Wo àwọn kòkòrò àìfojúrí tó ń wà nínú búrọ̀ṣì ìfọyín rẹ àti ohun tí o ní láti ṣe nípa wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Richard Gray
- Role, BBC Future
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7
Búrọ̀ṣì ìfọnu rẹ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn nǹkan tó ń kó àwọn kòkòrò àìfojúrí tó lé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíọ̀nù sínú.
Kò dín ní mílíọ̀nù kan sí mílíọ̀nù méjìlá àwọn kòkòrò àìfojúrí onírúurú ẹ̀yà tó jẹ́ ti bacteria àti fungi, tó fi mọ́ àwọn virus ló wà nínú búrọ̀ṣì ìfọnu rẹ. Omi, itọ́ ẹnu àtàwọn oúnjẹ tí ó ń ṣẹ́kù lẹ́nu wa tó ń kan búrọ̀ṣì náà ní ojoojúmọ́ ń fún àwọn kòkòrò àìfojúrí náà ni àǹfààní láti máa dàgbà, kí wọ́n sì máa pọ̀ si.
Bákan náà ni àwọn kòkòrò àìfojúrí tó ń jáde nínú àwọn ilé ìgbọ̀nsẹ̀ àti àwọn fèrèsé tó bá wà ní àyíká náà máa ń pọnkún iye tó máa ń wà nínú àwọn búrọ́ṣì yìí.
Tó sì jẹ́ pé lọ́pọ̀ ìgbà ni a máa ń fi búrọ̀ṣì yìí fọ ẹnu ní ó kéré tán ẹ̀ẹmèjì lójúmọ́.
Ṣé ó yẹ láti kọminú lórí bí búrọ̀ṣì èèyàn ṣe mọ́ sí?
Ìbéèrè yìí ló ti ń da ọkàn ọ̀pọ̀ àwọn dókítà tó ń ṣe ìtọ́jú eyín láàmú, èyí ló sì mú wọn ṣe ìwádìí láti mọ àwọn nǹkan tó ń gbé nínú àwọn búrọ̀ṣì, irú ìpalára wo ni àwọn kòkòrò àwọn kòkòrò àìfojúrí ọ̀hún le dá sí àgọ́ ara àti pé báwo ló ṣe yẹ fún wa láti máa ṣètọ̀jú àwọn búrọ̀ṣì wa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Níbo ni àwọn kòkòrò àìfojúrí ti ń wá?
Ọ̀nà mẹ́ta láwọn kòkòrò àìfojúrí yìí ń gbà wọ búrọ̀ṣì gẹ́gẹ́ Marc-Kevin Zinn, onímọ̀ nípa àwọn kòkòrò àìfojúrí ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Rhine-Waal University of Applied Sciences ní Germany tó ṣe ìwádìí lórí àwọn búrọ̀ṣì ṣe sọ.
Àwọn ọ̀nà náà ni ẹnu ẹni tó ń lo búrọ̀ṣì, ara rẹ̀ àti àyíká tí à ń tọ́jú búrọ̀ṣì sí.
Kí a tó lo búrọ̀ṣì rárá, ó ṣeéṣe kí ó ti ní àwọn kòkòrò àìfojúrí láti ibi tí wọ́n ti ṣé wá. Àyẹ̀wò àwọn búrọ́ṣì ogójì tuntun láti iléeṣẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní Brazil ṣàfihàn rẹ̀ pé ìdàjí nínú àwọn búrọ̀ṣì náà ni wọ́n ti ní onírúurú kòkòrò bacteria nínú.
Ọ̀pọ̀ wa náà la tún máa ń fi àwọn búrọ̀ṣì wa sínú àwọn ilé ìgbọ̀nsẹ̀ tí à ń lò.
Ohun tó dára níbẹ̀ ni pé ọ̀pọ̀ àwọn kòkòrò àìfojúrí tí ìwádìí fi hàn pé wọ́n máa ń wà nínú àwọn búrọ̀ṣì ni kìí ṣe èyí tó le èèyàn lára. Ọ̀pọ̀ wọn ló jẹ́ pé ẹnu wa ni wọ́n ti wá. Nígbà tí a bá ń lo búrọ̀ṣì láti fi fọ ẹnu, wọ́n máa ń kó àwọn kòkòrò àìfojúrí bíi Rothia denocariosa, Streptococcaceae mitis àti àwọn ẹ̀yà Actinomyces bacteria – gbogbo àwọn kòkòrò yìí ló jẹ́ pé ẹnu w ani wọ́n ń gbé.
