Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ DJ Chicken tí wọ́n fi lù ú ní àlùbami ní Sagamu?

Aworan Ademola Abiodun, ẹni ti ọpọ mọ si DJ Chicken

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Adẹrinposonu lori ikanni ayelujara Tiktok, Ademola Abiodun, ẹni ti ọpọ mọ si DJ Chicken ni o ma ru igi oyin ni ọjọ Ṣatide, ọjọ kinni, oṣu kọkanla ọdun 2025 lẹyin ti ọkọ rẹ ni ijamba ni ọna Sagamu nipinlẹ Ogun.

Ninu fọnran to n tan ka lori ayelujara, DJ Chicken ni a ri to jokoo si ilẹ pẹlu oju to ti wu lọwọ lilu alubami, ti ọpọ ero si yi ka.

Ẹjẹ bo ẹnu rẹ, ti ọpọ awọn eeyan to yi ka si n da ifọti ati abara bo lẹyin ti ijamba ọkọ naa waye.

Fọnran ọhun tun ṣapejuwe bi ọkọ naa ṣe bajẹ, ti ọkade kan ti igbagbọ wa pe o jẹ ti ọkọ lara awọn eeyan ti ori ko yọ ninu ijamba naa wa pẹlu rẹ. A ri eeyan mii to n jẹ irora ni ilẹ ni ẹgbẹ DJ chicken.

Ki lohun to ṣẹlẹ gangan gẹgẹ bi a ṣe gbọ?

Ohun ti a ri gbọ ni pe ọkọ DJ Chicken kọlu ọkada kan, ti eeyan to n wa ọkada naa ati ero to gbe si farapa yanayana.

Gẹgẹ bii Legit NG se gbe iroyin naa jade, oṣojumikoro ti wọn ba sọrọ fẹsun kan DJ Chicken pe ere aṣapajude lo ṣokunfa ijamba naa.

Ọpọ ohun labẹ fọnran naa ni wọn pariwo pe ki n ṣe igba akọkọ ree ti Dj Chicken yoo da wahala silẹ lasiko to n wa ọkọ loju opopona,

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ko ti sọ ohun ko nipa iṣẹlẹ naa titi di asiko yii.

Ọpọ awọn akẹgbẹ rẹ lori ayelujara ti wọn ti n ba bẹ ibẹ lori ayelujara pe ki awọn eeyan Sagamu tu silẹ.

Dj Chicken naa ko ti sọ ohunkohun nipa iṣẹlẹ naa.

Ta ni Dj Chicken?

Ademola Abiodun, ẹni ti ọpọ mọ si DJ Chicken, ni a le pe ni olori to di olokiki lori opo ayelujara Tiktok.

Wọn bi ni ọjọ kẹwaa oṣu kẹrin ọdun 1995 nipinlẹ Eko.

Ipinlẹ Ogun gbe dagba, ko to pada si ilu Eko.

Bakan naa ni a le ṣapejuwe rẹ gẹgẹ ọmọ ẹyin gbajugba olorin takasufe, Portable.

Ṣugbọn wọn ti pinya bayii lẹyin ti awọ bẹ silẹ laaarin wọn.