NDLEA ṣàwárí ilé tí wọ́n ti ń po oògùn olóró Colorado nílùú Eko, mú àwọn afurasí

Ẹsẹ afurasi ati akọle tin NDLEA fi lede nipa rẹ

Oríṣun àwòrán, NDLEA

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ to n gbogun ti lilo ati tita oogun oloro ni Naijiria, NDLEA, ti ṣawari ile kan ti wọn ti n po oogun oloro Colorado lagbegbe Ajao Estate, ni Isolo.

Agbẹnusọ ajọ naa, Femi Babafemi, lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn ti fi ṣikun ofin mu ẹni to ni yara ti wọn ti n po oogun oloro naa, Stephen Kelechi Imoh to jẹ ẹni ọgbọn ọdun lẹyin ti awọn kan sin ajọ naa ni gbẹrẹ ipakọ.

Atẹjade naa sọ pe ọpọlọpọ oogun oloro Colorado ni awọn ri lakata Imoh.

Ninu alaye NDLEA, aṣeyọri yii waye lẹyin ti wọn ti kọkọ ri ọpọlọpọ Colorado gba muninu oṣu Kẹta ati oṣu Karun un ọdun 2025 yii, eyii to jẹ ki awọn mọ pe oogun oloro naa ti wọn n ko wọle lati ilẹ okere tẹlẹ ti pọ yanturu laarin ilu Eko.

Babafemi sọ pe "a ri Colos ti wọn ṣẹṣẹ po ti iwọn rẹ jẹ 16.2kg, iwọn 1.7kg oogun oloro ADB-CHMNACA Cannabinol, 4.5kg oogun oloro Potassium Carbonate, ati ọgọrun din mẹsan an lita Dibromobutane ti wọn fi n po Colorado pọ.

"A ṣe aṣeyọri yii ni ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2025 nigba ti NDLEA ya bo ile kan ni Ajao Estate, Isolo, ilu Eko, nibi ti Kelechi ti n po oogun oloro Colos pọ, to jẹ oogun ti wọn n ri lati ara igbo ti wọn si maa n po oniruru kẹmika pọ mọ."

Ọwọ NDLEA tun tẹ awọn afurasi mii to n ta oogun oloro

NDLEA ni awọn tun ya bo ibuba oloogun oloro mii, Afeez Salisu ti inagijẹ rẹ n jẹ 'Malu' lagbegbe Mushin.

O ni ibẹ ni wọn ti ṣawari oogun oloro Ghana Loud mẹrindinlogun ati Colorado pẹlu.

NDLEA tun mu ẹni ogun ọdun mii, Godspower George Osahenrumwen, ti inagijẹ rẹ n jẹ Steady Boy lori ẹsun pe oun naa n ta oogun oloro.

Eyii ti wọn ka mọ lọwọ lo wa ninu ẹru aṣọ kan to ṣẹṣẹ de lati ilẹ Amẹrika.