Àwọn kòkòrò yìí le wúlò fún ìlera wa nígbà míì nítorí wọ́n máa ń dènà àwọn kòkòrò míì tó máa ń mú kí eyín èèyàn jẹrà.
Bákan náà ni àwọn míì wà níbẹ̀ tó máa ń ṣe ara ní ìjàmbá.
Àwọn kòkòrò àìfojúrí tó léwu
"Àwọn tó ṣe pàtàkì jùlọ níbẹ̀ ni Streptococci àti Staphylococci, tí wọ́n máa ń fa kí eyín jẹrà," Vinicius Pedrazzi, Ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ nípa eyín ní ilé ẹ̀kọ́ gíga University of São Paulo ní Brazil sọ. Àwọn míì máa ń fa kí erìgì èèyàn wú.
Àwọn olùwádìí tún ti ṣàwárí àwọn bacteria àti fungi tí kò yẹ kí wọ́n wà níbi búrọ̀ṣì níbẹ̀ – àwọn kòkòrò àìfojúrí tó níṣe pẹ̀lú inú àti oúnjẹ tí kò dára bíi Escherichia coli, Pseudomonas aeruginosa, àti Enterobacteria. Bákan náà ni wọ́n tún ti ṣàwárí àwọn kòkòrò àìfojúrí ilé ìwòsàn bíi Klebsiella àti Candida yeasts lára búrọ̀ṣì.
Lára àwọn omit í a fi ń fọ búrọ̀ṣì, fọ ọwọ́ àti ilé ìgbọ̀nsẹ̀ ló ṣeéṣe káwọn kòkòrò náà ti wọ búrọ̀ṣì wa.
Ọ̀pọ̀ àwọn balùwẹ̀ ni kìí ṣe ibi tó máa ń tutù, táwọn omi tó ń kán síbẹ̀ le máa gbé àwọn kòkòrò àìfojúrí nínú afẹ́fẹ́. Èyí ló máa ń jẹ́ kí àwọn búrọ̀ṣì tí à ń fi sí balùwẹ̀ àti ilé ìgbọ̀nsẹ̀ máa kó kòkòrò púpọ̀ gẹ́gẹ́ bí Zinn ṣe sọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Toilet plume
Ní gbogbo ìgbà tí a bá fi omi ti ìgbẹ́ tí a yà sínú kòkò ìgbọ̀nsẹ̀ láti, níṣe ni omi díẹ̀ máa ń fọ́n pẹ̀lú ìgbẹ́, tí afẹ́fẹ́ sì le gbe gòkè wọ ìwọ̀n bàtà ẹsẹ̀ márùn-ún. Àwọn kòkòrò àìfojúrí tó le tara rẹ̀ jáde jẹ́ àwọn tó máa ń fa ikọ́, kàtá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Tí búrọ̀ṣì bá wà ní ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀, ó ṣeéṣe kí àwọn kòkòrò yìí ta si, tí èèyàn yóò sì fi sẹ́nu láìmọ̀. Bákan náà ni èèyàn tún le fa àwọn kòkòrò sí imú tí a kò bá pa àwo ìgbọ̀nsẹ̀ dé kí èèyàn tó fi omi ti ìgbẹ́ lọ.
Ìwádìí ilé ẹ̀kọ́ kan tún fi hàn ìdá ọgọ́ta búrọ̀ṣì àwọn akẹ́kọ̀ọ́, níbi tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń lo balùwẹ̀ kan ṣoṣo, lọ ní àwọn kòkòrò àìfojúrí tó máa ń wà nínú ìgbẹ́, tí ìgbàgbọ́ sì wà pé ó ṣeéṣe kí kòkòrò náà máa bọ́ látara búrọ̀ṣì ẹnìkan sí ti ẹlòmíràn.
