Kí ni ìtumọ̀ ìpanirun tí Trump lò fún ẹ̀sùn pípa àwọn Kristẹni ní Naijiria?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nigba ti Aarẹ orilẹede America, Donald Trump, n ṣapejuwe ipaniyan to ni o n waye laaarin awon Kristẹni nikan ni Naijiria, o lo ede oyinbo kan to pe ni 'Genocide.'
Bo ti lo ọrọ naa lo ni oun ti paṣẹ fun awọn ologun America lati waa koju awọn alakatakiti ẹlẹsin Islam to n pa Kristẹni labẹ Jihad ti wọn gbe lọwọ.
Bẹẹ lo ni ijọba apapọ Naijiria lo kuna ninu ojuṣe rẹ to fi di pe Kristẹni nikan lo di ẹran amupa ti awọn apaayan n pa lorilẹede Naijiria.
Bo tilẹ jẹ pe Trump ko sọ pato iru ipaniyan to n mẹnuba, o ni iroyin nipa bi wọn ṣe n pa awọn Kristẹni nikan n gbilẹ si i lorilẹede Naijiria lẹnu ọjọ mẹta yii, o si n de etigbọọ America.
Eyi ni awọn ajọ to n mojuto jagidijagan ti tako pe ko ri bẹẹ, wọn ni ko si aridaju pe Kristẹni ni wọn n pa ju Musulumi lọ.
Ijọba apapọ Naijiria naa si ti tako Trump pe ko ri bẹẹ, wọn ni gbogbo ẹya ati ẹsin lo jọ n ṣe pọ ni Naijiria, ṣugbọn Aarẹ America naa yari kanlẹ.
Loootọ ni ipaniyan n waye ni Naijiria, paapaa lawọn apa Ariwa-Ila-Oorun, nibi ti awọn Boko Haram ati ISWAP ti n ṣoro.
Bakan naa ni wọn n pa eeyan bii ẹni pa ẹran ni Plataeu ati Benue, eyi to ni i ṣe pẹlu awọn agbẹ ati awọn darandaran.
Ṣugbọn ṣe iku awọn eeyan yii to ohun ti eeyan le pe ni ipanirun tabi jijẹ ilu run bi Trump ṣe n kede rẹ nipa Naijiria yii?
Ki gan-an ni Genocide ati itumọ rẹ gan-an bi Trump ṣe n pokiki rẹ nipa Naijiria?
Ìtumọ̀ 'Genocide'
Ọrọ ti oyinbo n pe ni genocide yii waye lati ọwọ ọmọ ilẹ Jew ati Poland kan ni 1943, iyẹn Raphael Lemkin, agbẹjọro ni.
Raphael Lemkin lo pa ede Greek ti i ṣe "genos" to tumọ si ìran tabi ẹya, pọ mọ 'cide', ọrọ Latin to tumọ si ki eeyan pa nnkan. (genos-race or tribe), (cide- to kill).
Lẹyin to koju ipaniyan to pa ọpọlọpọ awọn Jew lasiko ogun agbaye keji, ti wọn pa gbogbo ẹbi rẹ, afi aburo rẹ kan ṣosọ to ṣẹku, ni Ọmọwe Lemkin bẹrẹ ipolongo lori genocide.
O gbe igbesẹ pe ko di ohun ti wọn yoo fi ọwọ si gẹgẹ bii iwa ọdaran ninu iwe ofin agbaye.
Igbiyanju Lemkin lo jẹ ki ajọ Iṣọkan Agbaye pade loṣu Kejila ọdun 1948.
Loṣu Kin-in-ni ọdun 1951, o di itẹwọgba, nigba ti yoo si fi di 2022, orilẹede 153 lo ti gba genocide wọle bii iwa ọdaran labẹ ofin wọn.
Abala keji ninu iwe ofin ipade naa, ka genocide si eyikeyi ninu awọn iwa to jẹ mọ ipanirun, boya pipa diẹ abi patapata si orilẹede, ẹ̀yà, ẹsin tabi ẹgbẹ:
• Pipa ọmọ ẹgbẹ naa.
• Ṣiṣe wọn ni ijamba lara tabi kiko ironu ba wọn.
• Ki eeyan mọ-ọn-mọ ko ẹgbẹ kan sinu iyọnu tabi idaamu to foju han.
• Ki eeyan gbe igbesẹ ti ko ni i jẹ ki awọn ọmọ ẹgbẹ naa pọ si i nipa ọmọ bibi.
• Fifi ipa ko awọn ọmọ ẹgbẹ naa lọ sinu ẹgbẹ miran.
Ipade ajọ Iṣọkan Agbaye naa gbe iṣẹ le awọn orilẹede to tẹwọ gba a lọwọ, pe ki wọn maa dena genocide, ipanirun. Ki wọn si maa fiya jẹ ẹni to ba ṣe e.
Ta ló lè sọ bóyá genocide rèé tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
Gẹgẹ bi Ajọ Iṣọkan Agbaye ṣe wi, awọn ko le sọ boya genocide, ipanirun lo n ṣẹlẹ nibi kan, lasiko kan.
Wọn ni ẹka idajọ to laṣẹ rẹ lo le sọ ọ.
