Àwọn agbébọn jí Igbákejì olórí ilé ìgbìmọ̀ aṣofin Kebbi gbé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn agbebọn lati agbegbe Lakurawa ti nawọ gan igbakeji olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kebbi, Samaila Bagudo, ti wọn ji gbe lọ.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kebbi ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, to si ni awọn agbebọn naa kọlu aṣofin naa kete to kirun tan, to n lọ si ile rẹ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kebbi, CSP Nafiu Abubakar, ni awọn ẹsọ alabo ti wa nita bayii lati ṣawari Bagudo.
CSP Abubakar ni ọpọ awọn ẹsọ alabo lati ileeṣẹ ologun, ileeṣẹ ọlọpaa ati awọn fijilante lo wa ni ayika ipinlẹ naa lati gba Bagudo silẹ lọwọ awọn ajinigbe.
"Awọn ẹsọ alabo n sisẹ papọ lati koju awọn agbebọn to yi awọn agbegbe ipinlẹ Kebbi ka lati gba aṣofin silẹ, ki ọwọ si tẹ awọn agbebọn naa pẹlu,"
O fikun pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kebbi ko fi gba kankan ju wọ silẹ lori dida bobo araalu, to si jẹ pe dida bobo ẹmi ati dukia lo jẹ wọn logun.
CSP Abubakar further rọ awọn araalu lati ṣe suuru, ki wọn si kiyesi agbegbe wọn, ki wọn si tun ran ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ pẹlu awọn iroyin to le ṣe anfani fun iwadii wọn.