Ṣùgbọ́n Erica Hartmann, Ọ̀jọ̀gbọ́n lẹ́ka ìmọ̀ ẹ̀rọ ní ilé ẹ̀kọ́ Northwestern University in Illinois, US tó ṣe ìwádìí lórí bí àwọn kòkòrò àìfojúrí ṣe máa ń dàgbà ní àwọn tó máa ń wà nílé ìgbọ̀nsẹ̀ kò léwu tó báwọn èèyàn ṣe máa ń sọ ọ́.
Àbọ̀ iṣẹ́ tí ìgbìmọ̀ olùwádìí rẹ̀ ṣe kò rí àwọn kòkòrò àìfojúrí tó jẹ́ ti ìgbọ̀nsẹ̀ lára àwọn búrọ̀ṣì mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n tí wọ́n fi ṣe ìwádìí ní Illinois. Ó wòye pé ọ̀pọ̀ àwọn kòkòrò náà kìí le ṣẹ̀mí pẹ́ púpọ̀ tí wọ́n bá ti wà nínú afẹ́fẹ́.
"Mi ò rò pé búrọ̀ṣì ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ṣe àìsàn."

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹ̀wẹ̀, àwọn ìwádìí kan tún fi hàn pé àwọn kòkòrò àìfojúrí bíi influenza àti coronavirus le ṣẹ̀mí lára búrọ̀ṣì fún ọ̀pọ̀ wákàtí, tí herpes sì le lo ọjọ́ méjì gbáko. Èyí le ṣokùnfà ìtànkálẹ̀ àìsàn, ìdí nìyí tí àwọn onímọ̀ fi tako pínpín búrọ̀ṣì lò.
Àwọn onímọ̀ ìlera tún máa tako kí búrọ̀ṣì méjì máa fara kan ara wọn nígbà tí a bá búrọ̀ṣì púpọ̀ sí ojú kan náà pàápàá tí kìí bá ṣe èèyàn tí à ń bá gbé papọ̀.
Lára àwọn kòkòrò àìfojúrí tí wọ́n máa ń wà lára búrọ̀ṣì ni wọ́n ń ṣiṣẹ́ tó da fún ọmọnìyàn. Hartmann àtàwọn ikọ̀ rẹ̀ ṣàwárí àwọn kòkòrò kan tó jẹ́ pé kòkòrò àìfojúrí míì ni wọ́n máa ń ṣe ìkọlù sí dípò èèyàn, èyí sì lè mú àdínkù bá iye kòkòrò tó ń wà lára búrọ̀ṣì.
Kí ni àwọn èwu tó rọ̀ mọ?
Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ewu tó máa ń rọ̀ mọ kéré gẹ́gẹ́ bí Zinn ṣe sọ àmọ́ ó le jẹ́ ohun ìkọminú fáwọn tí ẹ̀yà ara wọn kò le tó bẹ́ẹ̀, tó sì ṣeéṣe fún wọn láti tètè ní àìsàn. Ìwádìí Zinn àtàwọn míì tó fara pẹ sọ pé àwọn kòkòrò yìí ni oògùn antibiotics kìí ràn wọ́n.
Èyí túmọ̀ sí pé tí wọ́n bá fa àìsàn sí èèyàn lára, ó máa ń ṣòro láti tọ́jú. Àmọ́ ìwádìí Zinn ní àwọn kòkòrò yìí kò wọ́pọ̀. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe fáwọn búrọ̀ṣì àádọ́ta ní Italy fi hàn pé gbogbo wọn ló ní kòkòrò táwọn oògùn kan kò lè tọ́jú.
Àwọn búrọ́ṣì kan sì wà tí wọ́n ti ń tà pẹ̀lú àwọn oògùn tí kò ní jẹ́ káwọn kòkòrò àìfojúrí dúró lára búrọ̀ṣì ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ìwádìí ní àwọn oògùn náà kìí sábà ṣiṣẹ́ àti pé wọ́n tún máa ń pọnkún àwọn kòkòrò tí kìí gbọ́ oògùn ni.
