Àwọn ọ̀dọ́ lu Ìmáàmù àgbà kan pa ní Kwara; Ohun tí a mọ̀ nípa rẹ̀ rèé

Awọn ọdọ kan n ṣe iwọde.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn ọdọ kan ni agbegbe Sokupkpan, ni ijọba ibilẹ Edu nipinlẹ Kwara ni wọn yalu imaamu agba agbe naa, ti wọn pe orukọ rẹ ni Abdulahi Audu, ti wọn si lu pa, lori ẹsun pe o lọwọ ninu iku ọdọmọkunrin kan to n gbe ni agbegbe naa, ti orukọ rẹ n jẹ Ibrahim Gana.

Ohun ta ri gbọ ni pe Gana fẹsun kan Imaamu agba naa pe o lọwọ ninu aisan to n se, eyi to pada gba ẹmi rẹ, ko to di pe o jaye laye.

Gana ni wọn ni o sọ fun awọn eeyan pe ọpọ igba ni oun n ri imaamu agba naa loju ala to n kọlu oun.

Ọjọ karun un, oṣu kọkanla ọdun 2025 ni awọn ọdọ to n binu kọlu imaamu agba naa, ti ọrọ naa di wahala ni agbegbe naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, ti wọn si ni awọn ẹgbọn oloogbe Gana, Mohammed Shaba ati Mahmud Gana lo lọ fẹsan kan Imaamu agba naa lẹyin iku aburo wọn, o lọwọ ninu iku rẹ.

Aworan Kọminsana ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, CP Adekimi Ojo, psc, mnips

Oríṣun àwòrán, Kwara Police

Muhammad Shaaba ati Mahmud Gana ni wọn ko ero lẹyin pẹlu ọpọ ohun ija lọ kọlu Imaamu agba, to si gba ibẹ jade laye.

"Ni Ọjọ kẹrin, ọdun 2025, ni deede ago mẹsan an abọ, Ibrahim Gana, ẹni ọdun mẹdọgbọn, olugbe Sokunkpan ni Tsaragi, ẹni to ti n se aisan fun ọjọ pipẹ.

"Lẹyin iku rẹ, awọn ẹgbọn rẹ meji, Mohammed Shaba ati Mahmud Gana fẹsun kan Imaamu agba ilu naa, Alh Abdullahi Audu, pe o lọwọ ninu iku aburo wọn.

"Rogbodiyan bẹ silẹ, Muhammad Shaaba ati Mahmud Gana ni wọn ko ere lẹyin lọ kọlu Imaamu agba pẹlu awọn ija, to si ja si iku fun Imaamu naa."

Awọn to kọlu imaamu naa ni wọn lu titi ẹmi fi pin ni lẹyin ti ọpọ agba ilu gbiyanju lati da si ọrọ naa.

Iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe wọn ti sin Imaamu agba, Abdulahi Audi, no wọn ti sin ni ilana ẹsin Islam ni irọlẹ ọjọru, pẹlu omije loju ọpọ araalu.

Ọwọ ti tẹ afurasi mẹrin lori iṣẹlẹ yii, ti ileeṣẹ ọlọpaa si ti bẹrẹ iwadii ati igbiyanju lati mu awọn afurasi yooku.

‎Kọmisana fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, CP Adekimi Ojo, psc, mnips, koroju siṣe idajọ lọwọ ara ẹni, to si jẹ ko di mimọ pe irufẹ eyi lodi si ofin orilẹede Naijiria.

O rọ araalu lati ma kan si ileeṣẹ ọlọpaa to ba wa ni itosi wọn fun awọn irufẹ iṣẹlẹ bayii.