Zohan Mamdani mùsùlùmí àkọ́kọ́ tí yóò jẹ alákòóso ìjọba New York sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Donald Trump

Oríṣun àwòrán, ANGELA WEISS/AFP via Getty Images
Zohan Mamdani, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan gẹgẹ bi alakooso ijọba ilu New York lorilẹede Amẹrika bayii ti sọko ọrọ si Aarẹ Donald Trump.
Nigba to n sọrọ lẹyin to jawe olubori ninu eto idibo to gbe e wọle ni Mamdani gba Trump ni gbolohun pe ko tẹti bẹlẹjẹ lati gbọ winrin-winrin lẹnu oun.
Mamdani ni alakooso ilu New York to kere julọ bayii ninu itan ilu naa.
Alakooso tuntun ilu New York naa sọ ninu fidio kan wi pe ọrọ mẹrin pere loun ni lati sọ fun aarẹ Amẹrika.
Mamdani to wọle ibo alakooso ilu New labẹ asia ẹgbẹ oṣelu alatako Democratic Party sọ pe ''Donald Trump, mo mọ pe o n wo mi bayii, ọrọ mẹrin ni mo ni fun ọ.
Ti ẹnikẹni ba fẹ ṣafihan orilẹede ti Trump ti ja kulẹ, tabi ọna lati ri pe Trump fidirẹmi, ilu yii ni.
Ti ọna kan ba wa lati dẹru ba olori abaṣẹ-waa to n lo agbara lori awọn eeyan lọna aitọ, nipa didena bi o ti de ipo agbara ni ọna naa.
Bi a ti le da Trump duro niyi, ati ẹlomiran to ba tun fẹ ṣe bii Trump.''
Ti ẹ o ba gbagbe, Trump ti leri ṣaaju wi pe oun yoo mu adinku ba owo to n lọ sapo ijọba ilu New York ti Mamdani ba fi le wọle ibo alakooso ilu naa.
Tani Zohan Mamdani, ẹni ọdún 34 tó di alákóso ìjọba ìlúu New York?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Zohan Mamdani, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn ni wọn ṣẹṣẹ dibo yan gẹgẹbi alakoso ijọba ilu New York lorilẹede Amẹrika bayii.
Ki o to di wi pe o bori idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu Democratic Party fun idibo si ijoko alakoso ijọba agbegbe naa,iwọnba perete eniyan lo da a mọ, ọpọ lo n foju wo o bayii gẹgẹbi ọkan lara awọn irawọ tuntun to n sẹyọ gẹgẹbi omi oṣelu tuntun to n ru lorilẹede naa, bi o tilẹ jẹ wi pe awọn miran, ninu eyi ti aarẹ orilẹede naa, Donald Trump wa n rii gẹgẹbii awọn oloṣelu afẹ-ajẹ-maa-fẹ-a-yo.
Ni ilu Kampala,lorilẹede Uganda ni wọn ti bi Mamdani ki o to lọ si ilu New York pẹlu ẹbi rẹ nigba to jẹ ọmọ ọdun meje. Ile ẹkọ giga Bronx High School of Science lo ti kẹkọ girama ki o to tẹsiwaju lọ kẹkọgboye imọ ijinlẹ ninu imọ nipa ilẹ Afirika ni ilẹẹkọ giga Bowdoin College, nibi to ti wa lara awọn to da ẹgbẹ awọn akẹkọọ to n ja fun idajọ ododo fawọn eeyan Palestine Students for Justice in Palestine, silẹ.
Mamdani ni musulumi akọkọ ati ọmọ ilẹ Gusu Asia ti yoo jẹ alakoso ijọba ilu New York.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lara awọn ileri to ṣe fawọn araalu ni eto ileegbe ti ko ga jara lọ, bọọsi irinna ọfẹ, eto iyalegbe to se araalu loore ati eto igbayegbadun fawọn ọmọde ti ọjọ ori wọn ko tii ju ọdun marun un lọ.
Mamdani ṣalaye ninu ọrọ to ba BBC News sọ pe, "Eeyan kan ninu mẹrin to n gbe inu ilu yii lo jẹ wi pe inu oṣi ati iṣẹ ni wọn wa, ilu nla to jẹ wi pe ẹẹdẹgbẹta ẹgbẹrun ọmọde ni wọn n sun lairi ounjẹ jẹ".
"Bakan naa lo jẹ wi pe ewu pipadanu nnkan to mu ki ilu yii ṣe pataki loju araye."
Mamdani ni New York yoo yipada si "imọlẹ" laarin okunkun
Ninu ọrọ to sọ lẹyin ti wọn kede rẹ gẹgẹbi olubori ibo alakoso ilu New York, Mamdani sọrọ lori awọn ileri to ṣe lasiko ipolongo ibo ati ọna ti yoo gba mu ileri rẹ ṣẹ nipataki julọ fun awọn ẹgbẹjẹgbẹ to tii lẹyin lati de ipo.
Ko ṣai tẹsiwaju nipa ọrọ rẹ to da lori ireti, nigba to n ba awọn ọgọrọ ero sọrọ pe "lasiko yii ti okunkun ṣu bolẹ lori eto oṣelu, New York yoo jẹ imọlẹ."
Bakan naa lo tun fi ohun ranṣẹ si Aarẹ Donald Trump pe, ilu "to gbe e dide" le ṣokunfa ijakulẹ rẹ pẹlu.














