tik ú nínú gbogbo àwọn ìròyìn tó jáde náà tí àpapọ̀ wọn sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ta dípò ẹgbẹ̀rún méje tí InterSociety pè é.

InterSociety sọ pé àwọn kó àwọn àwọn rò pé ọ ṣeéṣe kí wọ́n ti kú sí àhámọ́ àtàwọn nǹkan táwọn èèyàn tí ìkọlù náà ń ṣojú wọ só fún àwọn si ni.

Ta ló wà nídìí àwọn ìpànìyàn yìí?

Lára àwọn tí wọ́n ló ń ṣokùnfà ikú náà ni Boko Haram àtàwọn Fulani darandaran. Ẹ̀yà tí ọ̀pọ̀ wọn jẹ́ mùsùlùmí ni Fulani tí wọ́n tàn káàkiri gbogbo ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Africa, tó sì jẹ́ pé iṣẹ́ darandaran ni wọ́n ń ṣe jẹun.

Ṣíṣe àfikún àwọn Fulani darandaran sára àwọn tí InterSociety ń pè ní alákatakítí ẹ̀sìn nínú ìjábọ̀ wọn jẹ́ ohun tó wà lára nǹkan tó ń fa awuyewuye ní Nàìjíríà pàápàá lórí ìsọ̀rí tí wọ́n máa pín àwọn ìpànìyàn náà sí.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn darandaran yìí ló jẹ́ Mùsùlùmí, ọ̀pọ̀ àwọn olùwádìí ni kò gbà pé ìkọlù wón ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú ẹ̀sìn.

Wọ́n gbà pé ìkọlù wọn ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ilẹ̀ àti omi.

Àwọn Fulani darandaran ti ní ìfaǹfà pẹ̀lú àwọn Mùsùlùmí àti Kristẹni káàkiri Nàìjíríà.

Ani sọ pé láti pé àwọn darandaran ní alákatakítí ẹ̀sìn jẹ́ ohun tó gùn gan. "Kò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú rẹ̀ rárá."

Confidence McHarry, tí iléeṣẹ́ SBM sọ pé ọ̀rọ̀ ohun àlùmọ́nì àti ìjà ẹlẹ́yàmẹ̀yà ni àwọn èèyàn náà sábà máa ń jà sí.

InterSociety tún dárúkọ àwọn tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí gẹ́gẹ́ bí agbébọn pé ọ̀pọ̀ wọn ló jẹ́ Fulani ní ẹkùn ìwọ̀ oòrùn àríwá Nàìjíríà tó jẹ́ pé ìjínigbé ni wọ́n sábà máa ń ṣe, tó sì jẹ́ pé àti Mùsùlùmí pẹ̀lú Kristéni ni wọ́n máa ń ṣe ìkọlù sí.

Àwòrán àwọn àkọ́lé lójú àwọn ìwé ìròyìn Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àwọn wo ló ti ń polongo èyí?

Àwọn olóṣèlú Amẹ́ríkà àtàwọn Kristéni míì lágbàáyé ti ń sọ̀rọ̀ lórí ìdúnkokò tó ń kojú àwọn Kristẹni ní Nàìjíríà ti pẹ́.

Ní àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn ni ẹgbẹ́ Indigenous People of Biafra (Ipob) tẹ̀ka Amẹ́ríkà ti kọ́kọ́ ń kọminú lórí ẹ̀sùn yìí.

Iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà sọ pé InterSociety ní àjọṣepọ̀ ṣe pẹ̀lú Ipob àmọ́ wọ́n jiyàn ẹ̀sùn náà.

Ikọ̀ Biafra míì ni wan tún fẹ̀sùn kàn pé òun náà lọ́wọ́ nípa pípolongo pípa àwọn Kristẹni lọ́nà àìtọ́ fáwọn ilé aṣòfin Amẹ́ríkà.

Ẹgbẹ́ Biafra Republic Government in Exile, BRGIE, júwe pípa àwọn Kristẹni bí ohun tí wọ́n ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣe, tí wọ́n sì ní àwọn ti ń bá ọ̀pọ̀ àwọn iléeṣẹ́ ní Amẹ́ríkà jíròrò, tó fi mọ́ Cruz àmọ́ àṣòfin náà jiyàn èyí.

Kí ni ìwádìí àwọn àjọ míì ń sọ?

Àwọn àkọ́ọ́lẹ̀ àjọ míì ló kéré jọjọ sí ti InterSociety lórí ìpanìyàn àwọn Kristẹni ní Nàìjíríà.

Acled tí òun náà jẹ́ àjọ tó máa ń mójútó àwọn ìwà ipá tó ń wáyé ní ìwọ̀ oòrùn Africa náà ti ṣe àgbékalẹ̀ àwọn àkọ́ọ́lẹ̀ tó yàtọ̀ sí ti InterSociety. Àwọn àkọ́ọ́lẹ̀ tó wà lójú òpó wón jẹ́ èyí tó ṣe é wádìí.

Ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀, Ladd Stewart sọ fún BBC pé ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé gbogbo àwọn tó ti bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìwà ìpànìyàn lọ lórí ètì òṣèlú ni àkọ́ọ́lẹ̀ 100,000 tó gba orí ayélujára.

Ó ní kìí ṣe òótọ́ ni láti sọ pé àwọn Kristẹni tí wọ́n ti pa láti ọdún 2009 ni àwọn èèyàn náà.

Acled ṣàwárí rẹ̀ pé àwọn èèyàn, mùsùlùmí àti Kristẹni ti iye wọn dín ní 53,000 ni wọ́n ti jáde láyé lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú láàárín ọdún 2009 sí àsìkò yìí.

Àwọn àkọ́ọ́lẹ̀ Trump

Nínú àtẹ̀jáde kan tí Trump fi sórí sójú òpó Truth Social lọ́jọ́ Ẹtì sọ pé àwọn Kristẹni 3,100 ni wọ́n ti pa. Ìjábọ̀ Open Doors fún iye àwọn Kristẹni tó jáde láyé nínú oṣù Kẹwàá 2023 ni Trump ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

Open Doors jẹ́ àjọ tó máa ń ṣe ìwádìí lórí ikú àwọn Kristẹni káàkiri àgbáyé.

Ìjábọ̀ ní àwọn Kristẹni 3,100 ni wọ́n pa láàárín ọdún kan táwọn mùsùlùmí sì jẹ́ 2,320.

Open Doors ṣe àfíkun àwọn ikọ̀ tí wọ́n pè ní Fulani Terroe Groups sínú àkọ́ọ́lẹ̀ àwọn tó ṣe ìkọlù náà.

Frans Veerman tó jẹ́ àgbà olùwádìí sọ pé ohun tó fojú hàn ni pé wọ́n ń ṣe ìkọlù sáwọn Kristẹni àti pé aọn mùsùlùmí náà kò móríbọ́ nínú ìkọlù bákan náà.

Àwọn olùyànnànà ọ̀rọ̀ gbà pé ìkọlù sáwọn mùsùlúmí àti mọ́ṣáláṣí pọ̀ ní ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà.