Wo ìdí tí Tinubu fi buwọ́lu àfikún15% owó orí epo bẹntiroolu àti disu

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọjọbọ ana ti i ṣe ọgbọnjọ, oṣu Kẹwaa ọdun 2025 ni iroyin gbode, pe Aarẹ Bola Tinubu ti buwọlu afikun owo ori epo bẹntiroolu ati disu to n wọle lati ile okeere pẹlu ida mẹẹẹdogun (15%).
Ohun ti eyi tumọ si ni pe orilẹede Naijiria yoo san alekun owo 99.72 fun lita bẹntiroolu ati disu ti wọn ba n ko wọle.
Bi iroyin naa sẹ jade ni ọpọ araalu ti n fi aidunnu wọn han lori rẹ, wọn ni ohun ti yoo tun mu ọwọngogo ọja ati inira tuntun waye leyi.
Ṣugbọn awọn oṣiṣẹ elepo labẹle ni Naijiria faramọ igbesẹ aarẹ yii, wọn ni yoo jẹ ọna kan lati gbogun ti kiko epo bẹntiroolu olowo pọọku wọle.
Wọn fi kun un pe yoo ran fifọ epo nilẹẹ wa lọwọ, yoo si tun da aabo bo ẹka ipesẹ agbara.
Ṣugbọn ki ni alaye ajọ Federal Inland Revenue Service (FIRS) to n pawo wọle labẹnu?
Zacch Adedeji, Alaga ajọ naa ṣalaye ohun to rọ mọ ọn.
''Ààrẹ gbé ìgbésẹ̀ yìí ki owo tá a fi ń gbé epo wọlé lè bá ti ilẹ̀ wa mu, kì í ṣe láti fi pawó wọlé''
Nigba to n ṣalaye afikun owo ori epo yii ninu atẹjade kan, Alaga FIRS, Zacch Adedeji, sọ pe ki gbogbo ẹ le wa ni ibamu pẹlu ohun to n ṣẹlẹ lorilẹede Naijiria ni.
Alaga ajọ to n pawo wọle labẹnu naa sọ pe afikun yii ki i ṣe lati fi kun owo tijọba n pa wọle, ṣugbọn lati jẹ ki owo ilẹ okeere ṣe rẹgi pẹlu ohun to wa nilẹ ni Naijiria ni.
Bakan naa lo ni o tun wa fun lati ro ẹka ifọpo Naijiria lagbara, ko si ṣẹgun aigbọra ẹni ye to maa n waye laaarin awọn to n fọ epo labẹle ati awọn alagbata epo.
" Bi fifọ epo labẹle ṣe ti n goke si i, ti disu naa si ti n pọ daadaa, owo ti a n ta wọn ko duro loju kan, lara ohun to si n fa a ni aigbọra ẹniye laarin awọn to n fọ epo ilẹ wa ati awon alagbata."
Adedeji lo sọ bẹẹ
"Koda pẹlu atunto yii, owo lita epo kan l'Eko yoo ṣi wa laaarin N964.72 fun lita kan, eyi ti I ṣẹ $0.62, owo ilẹ okeere, ti ko ti i to bi wọn ṣe n ta a ni awọn ilu bii Senegal to n ta a ni $1.76 fun lita kan.
"Cote d'Ivoire n ta tiẹ ni $1.52 ,Ghana si n ta a ni $1.37 fun lita kan."
Ìgbà wo ní àfikún owo orí epo náa yóò bẹ̀rẹ̀?
Alaga ìgbìmọ̀ tó ń rí sí àtúnṣe owó orí, Taiwo Oyedele, ṣalaye pe afikun yii ki i ṣe ohun ti yoo bẹrẹ lẹsẹkẹsẹ.
O ni o digba ti idagbasoke to foju han ba ba awọn ẹka ọrọ aje, ti owo naira si gbera sọ si i .
Oyedele fi kun un pe o si le jẹ nigba ti owo epo rọbi ba ja walẹ lọja agbaye.
O ni bo tilẹ jẹ pe igbesẹ naa wa fun lati fi owo to ba yọ nibẹ tun ọna ṣe, yoo mu inira ba araalu bi won ba bẹrẹ rẹ lasiko yii.
Gẹgẹ bi Alaga atunṣe owo ori naa ṣe tẹsiwaju, o ni aarẹ tẹlẹ, Olusegun Obasanjo, nigba tiẹ, ṣeto pe wọn yoo maa fi owo to ba n wole lati ara epo tun ọna ṣe.
Ida ogoji(40% ) fun atunṣe ọna ijọba apapọ, ati ida ọgọta (60%) fun ọna ipinlẹ.
"Aba naa mu ọgbọn wa pupọ, wọn si ti n lo o ni awọn orilẹede bii aadọjọ (150)"
Oyedele lo ṣalaye bẹẹ.
O ni ajọ Federal Roads Maintenance Agency (FERMA) tilẹ ti fẹ maa gba owo naa latigba ti wọn ti yọ ọwo iranwọ epo, (subsidy), sugbọn igbimọ alatunṣe owo ori toun jẹ alaga rẹ ni ko gba fun wọn.
O ni awọn ro o nigba naa pe yoo mu inira wa fun araalu.
"Ni temi o, asiko to maa daa ju ni nigba ti owo naira ba lagbara si i, tabi ti owo epo ba ja walẹ. Nigba naa ni afikun yii ko ni i kan iye ti wọn n ta epo.
Oyedele lo ṣalaye bẹẹ.
Ṣaa, ireti araalu ni pe ki igbesẹ tuntun yii ma ṣe mu alekun inira wa.














