Lẹ́yìn Ọlọ́run, ìyá tó bí mi, Tinubu ló kàn, bí Tinubu ṣe máa wọlé ní 2027 ló bá mi báyìí – MC Oluomo

Oríṣun àwòrán, Others
Aarẹ awọn awakọ lorilẹede Naijiria, Musiliu Akinsanya, ẹni ti ọpọ mọ si MC Oluomo ti wọgile ẹsun ti wọn fi kan pe o kuna lati san owo fun awọn oṣere tiata to kopa ninu ipolongo ibo fun Aarẹ Bola Tinubu lasiko ipolongo ọdun 2023.
MC Olumomo ni irọ to jina si otitọ ni ọrọ naa, to si jẹ ko di mimọ pe owo ara oun ni oun fi ṣe ipolongo ibo fun aarẹ lasiko naa.
Ọpọ awọn oṣere tiata bii Fatai Adetayo (Lalude), Ronke Oshodi-Oke, ati Ganiu Nafiu (Alapini), lo jade sita lati fi ẹsun kan Ọga NURTW pe ko mu adehun rẹ sẹ lasiko ipolongo ibo fun aarẹ Tinubu ati Gomina Babajide Sanwo-Olu.
Lalude, ni MC Oluomo se adehun pe oun yoo fun onikaluku wọn ni owo toto N1.5m ṣugbọn kobo wọn ko ri gba lẹyin ipolongo ibo.
"Ni akọkọ, wọn n fun wa ni N10,000, owo ounjẹ ṣugbọn wọn tun pada da duro. A n fi ẹsẹ rin ọna jijin lojojumọ nigba ti MC yoo ma fi ọkọ ayọkẹlẹ tẹle wa. Ni ipari, wọn ja wa si ofo," Lalude ṣalaye.
Nigba to n fesi ẹsun naa, MC Oluomo ni oun ko ni idi lati mu owo ẹnikẹni dani, to si jẹ ko di mimọ pe owo ara oun ni oun fi ko awọn oṣere jọ, ti oun si tun san owo ile ti wọn de si.
"Mo n ri gbogbo ẹsun ti wọn fi kan mi, mi o kan fesi ni. Ohun ti mo mọ ni pe gbogbo wa jọ se ipolongo fun Tinubu papọ, ẹnikẹni ninu wọn ti ko ba ri nnkan ni eyi, ko jade sita wa sọrọ.
"Ẹnikẹni ko fun mi lowo; Mo lo owo ara mi lati se ipolongo ibo fun Asiwaju Bola Tinubu nitori Tinubu lo kan lẹyin Ọlọrun ati iya mi ni igbesi aye mi.
"Mo gba yara ile ituea140 fun wọn lasiko ipolongo ibo, ti mo si san ₦45,000 fun yara kan. Mo n fun wọn ni ow oni ojoojumọ, wọn si lo oṣu meji ninu ile itura naa.
"Ko da wọn se ọjọbi fun mi. Mo pada de lati US ni awọn eeyan sọ fun mi pe ki n lọ si ile itura naa. Nigba ti mo de si ibẹ, wọn se ọjọbi fun.
"Owo ara mi ni mo fi ṣe ipolongo ibo fun Tinubu, ti ma si tun ṣe fun un ni ọdun 2027. Ẹsun ti wọn fi kan mi ko le yi ipinnu mi pada, nitori Tinubu ni mo wa fun," MC Oluomo sọ.