Ní kúkúrú, fífi búrọ̀ṣì sílẹ̀ lóòró lẹ́yìn tí èèyàn bá lò ó tán láti gbẹ sínú yàrá jẹ́ ọ̀nà kan láti mú àdínkù bá bí àwọn kòkòrò ṣe le máa gbé níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn kòkòrò àìfojúrí bíi influenza àtàwọn coronavirus ni wọ́n máa ń kú níbi tó bá gbẹ.
Àwọn kòkòrò bíi Streptococcus mutans tó máa ń fa kí eyín rà le wà lárá búrọ̀ṣì fún wákàtí mẹ́jọ àmọ́ tí wọ́n máa kú tó bá ti ń tó wákàtí méjìlá.
Ẹgbẹ́ àwọn onímọ̀ nípa eyín ní America àti US Centre for Disease Control and Prevention sọ pé kí a dènà dídé ẹnu búrọ̀ṣì kí atẹ́gùn le máa fẹ́ sí wọn, tí yóò sì dènà kí àwọn kòkòrò àìfojúrí le máa wà níbẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Báwo ló ṣe yẹ láti máa ṣe ìtọ́jú búrọ̀ṣì?
Onírúurú àwọn ohun èlò láwọn èèyàn ń lò láti ṣe àfọ̀mọ́ búrọ̀ṣì wọn. Àwọn kan máa ń lo iná, àwọn míì ń lo ẹ̀rọ amú oúnjẹ gbóná. Lára èyí tó ṣiṣẹ́ ni lílo ẹ̀rọ tí wọ́n fi máa ń gbẹ irun àti fífi sínú ọtí whisky.
Àwọn ẹ̀rọ ìfọyín tí à ń lò tí ọ̀pọ̀ wọn máa ń ní èròjà láti gbógunti àwọn kòkòrò àìfojúrí yìí náà máa ń ṣiṣẹ́ mímú àdínkù bá àwọn kòkòrò àìfojúrí ara búrọ̀ṣì. Ṣíṣan búrọ̀ṣì pẹ̀lú omi náà máa ń jẹ́ kí àwọn kan kúrò àmọ́ àwọn ṣì máa ń lẹ̀ ma búrọ̀ṣì.
Àwọn olùwádìí kan ní lílo ìdá kan vinegar jẹ́ ọ̀nà tó pójú owó láti fi mú àdínkù bá bacteria àmọ́ ó ṣeéṣe kí àwọn ẹlòmíràn má fẹ́ràn bí búrọ̀ṣì wọn yóò ṣe máa rí lẹ́nu nígbà tí wọ́n bá ń tún búrọ̀ṣì náà lò.
Fífi búrọ̀ṣì sínú àwọn èròjà ẹnu fífọ̀ fún ìṣẹ́jú márùn-ún sí mẹ́wàá náà dára.
Pedrazzi sọ pé fífi búrọ̀ṣì sínú ìfọnú tó ní 0.12% chlorhexidine tàbí 0.05% cetylpyridinium chloride náà le mú àdínkù bá àwọn kòkòrò náà.
Àwọn búrọ̀ṣì tó bá ti pẹ́ náà máa ń jẹ́ kí kòkòrò àìfojúrí pọ̀ si. Èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìdí tí American Dental Association ṣe máa ń ní káwọn èèyàn máa pààrọ̀ búrọ̀ṣì lẹ́yìn oṣù mẹ́ta.
Àwọn olùwádìí míì ẹ̀wẹ̀ ń faramọ́ lílo àwọn ìfọyín tó máa ń fi ààyè gba kí àwọn kòkòrò àìfojúrí máa dàgbà.
Bí àpẹẹrẹ, Streptococcus salivarius, máa ń ṣe ìrànwọ́ láti kogún ja àwọn kòkòrò kan, tí iléeṣẹ́ kan ní New Zealand sì ti ṣe àyẹ̀wò rẹ̀. Bákan náà ni Limosilactobacillus reuteri máa ń kogún ja eyín rírà.
Ẹ̀wẹ̀, bó yá àsìkò ti tó fún ọ láti wo búrọ̀ṣì rẹ bóyá ó tit ó àsìkò láti pàrọ̀ rẹ̀ tàbí kí o mu kúrò nínú balùwẹ̀ tí o wà.












