Apàṣẹ-wàá, amọtara ẹni nìkan lásán ni Trump - Soyinka

Oríṣun àwòrán, ANDREW HARNIK VIA GETTY IMAGES AND IFIOKABASI ETTANG/BBC
Lẹyin iṣẹlẹ fifi ofin de agba ọnkọwe nni, Ọjọgbọn Wole Soyinka, lati ma le lọ si America , baba naa ti fi Aarẹ America, Donald Trump, we ẹni to n mọ ti ara rẹ nikan to si wulẹ fẹran ko maa paṣẹ waa le awọn eeyan lori lasan.
Soyinka, ẹni ọdun mọkanlelaadọrun-un (91), sọ fun BBC pe iṣesi Trump n mu oun ranti aarẹ apaṣẹwaa ilẹ Uganda nigba kan, Idi Amin.
Ẹ o ranti pe ṣaaju ni Ọjọgbọn Soyinka ti kede pe ilẹ America ni koun wa tun iforukọsilẹ ṣe boun ba ṣi fẹ wọ ilu naa.
Ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu BBC, agba onkọwe yii sọ pe oun ti kilọ tẹlẹ, pe bi Trump ba fi le di aarẹ America, ẹni ti yoo fi jofin ni yoo maa wa kiri.
"Bo tilẹ jẹ pe mo kilọ naa, awọn eeyan ko gba a gbọ. Emi o fẹran ki eeyan le mi jade o, maa yaa jade funra mi ni, iyẹn ṣi buyi kun eeyan."
"Ki lo de, nitori mo sọ pe olooraye apaṣẹ waa ni, ni wọn ṣe fẹ ṣe tiwọn pada fun mi. Ẹyin naa ṣaa ri i bo ṣe n ṣe si awọn ti ko fẹran rẹ lẹyin to gbajọba."
Ọjọgbọn Wole Soyinka lo sọ bẹẹ.
Mo fa ìwé tí mo lè fi gbé l'America ya nígbà tí Trump kọ́kọ́ di ààrẹ
Ni itẹsiwaju alaye rẹ fun BBC, Ọjọgbọn Soyinka sọ pe:
"Mo fa iwe igbeluu mi ya nigba ti aarẹ yii kọkọ di aarẹ ni.
"Ki lo de ti mo fi ṣe bẹẹ? Nitori mo gbọ lasiko to n polongo ibo, mo si ri ọrọ to n jade lẹnu ẹlẹyamẹya ti mi o ri iru rẹ ri laye mi ninu ipolongo ibo l'America."
Ọjọgbọn Soyinka sọ pe lasiko Trump di aarẹ ni a bẹrẹ si i ri idakeji America.
O ni lasiko rẹ ni ipaniyan pọ, ti wọn n pa awọn ẹya to kere niye ati awọn alawọ dudu.
O ni oun ri i bi Obama ṣe polongo ibo lasiko to fẹ di aarẹ, oun si ri ọna òdì ti Trump gbe tiẹ gba.
"Mo ti sọ ọ tẹlẹ, pe ti ọkunrin yẹn ba wọle ibo, ohun to maa kọkọ ṣe ni ko fagile iwe igbeluu awọn eeyan, ko si sọ fun wọn pe ki wọn lọ tun iforukọsilẹ ṣe.
"Mo ni emi o ni i duro de igba yẹn tabi ifọrọwanilẹnu wo kankan, nibi ti wọn yoo ti sọ fun mi pe wọn ti fagile iwe igbeluu mi."
Agba onkọwe naa lo ṣalaye bẹẹ.