Awọn bii kootu agbaye ni wọn lo ni aṣẹ ati sọ pe ipanirun lo n ṣẹlẹ nibi kan lasiko kan.
Koda, labẹ ofin agbaye, awọn ẹjọ ti wọn ka si ipanirun yii ṣe e ka, ko pọ:
Ipanirun to waye ni Rwanda ni 1994.
Genocide ọdun 1995 to waye ni Srebrenica, ti wọn pa ọpọ eeyan ni Bosnia, ati ti ipolongo Khmer Rouge ti wọn ṣe tako awọn ẹgbẹ ti ko to nnkan ni Cambodia lati 1975 titi di 1979.
Bi wọn yoo ba dajọ lori ipaniyan-panirun yii, awọn ile ẹjọ bii ICJ ati International Criminal Court (ICC) ni wọn gbajumọ ju ninu sisọ pe genocide waye nibi kan.
Bakan naa ni Ajọ Iṣọkan Agbaye tun gbe igbimọ kan dide lati yanju ipanirun to waye ni Rwanda ati Yugoslavia ti tẹlẹ nigba naa.
Nipa awọn ẹjọ genocide to wa lori atẹ agbaye bayii, lara wọn ni eyi ti Ukraine pe tako Russia ni 2022.
Omiran ni ti Gambia ni 2017, ti wọn fi tako Myanmar.
Wọn ni ilu to kun fun awọn ẹlẹsin Buddhism yii pa awọn Musulumi Rohingya ti wọn ko to nnkan niluu naa.
Wọn ni niṣe wọn fẹ fi ọgbọn jẹ gbogbo abule awọn run.
Ọdun 2002 ni wọn gbe ile ẹjọ ICC kalẹ labẹ ofin Rome. Orilẹede 125 to ti gba a wọle ni wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ— America, China ati India ni ko si lara wọn.
Ile ẹjọ ICC naa ti n jẹjọ bọ lori ipanirun ọjọ pe, ṣugbọn Omar Hassan Ahmad Al Bashir, aarẹ Sudan ti wọn gbajọba lọwọ rẹ ni 2019 to si ti sa lọ bayii ni wọn doju kọ ju.
Ọkunrin naa fẹre lo to ọgbọn ọdun lori aleefa.
Ṣé àbàwọ́n kankan wà nínú gbígba òfin genocide wọlé?
Latigba to ti di ofin, ọpọ igba ni awọn awoye ti naka aleebu kan tabi ikeji si adehun Ajọ Iṣọkan Agbaye, paapaa awon ti ki i ri ofin naa lo nibi ti wọn ba ro pe ipanirun lo waye.
Abawọn rẹ si awọn kan ni pe ko kun to, awọn mi-in si ni agbara rẹ ti dinku.
"O ṣoro gan-an lati ri ofin genocide mulo"
Onimọ nipa ofin naa, Thijs Bouwknegt, to ti ṣiṣẹ pẹlu ICC lo sọ bẹẹ ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu AFP.
"O gbọdọ fi han pe awọn ti o n fẹsun kan mọ-ọn-mọ ṣe e nnkan naa ni, ati pe ko si idi miran ti eeyan tun le fi mulẹ ju pe wọn mọ-ọn-mọ ṣe e ni."
Aleebu miran ti won tun tọka si i ni pe awọn ẹgbẹ oṣelu kan ti di aṣemalu, ti ofin naa ko mu wọn.
Bakan naa ni ko dẹrun lati mọ onka iku ti yoo ṣẹlẹ ka too sọ pe genocide lo waye.
Ọgbẹni Bouwknegt sọ pe o le gba ọpọlọpọ ọdun ki kootu kan too sọ pe ipanirun lo ṣẹlẹ nibi kan.
Ni ti Rwanda, o fẹrẹ to ọdun mẹwaa ki Ajọ UN too gba pe genocide lo ṣẹlẹ nibẹ loootọ.
1995 ni ipaniyan rẹpẹtẹ ti waye ni Srebrenica, ti musulumi to to ẹgbẹrun mẹjọ di oku lọwọ awọn to pa wọn, ṣugbọn 2007 ni ICJ too gba pa ipanirun waye nibẹ.
Awọn ọkunrin Musulumi ati awọn ọdọkunrin wọn ni wọn pa nigba naa.
Gẹgẹ bi Rachel Burns, olukọ imọ nipa Criminology lati University of York ṣe sọ, o ni eeyan perete ni wọn ti da lẹjọ lori ẹsun wọn ri.
"A ko mọ iye eeyan to lọwọ si ti Rwanda, Yugoslavia tẹlẹ ati Cambodia, eeyan perete ni wọn da lẹjọ ri."
Alaye awọn akọṣẹmọṣẹ lori genocide yii ni pe bi wọn ba ti kede pe o n ṣẹlẹ lorilẹede kan, awọn orilẹede to ti tọwọ bọwe rẹ gbọdọ gbe igbesẹ ti yoo dẹkun rẹ.
Nipa lilo ọgbọn inu, fifi ofin de nibi to yẹ ati lilo awọn ologun.














